Bí o ṣe lè ṣẹ̀dá àkántì Ethereum kan
Ẹnikẹ́ni lè ṣẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ Ethereum l'ọ̀fẹ́. O kàn ní láti fi ohun èlò ìfowópamọ́ kírípítò sórí ẹ̀rọ̀ rẹ. Ìṣẹ̀dá àwọn àpamọ́wọ́ àti Ìṣakóso àkọọ́lẹ̀ Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù rẹ. Wọ́n lè fi ìnáwó ránṣẹ́, ṣàyẹ̀wò owó rẹ, kí wọ́n sì so ọ́ pọ̀ mọ́ àwọn ohun èlò mìíràn tí wọ́n kọ sórí Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù.
Pẹ̀lú àpamọ́wọ́ kan o tún le wọlé sí èyíkèyí pàṣípààrọ̀ tọ́kẹ̀n, àwọn eré, àwọn ọjà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Kò sí ìdí fún ìforúkọsílẹ̀ ẹyọ kọ̀ọ̀kan, àkọọ́lẹ̀ kan ni a pín fún gbogbo àwọn ohun èlò tí a kọ sórí Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù.
Ìgbésẹ̀ 1: Yan àpamọ́wọ́ kan
Àpamọ́wọ́ jẹ́ ohun èlò tí ó ń ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣakoso àkáǹtì Ethereum rẹ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpò owó ló wà láti yàn nínú wọn: orí ẹ̀rọ alágbèéká, orí kọ̀ǹpútà alágbèéká, tàbí àwọn àfikún ìwífún aṣàwákiri pàápàá.
Àtòjọ àwọn wọ́lẹ́ẹ́tìTí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sí Kírípítò, o le yan aṣẹ̀yàn "Kiripito tuntun" ní orí pápá "wa àpamọ́wọ́" láti ṣe ìdánimọ̀ àwọn àpamọ́wọ́ tí ó máa kó gbogbo ẹ̀yà tí o wúlò fún ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀.
Àwọn aṣẹ̀yàn prófáìlì mìíràn tún wà láti ṣe àbójútó àwọn àìní rẹ. Àpẹẹrẹ àwọn àpamọ́ owó tí wọ́n sábà máa ń lò nìwọ̀nyí - ó yẹ kí o ṣe ìwádìí tìrẹ kí o tó fọkàn tán ètò èyíkéyìí.
Igbesẹ 2: Ṣe igbasilẹ ohun elo apamọwọ ki o fi sori ẹrọ rẹ
Lọgan ti o ba ti pinnu lori apamọwọ kan pato, lọ si oju opo wẹẹbu ojulowo wọn tabi itaja ohun elo, ṣe igbasilẹ ki o si fi si ori ẹrọ rẹ. Gbogbo wọn ló yẹ kó wà lọ̀fẹ́.
Igbesẹ 3: Ṣí ohun èlò náà kí o ṣẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù rẹ
Ní ìgbà àkọ́kọ́ tí o bà ṣí àpamọ́wọ́ tuntun rẹ ó le bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ẹ láti yàn láàrin ṣìṣẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ tuntun tàbí gbígbé ọ̀kan tí ó wà tẹ́lẹ̀ wọlé. Tẹ̀ sórí ìsẹ̀dá àkọọ́lẹ̀ tuntun. Èyí ni ìgbesẹ̀ nígbà tí àpamọ́wọ́ sọ́fítíwià ń ṣe àkọọ́lẹ̀ Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù rẹ
Ìgbésẹ̀ 4: Fi gbolohun olùgbàpadà rẹ pamọ́
Díẹ̀ nínú àwọn ohun èlò yóò bèèrè fún ọ láti kọ àṣírí pamọ́ "gbolohun olùgbàpadà" (nígbà míì wọ́n ń pè ní "gbólóhùn irugbin" tàbí "mnemonic"). Fí fi àwọn gbólóhùn yíì pamọ́ ṣe pàtàkì gidi gan! Èyí ni à ń lò láti ṣe àkọọ́lẹ̀ Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù rẹ àti pé o le lòó láti fi àwọn ìṣòwò ránṣẹ́.
Ẹnikẹ́ni tó bá mọ gbólóhùn náà lè wà ní àkóso gbogbo owó rẹ. Má ṣe sọ èyí fún ẹnikẹ́ni. Ọ̀rọ̀ yìí gbọ́dọ̀ ní ọ̀rọ̀ méjìlá sí mẹ́rìnlélógún tí wọ́n dá sílẹ̀ lóòrèkóòrè (ọ̀nà tí wọ́n gbà tòó ọ̀rọ̀ náà ṣe pàtàkì).
Kọ́ bí o ṣe le lòó.
Ṣé o fẹ́ mọ àwọn ìtọ́sọ́nà míì? Ṣàyẹ̀wò àwọn: ìtọ́nisọ́nà ìgbésẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan wa
Awon ibere gbogbo ìgbà
Ṣé ìkan náà ni àpamọ́ owó mi àti àkáǹtì Ethereum mi?
