Bí o ṣe le mọ àwọn àmi ẹ̀tàn
Ọ̀kan lára àwọn ohun tí wọ́n sábà máa ń lò Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù fún ni kí ẹgbẹ́ kan ṣẹ̀dá tọ́kẹ̀n kan tí o ṣe é tà, èyí tó dàbí owó tiwọn. Àwọn tọ́kẹ̀n yìí má ń tẹ̀lé àwọn ìlànà, ERC 20. Àmọ́ ṣá o, níbikíbi tí òfin bá ti fàyè gba àwọn nǹkan tó níye lórí, àwọn ọ̀daràn tó máa ń gbìyànjú láti jí nǹkan tó níye lórí náà máa ń wà.
Ọ̀nà méjì ni wọ́n lè gbà láti tàn ẹ́ jẹ:
- Títa ẹ̀dà owó àmi ẹ̀tàn kan fún ọ, èyí tó lè dà bí tọ́kẹ̀n tó jẹ́ ògidì, ṣùgbọ́n tí àwọn oní jìbìtì ṣe, tí kò sì níye lórí rárá.
- Títan ni jẹ láti buwọ́lu àwọn àdéhùn tí ó jẹ́ ayédèrú ìṣòwò, lọ́pọ̀ ìgbà nípa dídarí rẹ lọ síbi ohun elo tiwon. Wọ́n lè gbìyànjú láti mú kí o fún àwọn àdéhùn wọn ní owó òòyà lórí àwọn tọ́kẹ̀n ERC-20 rẹ, èyí tí yóò tú àṣírí àwọn ìsọfúnni rẹ tó ṣe kókó, tí yóò fún wọn ní ààyè sí àwọn ohun ìní rẹ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ojúewé oníṣe wọ̀nyí lè jẹ́ àdàkọ tí ó fẹ̀ẹ́ fara pẹ́ ti àwọn ojúewé tí ó jẹ́ ògidì, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àwọn ẹ̀tàn tí ó pamọ́.
Láti ṣe àpèjúwe àwọn àmì ẹ̀tàn yìí, a yóò wo àpẹrẹ kan: wARB
(opens in a new tab). Tọ́kẹ̀n yìí ń gbìyànjú láti dàbí àmì ARB
(opens in a new tab) tí ó jẹ́ ògidì.
Báwo ni àwọn tọ́kẹ̀n ẹ̀tàn ṣe ń ṣiṣẹ́?
Gbogbo ohun tí Ethereum wà fún ni aláìní ìṣàkóso. Èyí túmò sí pé kò sí aláṣẹ àárín gbùngbùn tí o le gba àwọn òhun ìní rẹ tàbí ṣe ìdíwọ́ fún ọ láti ṣe àgbéjáde àdéhùn ọlọ́gbọ́n. Àmọ́ ó túmọ sí pé àwọn oní jìbìtì le ṣe àgbéjáde àdéhùn ọlọ́gbọ́n tó wù wọ́n.
Ni pato, Arbitrum gbe adehun kan ti o lo aami ARB
. Ṣugbọn iyẹn ko da awọn eniyan miiran duro lati tun gbe adehun ti o lo aami kanna gangan, tabi ọkan ti o jọra. Ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìwé àdéhùn náà ló máa pinnu ohun tí ìwé àdéhùn náà máa ṣe.
Kò dà bí Ojúlówó
Àwọn ẹ̀tàn bíi mélòó kan wà tí àwọn tó ń ṣe ayédèrú tọ́kẹ̀n máa ń lò láti farahàn bíi Ojúlówó.
Orúkọ àti àmì ti ojúlówó. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ti sọ tẹ́lẹ̀, àwọn àdéhùn ERC-20 le ní àmì àti orúkọ kannáà bí àwọn àdéhùn ERC-20 mìíràn. O ò le gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọ̀nà yìí fún ààbò.
