Kí ni àwọn DAO?
DAO jẹ́ àjọ àjọni papọ̀ tó ń ṣiṣẹ́ fún ìmúṣẹ iṣẹ́ àyànfúnni.
DAO gbà wá láàyè láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tó ní ìrònú kan náà káàkiri àgbáyé láìsí ìgbẹ́kẹ̀lé nínú olùdarí onínúrere láti ṣàkóso àwọn owó tàbí àwọn iṣẹ́. Kò sí ọ̀gá àgbà tó lè ná owó lórí ohun tó bá ṣáà ti wù ú tàbí ọ̀gá àgbà tó lè ṣe àfọwọ́yí àwọn ìwé ọ̀hún. Dípo, àwọn òfin tó dá lórí blockchain tí a kọ sínú kóòdù náà ló ń sọ bí àjọ náà ṣe ń ṣiṣẹ́ àti bí wọ́n ṣe ń ná owó.
Wọ́n ní àwọn ilé-ìṣúra àkọ́sínú tí kò sí ẹnikan tó ní àṣẹ láti wọlé láìsí ìfọwọ́sí ẹgbẹ́ náà. Àwọn ìpinnu jẹ́ ìṣàkóso nípasẹ̀ àwọn ìgbèrò àti ìdìbò láti ríi dájú pé gbogbo ènìyàn nínú àjọ ní ohùn, àti pé ohun gbogbo ń ṣẹlẹ̀ ní gbangba ní .
Kí ni ìdí tí a fi nílò àwọn DAO?
Bíbẹ̀rẹ̀ àjọ kan pẹ̀lú ẹnìkan tí ó ní ìtìlẹyìn àti owó nínú gba ìgbẹ́kẹ̀lé tó pọ̀ nínú àwọn ènìyàn tí o ń bá ṣiṣẹ́. Ṣùgbọ́n, ó ṣòro láti fọkàn tán ẹnì kan tí o kàn bá pàdé lórí íńtánẹ́ẹ̀tì. Pẹ̀lú àwọn DAO o kò nílò láti gbẹ́kẹ̀lé ẹnikẹ́ni mìíràn nínú ẹgbẹ́ náà, kóòdù DAO nìkan, èyí tó jẹ́ ìdá ọgọ́rùn-ún ní ìfòtítọ́hùwà àti tí ó ṣeé jẹ́rì síí nípasẹ̀ ẹnikẹ́ni.
Èyí ṣí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àǹfààní tuntun fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àgbáyé àti ìsọdọ̀kan.
Ìfiwéra
DAO | Àjọ ìbílẹ̀ |
---|---|
Ó sábà máa ń jẹ́ pẹrẹsẹ, àti tiwantiwa ní kíkún. | Ó sábà máa ń jẹ́ ìṣàkóso nípasẹ̀ ẹgbẹ́. |
Ó nílò ìdìbò tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kí èyíkéyìí ìyípadà tó lè di ìmúṣe. | Tó dá lórí ètò, a lè béèrè àyípadà láti ọwọ́ ẹgbẹ́ kan nìkan, tàbí wọ́n lè jẹ́ kí ìdìbò wáyé. |
A ka àwọn ìbò náà, a sì lo àbájáde rẹ̀ ní tààràtà láìsí alárinà tó ṣeé fọkàn tán. | Tí a bá gba ìdìbò láàyè, àwọn ìbò á jẹ́ kíkà láàrín ẹgbẹ́, àbájáde ìdìbò gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí a ó fọwọ́ mú ní ṣíṣe. |
Àwọn iṣẹ́ tí a ń ṣe ni a mú ní àdáṣ láìfọwọ́yí ní ọ̀nà aláìlákóso (fún àpẹẹrẹ pínpín àwọn owó aláànú). | Nílò ìfọwọ́yí ènìyàn, tàbí àdáṣe ti ìṣàkóso láti àárín, tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n fọwọ́ kàn láti yi. |
Gbogbo ìgbésẹ̀ ni ó jẹ́ kedere àti gbangba pátápátá. | Iṣẹ́-ṣiṣe jẹ́ ìkọ̀kọ̀ nígbà gbogbo, kò sì kan gbogbo ènìyàn. |
Àwọn àpẹẹrẹ DAO
Láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún èyí láti mọ́gbọ́n díẹ̀ dání síi, èyí ni àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ ti bí ó ṣé lè lo DAO kan:
- Ẹgbẹ́ aláàánú – ẹ lè gba ọrẹ látọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni lágbàáyé kí ẹ sì dìbò láti mọ ohun tí ẹ fẹ́ fi ṣàtìlẹ́yìn fún.
- Níní àkójọpọ̀ – ẹ lè ra àwọn ohun-ìní ti ara tàbí dígítà, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ lè dibò lórí bí ẹ ṣe lè lò wọ́n.