Rara. Àpamọ́wọ́ jẹ́ ohun èlò ìṣàkóso tí ó ń ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣètò àwọn àkáǹtì. Àpamọ́wọ́ ẹyọ ọ̀kan le wọlé sí àwọn àkọọ́lẹ̀ púpọ̀, àti pé àkọọ́lẹ̀ kan le gba àwọn àpamọ́wọ́ púpọ̀. Ọ̀rọ̀ olùgbàpadà ni a ń lò láti ṣẹ̀dá àwọn àkọọ́lẹ̀ àti fún àṣẹ fún ohun èlò àpamọ́wọ́ láti ṣakoso àwọn ohun ìní.
Ṣé mo lè fi Bitcoin ránṣẹ́ sí adirẹsi Ethereum, tàbí ether sí adirẹsi Bitcoin?
Rárá o, o ò lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bitcoin àti ether wà lórí àwọn nẹ́tíwọ́ọ̀kì ọ̀tọ̀tọ̀ méjì (ie àwọn blockchains ọ̀tọ̀tọ̀), ọ̀kọ̀ọ̀kan pẹ̀lu ìwé-ìpamọ́ tirẹ̀ àti àwọn ọ́nà àdírẹ́sì tirẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìgbìyànjú ló ti wà láti ṣe afárá àwọn nẹ́tíwọ̀ọ̀kì oríṣi méjì, nínú èyítí ọ̀kan tí ó ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ ni Wrapped BTC tàbí WBTC(opens in a new tab). Èyí kìí ṣe ìfọwọ́sí, nítorí WBTC jẹ́ ojútùú ti olùbánifipamọ́ (ìtumọ̀ pé ẹgbẹ́ kan tí àwọn ànìyàn kan ṣàkóso àwọn iṣẹ́ pàtàkì) àti pé a pèsè rẹ níbí fún àwọn àlàyé nìkan ni.
Tí mo bá ní àdírẹ́sì ETH kan, ṣé mo ní adirẹsi kan náà lórí àwọn blockchains míràn?
O le lo kan náà lórí gbogbo àwọn blockchains tí o ń lo irú sọ́fítíwià ìpìlẹ̀ sí Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù (tí a mọ̀ bíi 'ibamu-EVM'). Àtòjọ(opens in a new tab) yìí yóò fi hàn ọ́ àwọn blockchain tí o lè lò pẹ̀lú àdírẹ́sì kan náà. Díẹ̀ nínú àwọn blockchain, bí Bitcoin, ṣe ìmúse ìṣètò sí nẹ́tíwọ̀ọ̀kì tí ó yàtò pátápátá àti wípé o yóò nílò àdírẹ́ẹ̀sì tó yàtọ̀ pẹ̀lú ọ̀nà tó yàtọ̀. Tí o bá ní àpamọ́wọ́ àdéhùn ọlọ́gbọ́n kan, ó yẹ kí o ṣ'àyẹ̀wò ojú òpó wẹ́ẹ̀bù rẹ fún irú àwọn blockchain tí ó ṣe àtìlẹ́yìn fún nítorí ní gbogbo ìgbà, wọ́n má ń ní ààlà tí ó mọ níwòn ṣùgbón ààbò kíkún.
Ǹjẹ́ níní àpamọ́wọ́ tèmi lọ́wọ́ á dáàbò bò mí ju pé kí n kó owó mi sórí àpamọ́wọ́ tí àwọ́n pàsípáàrọ̀?
Tó o bá ní àpamọ́wọ́ tìrẹ, ìyẹn á jẹ́ kó o lè dáàbò bo àwọn ohun ìní rẹ. Ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ àwọn ilé ìfowópamọ́ tó ti kùnà ti pàdánù owó àwọn oníbàárà wọn. Níní àpamọ́wọ́ kan (pẹ̀lú ọ̀rọ̀ gbólóhùn olùràpadà) mú ewu tó so mọ́ ìṣègbẹ́kẹ̀lé àwọn ẹgbẹ́ kan láti tọ́jú àwọn ohun ìní rẹ. Àmọ́, o ní láti dáàbò bò ó fúnra rẹ, kí o sì yẹra fún àwọn ète ìtànjẹ, bíbuwọ́lu ìṣòwò láìsí ìdí tàbí ṣíṣí ọ̀rọ̀ gbólóhùn olùràpadà sílẹ̀, lílọ sí àwọn ìkànnì ayédèrú àti àwọn ewu ààbò ara ẹni mìíràn. Àwọn ewu àti àǹfààní tó wà nínú rẹ̀ yàtọ̀ síra.
Bí mo bá pàdánù fóònù mi/àpamọ́wọ́ alágbèéká mi, ṣé mo ní láti tún lo ẹ̀rọ àpamọ́wọ́ kan náà láti gba owó tí mo pàdánù padà?
Rárá, o lè lo àpamọ́wọ́ míì. Níwọ̀n ìgbà tóo bá ti ní gbólóhùn ìkọ̀kọ̀ náà o lè tẹ̀ ẹ́ sínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpamọ́ owó wọn yóò sì dá àkáǹtì rẹ padà. Ṣọ́ra tí o bá nílò láti ṣe èyí: ó dára jùlọ láti ríi dájú pé o kò ní àsopọ̀ sí orí íńtánẹ̀ẹ̀tì nígbàtí o bá ń gba àpamọ́wọ́ rẹ padà kí gbólóhùn ọ̀rọ̀ olùgbàpadà rẹ má ba ṣí sílẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀. Ó sábà máa ń ṣòro láti gba owó tó bá sọnù padà láìsí gbólóhùn olùgbàpadà náà.