Rékọjá sí àkóónú àkọ́kọ́

Dapps - Àwọn ohun èlò ẹ̀rọ tí kò ní àkóso

Àwọn irinṣẹ́ àti iṣẹ́ tí Ethereum ró lágbára

Dapps jẹ́ àgbékalẹ̀ tọ́ ń dàgbà ti àwọn ohun èlò tó ń lo Ethereum láti ṣe àyípadà àwọn àwòṣe ìṣòwò tàbí ṣẹ̀dá àwọn tuntun.

Àpèjúwe ti doge tó ń lo kọ̀ǹpútà kan

Bẹ̀rẹ̀

Láti gbìyànjú dapp kan, ìwọ yóò nílò àti díẹ̀ nínú ETH, wọ́lẹ́ẹ́tì kan yóò jẹ́ kí o lè so pọ̀, tàbí kí o wọlé. Àti pé ìwọ yóò nílò ETH láti san èyíkéyìí.

Ọ̀rẹ́ olùbẹ̀rẹ̀

Àwọn dapps díẹ̀ tó dára fún àwọn olùbẹ̀rẹ̀. Ṣàwárí dapps díẹ̀ síi ní ìsàlẹ̀.

Ààmì ìdánimọ̀ Uniswap

Uniswap

Ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn tọ́kẹ̀n rẹ pẹ̀lú ìrọ̀rùn. Àyànfẹ́ àwùjọ tó fún ọ láàyè láti ṣòwò àwọn tọ́kẹ̀n pẹ̀lú àwọn ènìyàn ní ààrin nẹ́tíwọọkì náà.

finance
Ṣí Uniswap(opens in a new tab)
Ààmì ìdánimọ̀ OpenSea

OpenSea

Ra, ta, ṣàwárí, kí o sì ṣòwò àwọn ọjà tí kò pọ̀ jù.

collectibles
Ṣí OpenSea(opens in a new tab)
Ààmì ìdánimọ̀ Gods Unchained

Gods Unchained

Eré káàdì ìṣòwò òní ìlànà. Gba àwọn káàdì nípa ṣíṣeré tí o lè tà ní ìgbésí ayé gidi.

gaming
Ṣí Gods Unchained(opens in a new tab)
Ààmì ìdánimọ̀ Iṣẹ́ Ethereum Name

Ethereum Name Service

Àwọn orúkọ ọ̀rẹ́-olùmúlò fún àwọn àdírẹ́sì Ethereum àti àwọn ibùdó aláìlákóso.

social
Ṣí Ethereum Name Service(opens in a new tab)

Ṣàwárí dapps

A lot of dapps are still experimental, testing the possibilities of decentralized networks. But there have been some successful early movers in the technology, financial, gaming and collectibles categories.

Yan ẹ̀ka

Ìṣúnná aláìlákóso

Àwọn ohun èlò wọ̀nyí tó dá lórí kíkó àwọn iṣẹ́ ìṣúnná owó nípa lílo àwọn owó crypto. Wọ́n máa ń yaá ni lówó, wọ́n máa ń gba owó èlé, wọ́n sì máa ń sanwó ti ara ẹni láì béèrè fún dátà nípa ara ẹni.

Ṣe ìwádìí ti ara rẹ nígbà gbogbo

Ethereum jẹ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ tuntun àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun èlò jẹ́ tuntun. Ṣáájú kí o tó fi àwọn iye owó ńlá sílẹ̀, ríi dájú pé o lóye àwọn ewu náà.

Yíya ni lówó àti yíyawó

Àwọn àfilọ́lẹ̀ pàṣípààrọ̀

Àwọn alápapọ̀ ìbéèrè

Awọn afara

Awọn owó ìdókòwò

Ìṣàkóso ìdókòwò

Ìbánigbófò

Àwọn owó sísan

Ìkówójọ lápapọ̀

Àwọn àmújáde látinú

Dídókòwò nínú ìsọdowó

Àwọn ọjà àsọtẹ́lẹ̀

Ṣé o fẹ́ láti ṣàwárí àwọn ohun èlò díẹ̀ síi?

Ṣàyẹ̀wò àwọn ọgọọgọ̀rún dapps(opens in a new tab)

Idán náà lẹ́yìn ìnáwó aláìlákóso

Kí ni ó wà nípa Ethereum tí ó jẹ́ kí àwọn ohun èlò ìnáwó aláìlákóso gbèrú?

Ṣí ìráàyèsí

Àwọn iṣẹ́ iṣúná owó tó ń ṣiṣẹ́ lórí Ethereum kò ní àwọn ìbéèrè ìforúkọsílẹ̀. Tí o bá ní owó àti àsopọ̀ íńtánẹ́ẹ̀tì, o dára láti lọ.