- Àwọn òwò àti ìfúnni – ẹ lè ṣẹ̀dá àkójọ owó fún òwò tó ń ṣàjọpọ̀ owó fún ìdókòwò kí ẹ sì dìbò lórí àwọn òwò láti ṣàtìlẹ́yìn fún. Owó tí wọ́n san padà lè wá di èyí tí wọ́n pín fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ DAO.
Báwo ni àwọn DAO ṣe ń ṣiṣẹ́?
Igi lẹ́yìn ọgbà DAO ni rẹ̀ èyí tó ṣàlàyé àwọn òfin ti àjọ náà tí ó sì ń tọ́jú ìṣúra ẹgbẹ́ náà. Ní kété tí àdéhùn náà bá wá láàyè lórí Ethereum, kò sí ẹnikan tó lè yí àwọn òfin padà àyàfi nípasẹ̀ ìbò kan. Tí ẹnikẹ́ni bá gbìyànjú láti ṣe nǹkan tí kò ní ààbò nípasẹ̀ àwọn òfin àti ọgbọ́n inú kóòdù, yóò kùnà. Àti nítorí pé àdéhùn ọlọ́gbọ́n náà ló ṣàlàyé ìṣúra, ìyẹn túmọ̀ sí pé kò sí ẹnikẹ́ni tó lè lo owó náà láìsí ìfọwọ́sí ẹgbẹ́. Èyí túmọ̀ sí pé àwọn DAO kò nílò aláṣẹ àpapọ̀ kan. Dípo, ẹgbẹ́ ń ṣe àwọn ìpinnu ní àpapọ̀, àti awọn ìsanwó ni a fi àṣẹ sí láìfọwọ́yí nígbàtí a bá gba ìbò wọlé.
Èyí ṣeé ṣe nítorí pé àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n jẹ́ èyí tí kò ṣe fọwọ́yí ní kété tí wọ́n bá wà láàyè lórí Ethereum. Ò kàn lè déédéé ṣàtúnkọ kóòdù (àwọn òfin DAO) láìsí àwọn wípé àwọn èniyàn ń ṣàkíyèsí nítorí ohun gbogbo jẹ́ gbangba.
Ethereum àti DAOs
Ethereum jẹ́ ìpìlẹ̀ pípé fún àwọn DAO fún àwọn ìdí púpọ̀:
- Ìfohùnṣọ̀kan Ethereum jẹ́ aláìlákóso tó sì ti fìdí múlẹ̀ dáradára fún àwọn àjọ láti gbẹ́kẹ̀lé nẹ́tíwọọkì náà.
- Kóòdù àdéhùn ọlọ́gbọ́n kò lè ṣeé ṣàtúnṣe ní kété tó bá wà láàyè lórí ayélujára, pàápàá nípasẹ̀ àwọn olóhun. Èyí gba DAO láàyè láti ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ àwọn òfin tí a fi ṣètò rẹ̀.
- Àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n lè fi owó ránṣẹ́/gba owó. Láìsí èyí, wàá nílò alárinà tó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé láti máa ṣàkóso owó ẹgbẹ́.
- Àwùjọ Ethereum ti fi hàn pé ó jẹ́ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ díẹ̀ síi ju ìdíje lọ, gbígba fún àwọn iṣẹ́ tó dára jùlọ àti àwọn ètò àtìlẹyìn láti farahàn ní kíákíá.
Ìṣàkóso DAO
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ni a máa ń gbéyẹ̀wò nígbà tí a bá ń darí DAO, bíi bí ìdìbò àti àwọn àbá ṣe ń ṣiṣẹ́.
Aṣojú
Àwọn aṣojú jẹ́ bíi ẹ̀yà DAO ti aṣojú ìjọba tiwantiwa. Àwọn tó ní tọ́kẹ̀n yóò fi iṣẹ́ ìdìbò rán àwọn olùmúlò tó yan ara wọn tó pinnu láti ṣàkóso ìlànà náà àti níní ifitonileti.
Àpẹẹrẹ olókìkí kan
ENS(opens in a new tab) – Àwọn tó ní ENS lè gbé ìbò wọn fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwùjọ tí wọ́n ń ṣojú fún wọn.
Ìṣàkóso ìdúnàádúrà àìfọwọ́yí
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn DAO, àwọn ìdúnàádúrà yóò jẹ́ ṣíṣe láìfọwọ́yí ti iye kan àwọn ọmọ ẹgbẹ́ bá dibò ní ìdánilójú.
Àpẹẹrẹ olókìkí kan
Nouns(opens in a new tab) – Nínú Nouns DAO, ìdúnàádúrà kan yóò wáyé láìfọwọ́yí tí iye àwọn ìbò bá wà àti tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ni, níwọ̀n ìgbà tí àwọn olùdásílẹ̀ kò bá tako èsì ìbò.
