Rékọjá sí àkóónú àkọ́kọ́

Ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso

  • Àwọn ìlànà ètò ṣíṣe ìdánimọ̀ ìbílẹ̀ ti ṣe àkópapọ̀ pípínfúnni, ìtójú àti ìṣàkóso àwọn ìdánimọ̀ rẹ.
  • Ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso yóò yọ ìgbẹ́kẹ̀lé sí àwọn ẹgbẹ́ kẹta ti àárín.
  • Ọpẹ́ ni fún kírípítò, àwọn olùmúlò ní báyìí àwọn irin-iṣẹ́ láti pín, dìmú àti ṣàkóso àwọn ìdánimọ̀ ara wọn àti àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí l'ẹ́kan sí.

Ìdánimọ̀ ṣe àtìlẹ́yìn fún gbogbo agbala ti ìgbésí ayé rẹ lónìí. Lílò àwọn iṣẹ́ orí ayélujára, ṣíṣí àkọọ́lẹ̀ ìfowópamọ́ kan, dídìbòyàn ní àwọn ìdìbò, ríra ohun-ìní, ṣíṣe ààbò iṣẹ́ – gbogbo ǹkan wọ̀nyí nílò láti ṣe ìjẹ́ẹ̀rísí ìdánimọ̀ rẹ.

Àmọ́, àwọn ètò íṣàkóso ìdánimọ̀ ìbílẹ̀ ti gbéralé àwọn agbedeméjì àárín tí ó fún ni, dìmú, àti ṣàkóso àwọn ìdánimọ̀ rẹ . Èyí túmọ̀ sí pé o kò le ṣàkóso àlàyé tí ó ní ìbátan ìdánimọ̀ tàbí pinnu taani ó ní àǹfàní ìwọlé sí àlàyé ìdánimọ̀ ti ara ẹni (PII) àti iye ìgbà wíwolé àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí.

Láti yanjú àwọn ìṣòro wọnyí, a ní àwọn ètò ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso tí a ti ṣe lórí blockchains gbangba bí Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù. Ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso gba àwọn ènìyàn láàyè láti ṣàkóso àlàyé tí ó ní ìbátan ìdánimọ̀ wọn. Pẹ̀lú àwọn ojútùú ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso, ìwọ le ṣ'èdá àwọn ìdámọ̀, àti kí o bèèrè àti kí o dì àwọn ẹ̀rí rẹ mú láìṣe ìgbékẹ̀lé àwọn aláṣẹ àárín, bíi olùpèsè iṣẹ́ tàbí àwọn ìjọba.

Kíni ìdánimọ̀?

Ìdánimọ̀ túmọ̀ sí ìmọ ara ẹni kọ̀ọ̀kan, àsọyé nípa àwọn àbùdá aláìlẹ́gbẹ́. Ìdánimọ̀ tọ́kasí jíjẹ́ olúkúlùkú, ìyẹn ni, ẹ̀dá ènìyàn ọ̀tọ̀tọ̀. Ìdánimọ̀ le tún tọ́ka sí àwọn ǹkan mìíràn tí kìí ṣe ènìyàn, gẹ́gẹ́bí àgbájọ tàbí aláṣẹ.

Kíni àwọn aṣe ìidámọ̀?

Aṣèdámọ̀ jẹ́ ǹkan ti àlàyé tí ó ṣiṣẹ́ bíi ìtọ́ka sí ìdánimọ̀ kan pàtó tàbí àwọn ìdánimọ̀. Àwọn aṣèdámọ̀ tí ó wọ́pọ̀ jẹ́:

  • Orúkọ
  • Nọ́ḿbà àwùjọ ààbò/nọ́ḿbà ìdánimọ̀ owó-orí
  • Nọ́ḿbà ẹ̀rọ alágbèéká
  • Ọjọ́ àti ibi ìbí
  • Àwọn ìwé-ẹ̀rí ìdánimọ̀ oní nọ́ḿbà, fún àpẹrẹ, àwọn àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì, àwọn orúkọ olùmúlò, àwọn àwòrán ara ẹni

Àwọn àpẹẹrẹ ìbílẹ̀ ti àwọn ìdámò ti wà ní ìdásílẹ̀, ní ídìmú àti ìṣàkóso nípasẹ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ ààrin gbùngbùn. O nílò ìgbaniláàyè láti ọ̀dọ̀ ìjọba láti yí orúkọ rẹ padà tàbí láti orí ẹ̀rọ ayélujára láti yí orúkọ olùmúlò rẹ padà.