Ọ̀nà ìṣúnná tọ́kẹ̀n tuntun

Ilé ayé àwọn tọ́kẹ̀n kan wà tí ó lè ní ìbáraẹnisepọ̀ pẹ̀lú káàkiri àwọn nǹkan owó wọ̀nyí. Àwọn ènìyàn ń kọ àwọn tọ́kẹ̀n tuntun sórí Ethereum ní gbogbo ìgbà.

Stablecoins

Àwọn ẹgbẹ́ ti ṣe – owó crypto tí kò fi bẹ́ẹ̀ yípadà ní iye. Àwọn nǹkan wọ̀nyí máa ń jẹ́ kó o lè ṣe àyẹ̀wò kí o sì lo owó-ìpamọ́ láìsí ewu àti àìdánilójú.

Àwọn iṣẹ́ ìṣúnná owó tí a so pọ̀

Àwọn ọjà owó ní ààyè Ethereum jẹ gbogbo èyí tó ní ètò àti ìbáramu pẹ̀lú ara wọn. Àwọn àtúntò tuntun ti àwọn ẹ̀rọ yìí ń jáde ní ọjà ní gbogbo ìgbà, tí ó ń mú kí ohun tí ẹ lè ṣe pẹ̀lú crypto rẹ pọ̀ sí i.

Àpèjúwe tí àwọn alálùpàyídà

Àwọn idán tó wà nídìí dapps

Dapps lè dàbí àwọn ohun èlò tó wọ́pọ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn àwọn ojú ìṣẹ̀lẹ̀, wọ́n ní àwọn àbùdá pàtàkì nítorí pé wọ́n jogún gbogbo agbára ńlá Ethereum. Èyí ni ohun tó jẹ́ kí dapps yàtọ̀ sí àwọn ohun èlò.

Kí ló mú kí Ethereum ṣe pàtàkì?

Kò sí àwọn olóhun

Ní kété tí wọ́n bá ti gbé e sórí Ethereum, a kò lè gbé kóòdì dapp kúrò. Ẹnikẹ́ni sì lè lo àwọn ohun èlò dapps. Kódà bí ẹgbẹ́ tó wà lẹ́yìn dapp bá túká, o ṣì lè lò ó. Bí ó bá ti wà lórí Ethereum, ó máa wà níbẹ̀ títí.

Òmìnira lọ́wọ́ ìfòfinde

Àwọn ìsanwó tí a ṣe sínú rẹ̀

Tibọ̀ọ́ kí o mu ṣiṣẹ́

Wíwọlé kan tí kò lórúkọ

Àtìlẹyìn nípa ohun àdàkọ

Kò sí àkókò ìsinmi

Bí dapps ṣe ń ṣiṣẹ́

Dapps ní àwọn kóòdù ẹ̀yìn wọn (àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n) tó ń ṣiṣẹ́ lórí nẹ́tíwọọkì aláìlákóso àti tí kìí ṣe olùpín alákóso. Wọ́n ń lo Ethereum fún ibi ìpamọ́ dátà àti àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n fún ọgbọ́n ohun èlò wọn.

Àdéhùn ọlọ́gbọ́n dàbí ètò àwọn òfin tó wà lórí ìgbésẹ̀ alákọsílẹ̀ fún gbogbo ènìyàn láti rí àti ṣiṣẹ́ ní ìbámu sí àwọn òfin wọ̀nyẹn. Fojú inú wo ẹ̀rọ ìtajà kan: tí o bá fi owó tó pọ̀ tó sínú rẹ̀, tí o sì yan èyí tó tọ́, wàá gba ohun tí o fẹ́. Bíi tàwọn ẹ̀rọ ìtajà, àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n lè mú owó dání bíi ti àkáǹtì Ethereum rẹ. Èyí ń gba kóòdù láàyè láti ṣe alárinà àwọn àdéhùn àti àwọn ìdúnàádúrà.

Ní kété tí o bá gbé àwọn dapps sórí nẹ́tíwọọkì Ethereum o kò lè yí wọn padà. Dapps lè jẹ́ aláìlákóso nítorí pé wọ́n jẹ́ ìṣàkóso nípasẹ̀ ọgbọ́n tí a kọ sínú àwọn àdéhùn, kìí ṣe ẹnìkan tàbí ilé-iṣẹ́ kan.

Ǹjẹ́ ojú-ìwé yìí ṣe ìrànlọ́wó?