Ìdarí Multisig
Nígbà tí DAOs lè ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó ń dibò, àwọn owó lè gbé nínú tó jẹ́ àjọpín láàrín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwùjọ lọ́wọ́lọ́wọ́ bíi 5-20 tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé àti nígbà gbogbo jẹ́ doxxed (àwọn ìdánimọ̀ gbangba tí àwùjọ mọ̀). Lẹ́yìn ìbò, àwọn tó fọwọ́ sí á wá ṣe ohun tí àwùjọ fẹ́.
Àwọn òfin DAO
Lọ́dún 1977, ìpínlẹ̀ Wyoming dá LLC sílẹ̀, èyí tó ń dáàbò bo àwọn oníṣòwò tó sì ń dín ẹrù iṣẹ́ wọn kù. Láìpẹ́ díẹ̀, wọ́n ṣe aṣáájú-ọnà òfin DAO tó fi ìdí ipò òfin múlẹ̀ fún àwọn DAO. Lọ́wọ́lọ́wọ́ Wyoming, Vermont, àti Virgin Islands ní àwọn òfin DAO ní àwọn ọ̀nà kan.
Àpẹẹrẹ olókìkí kan
CityDAO(opens in a new tab) – CityDAO lo òfin DAO ti Wyoming láti ra ilẹ̀ 40 acres nítòsí Yellowstone National Park.
Ọmọ ẹgbẹ́ DAO
Àwọn àwòṣe oríṣiríṣi wà fún ọmọ ẹgbẹ́ DAO. Ọmọ ẹgbẹ́ lè pinnu bí ìdìbò ṣe lè ṣiṣẹ́ àti àwọn abala pàtàkì mìíràn nínú DAO.
Jíjẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ tó dá lórí tọ́kẹ̀n
Ó sábà máa ń jẹ́ , tó dá lórí tọ́kẹ̀n tí wọ́n lò. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà àwọn tọ́kẹ̀n ìṣàkóso wọ̀nyí ni a lè fi ṣòwò láìsí ìgbanilááyè lórí . A gbọ́dọ̀ jèrè àwọn mìíràn nípa pípèsè iṣẹ́ tàbí àwọn ìjẹ́rìí sí iṣẹ́ mìíràn. Ohun yòówù kó jẹ́, wíwulẹ̀ di tọ́kẹ̀n náà mú fúnni ní ìráàyèsí ìdìbò.
Tí a lò nígbà gbogbo láti ṣàkóso àwọn ìlànà aláìlákóso gbòòrò àti/tàbí àwọn tọ́kẹ̀n fúnrara wọn.
Àpẹẹrẹ olókìkí kan
Maker DAO(opens in a new tab) – Tọ́kẹ̀n MKR ti MakerDAO ti wà ní ibi gbogbo lórí àwọn pàṣípààrọ̀ aláìlákóso, ẹnikẹ́ni lè ra láti ní agbára ìdìbò lórí ọjọ́ iwájú ìlànà Maker.
Ọmọ ẹgbẹ́ tó dá lórí ìpín
Àwọn DAO tó dá lórí ìpín ló ní ìgbanilááyè díẹ̀ síi, ṣùgbọ́n ó tì ṣí sílẹ̀ ní púpọ̀. Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ di ọmọ ẹgbẹ́ DAO lè ṣe ìfilọ́lẹ̀ láti di ọmọ ẹgbẹ́ DAO, tí wọ́n sì sábà máa ń fúnni ní ẹ̀bùn kan tó níye lórí bíi tọ́kẹ̀n tàbí iṣẹ́. Àwọn ìpín ìdókòwò dúró fún agbára ìdìbò tààràtà àti ìní. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ lè jáde nígbàkigbà pẹ̀lú ìpín wọn tó yẹ ti ìṣúra náà.
A sábà máa ń lò ó fún àwọn àjọ tí wọ́n sún mọ́ra jù, tí wọ́n gbájú mọ́ ènìyàn bíi àwọn àjọ aláàánú, àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, àti àwọn ẹgbẹ́ olùdókòwò. Ó tún lè ṣàkóso àwọn ìlànà àti àwọn tọ́kẹ̀n pẹ̀lú.
Àpẹẹrẹ olókìkí kan
MolochDAO(opens in a new tab) – MolochDAO fojúsí ìgbéowósílẹ̀ fún àwọn iṣẹ́ àkànṣe Ethereum. Wọ́n nílò àbá fún dídi ọmọ ẹgbẹ́ kí àwùjọ lè ṣàyẹ̀wò bóyá o ní òye pàtàkì àti owó láti ṣe àwọn ìdájọ́ tó mọ́gbọ́n dání nípa àwọn tó lè gba owó. O kò lè ra ìráàyèsí DAO lórí ọjà gbangba.