Àǹfàní ti ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso

  1. Ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso ṣe àfikún fún ìṣàkóso ẹnìkọ̀ọ̀kan fún ìdámò àlàyé. Àwọn ìdámò tí kò ní àkóso àti àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí le ṣe ìjẹ́ẹ̀rísí láì ṣe àgbẹ́kẹ̀lé àwọn aláṣẹ àárín àti àwọn iṣẹ́ ẹgbẹ́ kẹta.

  2. Àwọn ìdánimò tí kò ní àkóso ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún aláìfọkà tán, aláìsí yonu, àti ọ̀nà ìdáàbòbò àṣírí fún ìjẹ́ẹ̀rísí ati ìṣàkóso ìdánimọ̀ olùmúlò.

  3. Ìdánimò tí kò ní àkóso ń ṣe àtìlẹ́yìn fún ìmọ̀-ẹ̀rọ blockchain, èyítí o ṣ'èdá ìgbẹ́kẹ̀lé láàrin àwọn ẹgbẹ́ oríṣiríṣi àti ìpèsè àwọn ìṣèdúró fún kírípítò láti fi ìdí àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí múlẹ̀.

  4. Ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso jẹ́ kí dátà ṣe gbé kiri. Àwọn olùmúlò tọ́jú àwọn ìjẹ́ẹ̀rí àti àwọn ìdámò wọn sínú àpamọ́wọ́ alágbèéká àti wípé wón le pín wọn fún èyíkéyìí ẹgbẹ́ tí ó wù wọ́n. Àwọn ìdámò tí kò ní àkóso àti àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí kò ní títìpa sínú ibi ìpamọ́ dátà àwọn àgbájọ tí ó fún ni.

  5. Ìdánimò tí kò ní àkóso yẹ kí o ṣiṣẹ́ dáradára pẹ̀lú àwọn ìmọ̀-ẹ̀rọ tí ń yọ jáde tí yóò jékí àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan le ṣe àrídájú wípé àwọn ní tàbi àwọn ti ṣe ǹkan láìsí ìṣàfihàn kíni ǹkan náa ńṣe. Èyí le jẹ́ ọ̀nà tí ó lágbára láti ṣe àkópapọ̀ ìgbékẹ̀lé àti àṣírí fún àwọn ohun èlò bíi ìdìbò.

  6. Ìdánimò tí kò ní àkóso le jékí ó ṣeéṣe fún àwọn ìlànà sí ìdánimọ̀ nígbàtí ènìyàn kan bá ń díbọ́n wípé òún jẹ́ ènìyàn púpọ̀ sí èrè tàbí ṣe awúrúju ètò kan.

Lílò fún ìdánimò tí kò ní àkóso

Ìdánimò tí kò ní àkóso ní ìmúlò ọ̀nà tí ó pọ̀:

1. Àwọn ọ̀nà gbígbàwọlé káríayé

Ìdánimò tí kò ní àkóso le ṣe ìrànlọ́wọ́ ìrọ́pò fún àwọn ìgbaniwọlé oní ọ̀rọ̀-aṣínà pẹ̀lú ìfàṣẹsí tí kò ní àkóso. Àwọn Olùpèsè iṣẹ́ le fún àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí sí àwọn olùmúlò, èyí tí ó le wà ní ìpamọ́ sínú àpò àpamọ́wọ́ Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù. Àpẹrẹ ìjẹ́ẹ̀rísí yóò jẹ́ fífún ẹni tí ó ni ààyè sí àgbègbè orí ayélujára.