Oní ǹkán lọnà òtítọ́. Àwọn àmì ẹ̀tàn nígbàgbogbo má ń ṣe ìfiránṣẹ́ àwọn iye owó tó pọ̀ sínú àdírẹ́ẹ̀sì tí ó dàbí ojúlówó oníhun àwọn tọ́kẹ̀n ojúlówó.
Fún àpẹrẹ, ẹ jẹ ká tún wo
wARB
lẹ́ẹ̀kansi. Ó fẹ́rẹ̀ tó 16% àwọn tọ́kẹ̀n yìí(opens in a new tab) tí ó wà nínú àwọn àdírẹ́ẹ̀sì tí ìdánimọ̀ wọn jẹ́ Arbitrum Foundation: Deployer(opens in a new tab) tí ó farahàn sí gbogbo èèyàn. Èyí kìí ṣe àdírẹ́ẹ̀sì èké, kódà, ó jẹ̀ àdírẹ́ẹ̀sì tí ó lo àdéhùn ARB tòótọ́ lórí ẹ̀rọ Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù(opens in a new tab).Nítorí pé iye owó ti àdírẹ́ẹ̀sì ERC-20 jẹ́ ọ̀kan lára ìpamọ́ àdéhùn ERC-20, ó lè jẹ́ èyíkèyí tí àdéhùn náà bá sọ pé ó jẹ́. Ó tún ṣeé ṣe fún àdéhùn láti dènà ìfowóránṣẹ́ láti máà jẹ́ kí àwọn ojúlówó olùmúlò baà lè má kó àwọn ayédèrú tọ́kẹ̀n wọ̀nyẹn kúrò.
Ìfowóránṣẹ́ ojúlówó: . Àwọn oní ńkan tó jẹ́ ojúlówó kò ní sanwó láti fi tọ́kẹ̀n ẹ̀tàn ránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn, nítorí náà, bí wọ́n bá fi owó ránṣẹ́, ó ní láti jẹ́ èyí tó tó jẹ́ ojúlówó àbí?bẹ́ẹ̀ kọ́.
Àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ìfiránsẹ́
ni a ṣe nípasẹ̀ àdéhùn ERC-20. Ẹni tó ń tanni jẹ lè kọ ìwé àdéhùn náà lọ́nà tó máa mú kó ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀.
Àwọn ìkànnì ayédèrú
Àwọn oníjìbìtì tún lè ṣe àwọn ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó dáńgájíá gan-an, nígbà míì wọ́n lè ṣe àdàkọ ojúlówó ìkànnì pẹ̀lú àwọn àdàkọ UI tó fara jọra, àmọ́ wọ́n máa ń lo àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí kò farahàn. Àpẹẹrẹ lè jẹ àwọn ojú ọ̀nà ìtọ́kasí ti orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí ó farajọ ojúlówó sùgbọ́n tí ó ń gbé àwọn olùṣàmúlò lọ sí ojú-ewé ẹ̀tàn mìíràn, tàbí àwọn ìkànnì tí kò tọ̀nà tí ó ń darí olùṣàmúlò láti fi àwọn bọ́tìnì ìpamó wọn hàn tàbí tí ó ń rán owó lọ sí àdírẹ́sì oní jìbìtì.
Ohun tó dára jù lọ láti yẹra fún èyí ni láti farabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò URL fún àwọ ìkànnì tí o lọ, kí o sì fi àwọn àdírẹ́ẹ̀sì fún àwọn ìkànnì tí o mọ̀ pé ó jẹ́ ojúlówó sínú àwọn àlàfo rẹ. Lẹ́yìn náà, o lè wọlé sí ojúlé ojúlówó náà nípasẹ̀ àwọn àlàfo rẹ láìṣe àṣìṣe tàbí gbígbára lé àwọn ọ̀nà ìtọ́kasí ìta.
Báwo lo ṣe lè dáàbò bo ara rẹ?
