Ibi tí o ti lè ra ETH
O lè rí ETH nípasẹ̀ iṣẹ́ ṣíṣe, gbàá láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ, tàbí ràá láti àwọn pàṣípààrò àti àwọn ohun èlò ẹ̀rọ.
Iye owó ETH lọ́wọ́lọ́wọ́ (USD)
Àwọn pàsípáàrọ̀ alákóso
Àwọn pàsípáàrọ̀ jẹ́ àwọn ìṣòwò tí ó jẹ́ kí o ra kírípítò nípa lílo àwọn owó níná ìbílẹ̀. Wọ́n ṣe àmójútó lórí èyíkéyìí ETH tí o rà títí tí o fi fi ránṣẹ́ sí àpamọ́wọ́ tí o ṣàkóso.
Jèrè ETH
O lè jogún ETH nípa ṣíṣe iṣẹ́ fún àwọn DAO tàbí àwọn ilé-iṣẹ́ tó ń sanwó pẹ̀lú crypto, jíjèrè àwọn ẹ̀bùn àfitọrẹ, wíwá ojútu sí àwọn ìṣòro afílọ́lẹ̀ àti díẹ̀ síi.
Gba ETH láti ọ̀dọ̀ àwọn akẹgbẹ́ rẹ
Ní kété tí o bá ní àkántì Ethereum, gbogbo ohun tí o nílò láti ṣe ni pín àdírẹ́sì rẹ láti bẹ̀rẹ̀ fífi ránṣẹ́ àti gbígba ETH (àti àwọn ààmì mìíràn) ẹlẹgbẹ́-sí-ẹlẹgbẹ́.
Àwọn pàsípáàrọ̀ aláìlákóso (DEXs)
Tí o bá fẹ́ ìṣàkóso díẹ̀ síi, ra ETH nípa lílo àwọn . Pẹ̀lú DEX o lè ṣòwò àwọn ohun-ìní digitali láìsí fífún ilé-iṣẹ́ kan ní ìṣàkóso awọn owó rẹ.
Àwọn wọ́lẹ́ẹ́tì
Díẹ̀ nínú àwọn wọ́lẹ́ẹ́tì jẹ́ kí o ra kírípítò pẹ̀lú káàdì dẹ́bìtì/kírẹ́dìtì, fífi ránṣẹ́ lórí bánkì tàbí pàápàá Apple Pay. Àwọn ààlà agbègbè le wà.
Èrè idoko-òwò
Tí o bá ti ní ETH díè tẹ́lẹ̀, o lè jogún díẹ̀ síi nípa ṣí ṣẹ nódù olùfọwọ́sí kan. Wà á gba èrè ṣíṣe iṣẹ́ ìjẹ rìísí náà ní ETH.
Gbogbo àwọn ọjà tí a ṣe àkójọ sí ojú-ìwé yìí kìí ṣe àwọn ìfọwọ́sí ti ilé-iṣẹ́, àti pé a pèsè wọn fún àwọn ìdí àlàyé nìkan. Tí o bá fẹ́ ṣàfikún ọjà kan tàbí pèsè èsì lórí ìlànà náà gbé ọ̀ràn kan dìde ní GitHub. Jábọ̀ ìṣòro
Orílẹ̀-èdè wo ní ò ń gbé?
Àwọn àfilọ́lẹ̀ pàṣípààrọ̀ ní àwọn àṣàyàn ibi tí wọ́n lè ta crypto. Èyí ni àkójọ ti àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan. Ìfisí níbí kìí ṣe ìfọwọ́sí - ṣe ìwádìí tìrẹ!
Tẹ orílẹ̀-èdè ibùgbé rẹ láti rí àwọn àfilọ́lẹ̀ pàṣípààrọ̀ tí o ní àǹfààní láti lò
Àwọn pàsípáàrọ̀ aláìlákóso (DEXs)
Kí ni DEXs?
Àwọn pàsípáàrọ̀ aláìlákóso jẹ́ àwọn ojú-ọjà gbangba fún ETH àti àwọn ààmi yòóku. Wọ́n so àwọn ólùraja àti ólùtàja papọ̀ ní tààrà.