Iṣẹ́ ìwọlé pẹ̀lú Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù(opens in a new tab) yóò jẹ́kí àwọn apèsè láti ṣe jẹ́ẹ̀rísí àkọ́ọ́lẹ̀ Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù olùmúlò àti mú ẹ̀rí tí ò nílò láti inú àdírẹ́ẹ̀sì àkọ́ọ́lẹ̀ wọn. Èyí túmò sí pé àwọn olùmúlò le wọlé sí àwọn ojú ẹ̀rọ àti àwọn ojú òpó ayélujára láìsí níní láti ṣe àkọ́sórí àwọn ọ̀rọ̀ aṣínà gígùn àti ṣíṣe ìmúdárasí ìrírí orí ayélujára fún àwọn olùmúlò.

2. Ìfàṣẹsí KYC

Lílo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ orí ayélujára nílò àwọn ènìyàn láti pèsè àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí àti àwọn ìwé-ẹ̀rí, gẹ́gẹ́bí ìwé-àṣẹ awakọ̀ tàbí ìwé ìrìnnà orílẹ̀-èdè. Lílo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ orí ayélujára nílò àwọn ènìyàn láti pèsè àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí àti àwọn ìwé-ẹ̀rí, gẹ́gẹ́bí ìwé-àṣẹ awakọ̀ tàbí ìwé ìrìnnà orílẹ̀-èdè.

Ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso gba àwọn ilé-iṣẹ́ láàyè láti gbójú lórí ìlànà Mọ-Oníbárà-rẹ KYC(opens in a new tab) àti ṣe ìjẹ́ẹ̀rísí àwọn ìdánimọ̀ olùmúlò nípa àwon ìwé-ẹ̀rí tí a le s'àrídájú. Èyí mú àdínkù bá ìdíyelé ti ìṣàkóso ìdánimọ̀ àti ìdílọ́wọ́ fún lílo àwọn ìwé-ẹ̀rí irọ́.

3. Ìdìbò àti àwùjọ orí afẹ́fẹ́

Ìdìbò orí ayélujára àti orí ìkànnì àjọlò jẹ́ àwọn ohun èlò àràmàdá méjì fún ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso. Àwọn ètò ìdìbò orí ayélujára ní ìfaragbá sí ìfọwọ́yí, pàtàkì tí àwọn olùkópa búburú bá ṣ'èdá àwọn ìdámọ̀ èké láti dìbò. Bíbèèrè fún kí àwọn ẹnì-kọ̀ọ̀kan láti ṣàfihàn àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí lórí-ẹ̀rọ le mú ìdúróṣinṣin bá àwọn ìlànà ìdìbò orí ayélujára.

Ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso le ṣe ìrànlọ́wọ́ ìṣẹ̀dá àwọn agbègbè orí ayélujára tí kò ní àwọn àkọọ́lẹ̀ iró. Fún àpẹẹrẹ, olùmúlò kọ̀ọ̀kan le ní láti ṣe ìjẹ́ẹ̀rísí ìdánimọ̀ wọn nípa lílo ètò ìdánimọ̀ orí-ẹ̀rọ, bíi Iṣẹ́ Orúkọ Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù, mímú àdínkù bá ìṣeése àwọn rọ́bọ̀tì.

4. Ìdáàbòbò Anti-Sybil

Àwọn ohun èlò afúnni-láàyè tí ó ńlo ní ìfaragbá sí nítorí iye ẹ̀bùn ti pọ̀ si nígbàtí àwọn ènìyàn púpọ̀ bá dìbò fun, fífún àwọn olùmúlò ní ìwúrí láti pín àwọn ìpín wọn káàkiri ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdámò. Àwọn ìdámò tí kò ní àkóso ṣe ìrànlọ́wọ́ láti ṣe ìdíwọ́ èyí nípa gbígbé ẹrú lé orí olùkópa kọ̀ọ̀kan láti ṣe ìjẹ́ẹ̀rísí wípé àwọn jẹ́ ènìyàn nítòótó, bótilẹ̀jẹ́pé lọ́pọ̀ ìgbà láìsí níní láti ṣàfihàn àlàyé kan pàtó.

Kíni àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí?