Ṣàyẹ̀wò àdírẹ́sì àdéhùn náà. Àwọn tọ́kẹ̀n ojúlówó wá látọ̀dọ̀ àwọn àjọ ojúlówó o sì lè rí àwọn àdírẹ́sì àdéhùn náà lórí ìkànnì àjọ náà. Fún àpẹẹrẹ, fún
ARB
o le wo àwọn àdírẹ́sì tí ó tọ́ níbí(opens in a new tab).Àwọn tọ́kẹ̀n gidi ní owó tí wọ́n ń ná. Ọ̀nà mìíràn ni láti wo ìwọ̀n owó lórí Uniswap(opens in a new tab), ọ̀kàn nínú àwọn ìlànà pàsípààrọ̀ tọ́kẹ̀n tí ó wọ́pọ̀ jùlọ. Ìlànà yìí ń ṣiṣẹ́ nípa lílo adágún owó fún ìṣòwò, nínú èyí tí àwọn olùdókòòwò fi àwọn tọ́kẹ̀n wọn sínú ní ìrètí fún èrè láti ìdíyelé ìṣòwò.
Àwọn tọ́kẹ̀n èké sábà máa ń ní owó kékeré, bí ó bá ní rárá, nítorí pé àwọn oníjìbìtì kì í fẹ́ fi àwọn ohun ìní gidi wewu. Fun apẹẹrẹ, adágún ARB
/ETH
Uniswap ní bíi mílíọ̀nù kan dọ́là (wòó níbí fún iye tó jẹ́ lọ́wọ́lọ́wọ́(opens in a new tab)) àtipé rírà àti títà iye kékeré kò le yí iye owó padà:
Sùgbọ́n nígbàtí o bá gbìyànjú láti ra tọ́kẹ̀n ẹ̀tàn wARB
, kódà ìṣòwò kékeré kan yóò yí iye owó padà ní ìdá àádọ́rùn-ún – 90%:
Èyí tún jẹ́ ẹ̀rí mìíràn tó fi hàn pé kò ṣeé ṣe kí wARB
jẹ́ tọ́kẹ̀n ti ojúlówó.
Wo inú Etherscan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ tọ́kẹ̀n ayédèrú ni a ti mọ̀ tí àwọn ará àwùjọ ti ròyìn wọn. Irú àwọn tọ́kẹ̀n bẹ́ẹ̀ ni a fi àmì sí nínú Etherscan(opens in a new tab). Lóòótọ́ Etherscan kìí ṣe orísun àṣẹ ti òtítọ́ (ó jẹ́ ìṣẹ̀dá tí àwọn nẹ́tíwọ̀ọ̀kì tí kò ní àkóso pé kò le sí orísun apàṣẹ fún ìfúnni ní ojúlówó), àwọn tọ́kẹ̀n tí Etherscan ṣe ìdánimọ̀ bí ayédèrú ṣe é ṣe kò jẹ́ ayédèrú.
Conclusion
Níwòn ìgbà tí iye bá wà ní àgbáyé, àwọn oní jìbìtì yóò wà tí yóò gbìyànjú láti jalè iye náà fún ara wọn. Àti pé, ní àgbáyé tí kò ní àkóso àárín gbùngbùn, kò sí ẹnikẹ́ni láti dáàbòbo ìwọ àyàfi ara rẹ. A nírètí wípé óò rántí àwọn kókó wọ̀nyí láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dá àwọn ojúlówó tọ́kẹ̀n yàtọ̀ sí àwọn ayédèrú:
- Àwọn tọ́kẹ̀n ayédèrú ṣe bí àwọn tọ́kẹ̀n tòótọ, wọn le lo orúkọ kannáà, àmì ìdánimọ̀ kànnà, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
- Àwọn tọ́kẹ̀n ayédèrú kò le lo àdírẹ́ẹ̀sì àdéhùn kannáà.
- Orísun tó dára jùlọ fún tọ́kẹ̀n tí o jẹ́ ojúlówó ní ìkànnì àgbájọ tí o ṣe tọ́kẹ̀n náà.
- Tí o bá kùnà ìyẹn, o le lo ohun èlò gbajúgbajà, tí o ṣe f'ọkàn tán bíi Uniswap(opens in a new tab) àti Etherscan(opens in a new tab).