Ọmọ ẹgbẹ́ tó dá lórí orúkọ rere
Orúkọ rere sójú ìjẹ́rìísí ti ìkópa àti agbára ìdìbò fífúnni lówó nínú DAO náà. Kò dà bíi tọ́kẹ̀n tàbí ọmọ ẹgbẹ́ tó dá lórí ìpín, àwọn DAO tó dá lórí orúkọ rere kìí gbé ohun-ìní fún àwọn olùlọ́wọ́sí. A kò lè ra orúkọ rere, a kò lè gbé e fún ẹlòmíràn tàbí fi rán ẹlòmíràn; àwọn ọmọ ẹgbẹ́ DAO gbọ́dọ̀ jèrè orúkọ rere nípa lílọ́wọ́ nínú rẹ̀. Ìdìbò alákọsílẹ̀ oní jẹ́rìí sí jẹ́ èyí tí kò nílò ìgbanilááyè àti pé àwọn ẹni tó fẹ́ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ lè fi àwọn ìgbèrò sílẹ̀ láti darapọ̀ mọ́ DAO àti béèrè fún orúkọ rere àti àwọn tọ́kẹ̀n gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀bùn ní pàṣípààrọ̀ fún àwọn ìlọ́wọ́sí wọn.
A máa ń lo fún ìdàgbàsókè aláìlákóso àti ìṣàkóso ti àwọn ìlànà àti àwọn , ṣùgbọ́n ó tún dára fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àjọ bíi àwọn aláàánú, àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, àwọn ẹgbẹ́ ìdókòwò, àti bẹbẹ lọ.
Àpẹẹrẹ olókìkí kan
DXdao(opens in a new tab) – DXdao jẹ́ ilé ìṣọ̀kan olómìnira lágbàáyé tó ń kọ́ àti darí àwọn ìlànà àti àwọn ohun èlò aláìlákóso láti ọdún 2019. Ó lo ìṣàkóso tó dá lórí orúkọ àti láti ṣètò àti ṣàkóso owó, èyí tó túmọ̀ sí pé kò sẹ́ni tó lè ra ọ̀nà láti ní ipa lórí ọjọ́ ọ̀la tàbí ìṣàkóso.
Darapọ̀ mọ́ / bẹ̀rẹ̀ DAO kan
Darapọ̀ mọ́ DAO
- Àwọn DAO àwùjọ Ethereum
- Àtòjọ àwọn DAOHaus ti àwọn DAO(opens in a new tab)
- Àtòjọ Tally.xyz ti àwọn DAO(opens in a new tab)
Bẹ̀rẹ̀ DAO kan
- Pe DAO kan pẹ̀lú DAOHaus(opens in a new tab)
- Bẹrẹ Gómìnà DAO kan pẹ̀lú Tally(opens in a new tab)
- Ṣẹ̀dá DAO tó ní ìrólágbara Aragon(opens in a new tab)
- Bẹ̀rẹ̀ ìletò kan(opens in a new tab)
- Ṣẹ̀dá DAO kan pẹ̀lú ìfohùnṣọ̀kan holographic ti DAOstack(opens in a new tab)
Kíkà síwájú síi
Àwọn àròkọ DAO
- Kíni DAO?(opens in a new tab) – Aragon(opens in a new tab)
- Ilé ti àwọn DAOs(opens in a new tab) – Metagame(opens in a new tab)
- Kí ni DAO àti kí ni ó wà fún?(opens in a new tab) - DAOhaus(opens in a new tab)
- Bí o ṣe lè Bẹ̀rẹ̀ Àwùjọ Dígítà tí DAO Ró lágbára(opens in a new tab) – DAOhaus(opens in a new tab)
- Kíni DAO?(opens in a new tab) – Coinmarketcap(opens in a new tab)
- Kíni Ìfohùnṣọ̀kan Holographic?(opens in a new tab) - DAOstack(opens in a new tab)
- DAO kìí ṣe ilé-iṣẹ́: níbití aláìlákóso ní àwọn àjọ aládaṣe ti ṣe pàtàkì nípasẹ̀ Vitalik(opens in a new tab)
- DAOs, DACs, DAs àti Díẹ̀ síi: Ìwé Ìtọ́nisọ́nà Ìpìlẹ̀-ọ̀rọ̀ Àìpéyé kan(opens in a new tab) - Búlọ́ọ̀gì Ethereum(opens in a new tab)
Videos
- Kí ni DAO nínú crypto?(opens in a new tab)
- Ṣé DAO lè Kọ́ Ìlú kan bí?(opens in a new tab) – TED(opens in a new tab)