Ìjẹ́ẹ̀rísí jé ẹ̀tọ́ tí ẹ̀dá kan ṣe nípa ẹ̀dá míìràn. Tí o bá ń gbé ní orílẹ̀-ẹ̀dẹ̀ Améríkà, ìwé àṣẹ awakọ̀ tí Ẹ̀ka Àwọn Ọkọ̀ Ayọ́kẹ́lẹ́ (ẹ̀dá kan) pín fún ọ ṣe ìjẹ́ẹ̀rí wípé ìwọ (ẹ̀dá míìràn) ní ìgbàláàyè láti wa ọkọ̀ kan.

Àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí yàtọ̀ sí àwọn ìdámọ̀. Ìjẹ́ẹ̀rísí àwọn olùdámọ̀ láti tọ́ka ìdánimọ̀ kan pàtó, ó sì ṣe ẹ̀tọ́ nípa àwòmọ́ tí ó ní ìbátan sí ìdánimọ̀ yìí. Nítorí náà, ìwé àṣẹ ìwakọ̀ rẹ ní àwọn àmì ìdánimọ̀ (orúkọ, ọjọ́ ìbí, àdírẹ́sì) àmọ́ ó tún jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé o lẹ́tọ̀ọ́ láti wakọ̀.

Kí ni àwọn àmì ìdánimọ tí kò ní àkóso?

Àwọn ohun ìdánimọ̀ ìbílẹ̀ bíi orúkọ rẹ tàbí àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì rẹ gbẹ́kẹ̀lé àwọn ẹnìkẹta — àwọn ìjọba àti àwọn olùpèsè ímeèlì. Àwọn ìdámò tí a kò ṣàkóso (DIDS) yàtọ̀ — wọn kìí ṣàtẹ̀jáde, ṣalábòójútó, tàbí ṣàkóso nípasẹ̀ èyíkéyìí ile-iṣẹ́ ààrin-gbùngbùn.

Àwọn ìdámò tí a kò pín ní àtẹ̀jáde, dìmú, àti ìṣàkóso nípasẹ̀ àwọn ẹnì-kọ̀ọ̀kan. jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso. O le ṣẹ̀dá iye àkọọ́lẹ̀ tóo bá fẹ́ láìsí ìgbàṣẹ lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni àti láìsí ìdí láti fi wọ́n pamọ́ sínú ìwé ìforúkọsílẹ̀ ààrin-gbùngbùn.

Àwọn ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso ní àfipamọ́ lórí àwọn ìwé-ìpamọ́ pínpín () . Èyí jẹ́ kí àwọn DIDs jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ ní àgbáyé, tí o le yanjú pẹ̀lú wiwà tí ó ga, àti tí o le ìjẹ́ẹ̀rísí cryptographically(opens in a new tab). Àmì ìdánimọ tí kò ní àkóso lè ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá tí ó yàtọ̀ síra, títí kan àwọn ènìyàn, àwọn àjọ, tàbí àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba.

Kini o mu ki awọn asedanimọ alailakoso ṣeeṣe?

1. Bọ́tìnì cryptography gbangba

Bọ́tìnì cryptography gbangba jẹ́ ìgbésẹ̀ ààbò àlàyé tí ó ṣe àgbéjáde àti fún ẹ̀dá kan. Bọ́tìnì gbangba ni a nlo nínú àwọn nẹtiwọọki blockchain láti fi ìdánilójú ìdánimọ̀ àwọn olùmúlò hàn àti láti fi ẹ̀rí níní àwọn ohun-ìní oní-nóḿbà hàn.

Díẹ̀ nínú àwọn ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso, gẹ́gẹ́bí àkọọ́lẹ̀ Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù, ní àwọn bọ́tìnì gbangba àti ìkọ̀kọ̀. Bọ́tìnì gbangba ń ṣe ìdánimọ̀ olùdarí, nígbà tí àwọn àkọọ́lẹ̀ àdáni lè fọwọ́ sí àti tú àwọn ìfiránsẹ́ fún àkọọ́lẹ̀ yìí. Bọ́tìnì cryptography gbangba ṣe ẹ̀rí tí ó nílò láti ṣe ìjẹ́ẹ̀rísí àwọn àjọ àti dènà afinipeni lọ́nà èrú àti lílo ìdánimọ̀ ayédèrú, lílo ìbuwọ́lù cryptographic(opens in a new tab) láti ṣe ìjẹ́ẹ̀rísí àwọn ẹ̀tọ́.