Dípo lílo ẹnì keta tí a fọkàn tán láti dáàbò bo àwọn owó rẹ́ nínú ìdúnàádúrà náà, kóòdù ní wọ́n lò. ETH olùtàjà kò ní di títà àyàfi nígbàtí ó bá dánilójú pé owó á di sísan. Irú kóòdù yìí ni a mọ̀ sí àdéhùn ọlọ́gbọ́n. Díẹ̀ si ní orí àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n
Èyí túmọ̀ sí pé ídòjukọ igbùgbẹ díẹ̀ ló wà ju ti àṣàyàn alákóso lọ. Tí ẹnìkan bá ń ta ohun tí o fẹ́ tó sì ń gba ọ̀nà ìsanwó tí o lè pèsè, ìdúnàádúrà lè wáyé.
O nílò wọ́lẹ́ẹ́tì kí o tó lè lo DEX.
Gba wọ́lẹ́ẹ́tì kanRà pẹ̀lú kírípítò míràn
Pààrọ̀ àwọn tọ́kẹ̀n rẹ fún ETH àwọn èèyàn mìíràn. Àti ìdàkejì.
Fífi ETH rẹ pamọ́
Àwọn àkọsílẹ̀ àwùjọ lórí ààbò
Ethereum kò sí lábẹ́ ìṣàkóso àjọ kankan - ó aláìlákóso.
**Èyí túmọ̀ sí pé o ní láti gba ààbò àwọn owó rẹ níṣe gidi. Pẹ̀lú ETH, ìwọ kò ní ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ilé-ifowópamó̀ tàbí iléṣẹ́ kankan láti tọ́jú àwọn ohun ìní rẹ, ìwọ fúnrarẹ̀ ni o máa mú ní ojúṣe rẹ.
Fi ETH rẹ pamọ́ sínú wọ́lẹ́ẹ́tì tirẹ
Ọ̀kan nínú àwọn ànímọ́ pàtàkì tí Ethereum ní ni pé ìwọ ló máa ń ṣàkóso àwọn ohun ìní rẹ̀ nípasẹ̀ ìṣàkóso àkántì tirẹ. Èyí túmọ̀ sí pé o kò nílò láti fọkàn tán èyíkéyìí ẹnì kẹta láti tọ́jú àwọn ohun ìní rẹ, o sì ní ìdáàbòbò kúrò lọ́wọ́ àwọn olùtọọ́jú tó lè hùwà àìṣóòtọ́, já sí gbèsè tàbí kí wọ́n jí wọn gbé. Ṣùgbọ́n, èyí tún túmọ̀ sí pé ìwọ ló ni ojúṣe ààbò rẹ̀.
Ṣàyẹ̀wò àwọn wọ́lẹ́ẹ́tìÀdírẹ́sì ETH rẹ
Nígbàtí o bá ṣe àgbàsílẹ̀ wọ́lẹ́ẹ́tì kan yóò ṣẹ̀dá àdírẹ́sì ETH fún ìwọ. Bayí ní yòó ṣe rí:
0x0125e2478d69eXaMpLe81766fef5c120d30fb53f
Àpẹẹrẹ: Má ṣe ṣẹ̀dà
Ronú èyí bíi àdírẹ́sì ímeèlì rẹ. Sùgbọ́n kàkà bíi ímeèlì ó le gba ETH. Tí o ba fẹ fi ránṣẹ́ ETH láti orí pàsípáàrọ̀ sí inú wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ, lo àdírẹ́sì rẹ gẹ́gẹ́ bíi ibùjókòó. Ríi dájú láti yẹ̀ẹ́ wò lẹ́ẹ̀mejì kí o tó fi ránṣẹ́!
Tẹ̀lé àwọn ìlànà wọ́lẹ́ẹ́tì
Tí o bá pàdánù ìràyè sí wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ, ìwọ yóò pàdánù ààyè sí àwọn owó rẹ. Wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ yẹ kí o fún ọ ní àwon ìtọ́sọ́nà lórí ààbò láti yẹra fún irú èyí. Ríi dájú láti tẹ̀lé wọn pẹ́kípẹ́kí - ní òpòlopo àwọn ọ̀nà, kò sí ẹnìkan tí ó le ràn ọ́ lọ́wọ́ tí o bá pàdánù ìràyè sí àkántì rẹ.