2. Àwọn ibi ìpamọ́ ìsọfúnni tí a kò kò ní àkóso

Blockchain ń ṣiṣẹ́ bí ìforúkọsílẹ̀ dátà tí a lè ṣàyẹ̀wò: ìpamọ́ ìsọfúnni tó ṣí sílẹ̀, tí kò nílò ifọkàntán, tí kò sì ní àkóso. Ìwàláàyè àwọn blockchain tó wà fún gbogbo ènìyàn ṣe ìmúkúrò ìdí láti máa tọ́jú àwọn àmì ìdánimọ̀ sínú àwọn ìwé ìforúkọsílẹ̀ tó wà ní àárín gbùngbùn.

Bí ẹnikẹ́ni bá nílò láti jẹ́rìí sí ìwúlò àmì ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso wọ́n le wo bọ́tìnì tí ó so mọ́ ọn lórí ẹ̀rọ blockchain. Èyí yàtọ̀ sí àwọn ìdánimọ̀ ìbílẹ̀ tí ó nílò àwọn ẹgbẹ́ kẹta láti jẹ́ẹ̀rísí.

Báwo ni àwọn ìdámò àti àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí tí kò ní àkóso ṣe gba ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso láàyè?

Ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso ni èrò náà wípé àlàyé tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìdánimọ̀ yẹ kí ó jẹ́ èyí tí yóò darí ara rẹ̀, tí ó jẹ́ ti àdáni, tí ó sì ṣeé gbé kiri, pẹ̀lú àwọn ààmọ̀ ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso àti àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí tí ó jẹ́ kókó pàtàkì.

Ní àyíká ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso àwọn ìjẹ́ẹ̀rí (tí a tún mọ̀ sí Àwọn ìwé-ẹ̀rí tí a le ríí dájú(opens in a new tab)) jẹ́ àwọn àléébù tí a kò lè yí padà, tí wọ́n ṣeé ṣàyẹ̀wò nípa ẹ̀rọ cryptography tí àwọn olùfúnni ní ẹ̀rí ṣe. Gbogbo ẹ̀rí tàbí ìwé-ẹ̀rí tí a le ríí dájú ti ẹ̀dá kan (fún àpẹẹrẹ, àgbárí kan) ṣe jáde ní nkan ṣe pẹ̀lú DID wọn.

Nítorípé àwọn DID wà ní ìfipamọ́ lórí blockchain, ẹnikẹ́ni le ṣàyẹ̀wò ìfẹsẹ̀rinlẹ̀ ti ìjẹ́ẹ̀rísí kan nipa ìṣàyẹ̀wò DID ti olùfínni lori Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù. Ní pàtàkì blockchain Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù ṣiṣẹ́ bí ìtọ́sọ́nà àgbáyé tí ó fún ìjẹ́ẹ̀rísí ti àwọn DID tí ó ní ǹkan ṣe pẹ̀lú àwọn ǹkan kan láàyè.

Àwọn ohun ààmì ìdámọ̀ tí kò ní àkóso ni ìdí tí àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí ṣe jẹ́ èyí tí wọ́n ń ṣàkóso ara wọn àti èyí tí a lè ṣàyẹ̀wò. Kódà bí ẹni tó ṣe ẹ̀rí náà kò bá sí mọ́, ẹni tó ni ẹ̀rí náà á ṣì ní ẹ̀rí tó fi hàn pé ẹ̀rí náà jẹ́ ojúlówó.

Àwọn ohun ààmì ìdámọ̀ tí kò ní àkóso tún jẹ́ pàtàkì nínú dídá ààbò bo ìpamọ́ ìsọfúnni nípa ara ẹni nípa ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnìkan bá fi ẹ̀rí ti ìjẹ́ẹ̀rísí (ìwé-àṣe awakọ̀) sílẹ̀, ẹni tó ń ṣàyẹ̀wò kò ní láti ṣàyẹ̀wò bí ìsọfúnni tó wà nínú ẹ̀rí náà ṣe jẹ́ ojúlówó tó. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ìdánilójú tí wọ́n fi àwọn cryptography ṣe nìkan ni àwọn olùdánilójú nílò láti mọ bí ìwé ìdánilójú náà ṣe jẹ́ ojúlówó tó àti irú àjọ tó ṣe é kí ó tó lè mọ̀ bóyá ìwé ìdánilójú náà lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.

Àwọn oríṣi ti àwọn ẹ̀rí ìdánimọ̀ tí ó pín káàkiri

Ọ̀nà tí a fi àlàyé ijẹrisi pamọ́ àti gbígba padà ní ètò-àyè ìdánimọ̀ tí ó dá l'órí Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù yàtọ̀ pátápátá sí ìṣàkóso ìdánimọ̀ ìbílẹ̀. Èyí ní àwọn ọ̀nà oríṣiríṣi láti fúnni, tọ́jú, àti ṣ'ayẹwo àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí àwọn ètò ìdánimọ̀ tí ó pín káàkiri:

Àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí tí kò ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀ka

Ọ̀kan lára ohun tó ń jẹ́ kí àwọn ẹ̀rí wà lórí ẹ̀rọ ni pé wọ́n lè ní àwọn àlàyé tí àwọn èèyàn kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀. Ìṣẹ̀dá gbangba tí Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù blockchain ń ṣe jẹ́ kí ó jẹ́ ohun tí kò ní ìfanimọ́ra láti tọ́jú àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí bẹ́ẹ̀.

Ọ̀nà àbáyọ ni láti tẹ ìwé ẹ̀rí jáde, tí àwọn olùṣàmúlò ń kó sínú àpò owó oní-nọ́ḿbà, ṣùgbọ́n tí wọ́n fọwọ́ sí pẹ̀lú DID ti ẹni tí ó fúnni ní ìwé ẹ̀rí náà. Àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí wọ̀nyí ni a ṣe àkójọ bíi JSON Web Tokens(opens in a new tab) àti pé ó ní ìbuwọ́lù oní-nọ́ḿbà ti olùfúnni— èyí tí ó ṣe ìgbàláàyè fún àṣèyẹ̀wò tí ó rọrùn àwọn ẹ̀rí tí kò sí lórí ẹ̀rọ.

Èyí ní ìṣẹ̀lẹ̀ àròsọ tí ó ṣàlàyé àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí tí kò sí lórí ẹ̀rọ:

  1. Yunifásítì kan (olùfúnni) máa ń ṣe ìwé ìdánilójú (ẹ̀rí ìdánilójú ẹ̀kọ́ oní-nọ́mbà), yóò fi bọ́tìnnì rẹ̀ buwọ́ lu ìwé náà, yóò sì fi fún Bob (ẹni tó ni ìwé ìdánilójú náà).

  2. Bob kọ̀wé fún iṣé, ó sì fẹ́ fi ẹ̀rí hàn pé òun ti kàwé tó bó ṣe yẹ fún ẹni tó fẹ́ gbà á síṣẹ́, torí náà, ó fi ìwé ẹ̀rí tó wà nínú àpamọ́wọ́ rẹ̀ tó wà lórí tẹlifóònù alágbèéká rẹ hàn wọ́n. Ilé iṣẹ́ náà (àwọn olùṣàyẹ̀wò) lẹ́hìnáà le ṣàyẹ̀wò ìfẹsẹ̀rinlẹ̀ ti ìjẹ́ẹ̀rísí nípa ṣíṣàyẹ̀wò DID ti olùfúnni (i.e., bọ́tìnnì tí óhàn sí gbogbo ènìyàn ní orí Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù).

Àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí tí kò sí lórí ẹ̀rọ pẹ̀lú ìgbaniláàyè wíwọlé igbagbogbo

Lábẹ́ ètò yií àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí di yíyípadà sí àwọn fáìlì JSON àti fífipamọ́ lórí off-chain (ní bòjúmu lórí pẹpẹìpamọ àwọsánmà tí kò ní àkóso, bíi IPFS tàbí Swarm). Síbẹ̀síbẹ̀, ti fáìlì JSON ti wà ní ìfipamọ́ lórí on-chain àti tí o sopọ̀ mọ́ DID nípasẹ̀ ìforúkọsílẹ on-chain kan. DID tí ó sopọ̀ le jẹ́ bóyá tí olùfúnni ní ìjẹ́ẹ̀rísí tàbí ti olùgbà.

Ọ̀nà yìí jẹ́ kí àwọn ìwé-ẹ̀ri ó ní ìdúróṣinṣin tí ó dá l'órí blockchain, láàkókò tí a bá ń tọ́jú àlàyé ìpàrokò àwọn ẹ̀tọ́ àti tí ó ṣe ṣàyẹ̀wò. Ó tún jẹ́ kí yíyan ìṣàfihàn ṣeéṣe nítorípé olùdìmú bọ́tìnì ìkọ̀kọ̀ le tú àlàyé ìpàrokò náà.

Àwọn ẹ̀rí orí on-chain

Àwọn ẹ̀rí orí on-chain ni ó má ń wáyé ní lórí blockchain Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù. Àdéhùn ọlọ́gbọ́n náà (tí ó ṣiṣẹ́ bíi ìforúkọsílẹ̀) yóò ṣe àfiwé ìjẹ́ẹ̀rísí sí ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso on-chain tí ó báamu (bọ́tìnì gbangba).

Èyí ni àpẹẹrẹ láti fihàn bí àwọn ìfọwọ́sí on-chain le ṣiṣẹ́ ní ìṣe:

  1. Ilè-iṣẹ́ kan (XYZ Corp) ńgbèrò láti ta àwọn ìpín ìdíkòwò nípa lílo àdéhùn ọlọ́gbọ́n sùgbọ́n ó ń fẹ́ àwọn olùbárà tí ó ti parí àyẹwò abẹ́lé nìkan.

  2. XYZ Corp le ní ilé-iṣẹ́ tí ń ṣe àwọn àyẹ̀wò abẹ́lé láti fúnni ní àwọn ìjẹ́ẹ̀rísí on-chain lórí Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù. Ìjẹ́ẹ̀rísí yìí fi hàn pé ẹnì kan ti yege nínú àyẹ̀wò ìsọfúnni nípa ẹni náà láìfi ohunkóhun tó jẹ mọ́ ọn hàn.

  3. Àdéhùn ọlọ́gbọ́n tó ń ta ìpín lè ṣàyẹ̀wò àdéhùn ìforúkọsílẹ̀ fún àwọn olùbárà tí wọ́n ti ṣàyẹ̀wò, èyí tó mú kó ṣeé ṣe fún àdéhùn ọlọ́gbọ́n láti mọ ẹni tí wọ́n gbà láyè láti ra ìpín tàbí tí wọn kò gbà.

Àwọn tọ́kẹ̀n àti ìdánimọ̀ tí Soulbound

Àwọn tọ́kẹ̀n Soulbound (opens in a new tab) () le ṣeé lò láti gba àlàyé aláìlẹ́gbẹ́ sí àpamọ́wọ́ kan pàtó. Èyí ṣ'èdá ìdánimọ̀ on-chain aláìlẹ́gbẹ́ tí ó so pọ̀ sí àdírẹ́ẹ̀sì Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù kan pàtó tí ó le kó àwọn tọ́kẹ̀n tí ó ṣe aṣojú fún àwọn àṣeyọrí (fún àpẹrẹ píparí díẹ̀ nínú àwọn ẹ̀kọ́ orí ayélujára kan pàtó tàbí yíyege kọjá ààlà kan nínú eré kan) tàbí ìkópa àgbègbè.

Ìlò ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àkànṣe ló wà tí wọ́n ń lo Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún àwọn ojútùú ìdánimọ̀ tí kò ní àkóso:

Kíkà síwájú síi

Awọn arokọ

Videos

Àwọn àwùjọ

Ǹjẹ́ ojú-ìwé yìí ṣe ìrànlọ́wó?