Bí o ṣe lè fagilé ìráàyèsí ti àdéhùn ọlọgbọ́n sí àwọn owo crypto rẹ
Itọsọna yii yoo kọ ọ bi o ṣe le wo atokọ ti gbogbo ti o ti gba laaye lati wọle si awọn owo rẹ ati bi o ṣe le fagile wọn.
Nígbà míì àwọn olùdàgbà tí wọ́n ní èrò búburú máa ń kọ àwọn ẹnubodè ẹ̀yìn sínú àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n tí wọ́n máa ń jẹ́ kí wọ́n lè wọlé sí owó àwọn oníṣe tí kò mọ̀ tí wọ́n bá ń bá àdéhùn ọlọ́gbọ́n náà lò. Ohun tí ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni wípé irú àwọn pẹpẹ bẹ́ẹ̀ máa ń béèrè fún ààyè láti ná àìmọye àwọn tọ́kẹ̀n ní ìsapá láti fi àpò kékeré ti pamọ́ ní ọjọ́ iwájú, ṣùgbọ́n èyí máa ń wá pẹ̀lú ewu tó pọ̀ sí i.
Lọgan ti pẹpẹ kan ba ni awọn ẹtọ wiwọle ailopin si tọ́kẹ̀n kan lori rẹ, wọn le lo gbogbo awọn tọ́kẹ̀n wọnyẹn paapaa ti o ba ti yọ owo rẹ kuro lati pẹpẹ wọn sinu woleeti rẹ. Àwọn òṣìṣẹ́ burúkú ṣì lè wọlé sí owó rẹ kí wọ́n sì yọ wọ́n sínú woleeti wọn láìsí àbájáde ìmúbọ̀sípò fún ọ.
Àwọn ààbò kan ṣoṣo ni láti yẹra fún lílo àwọn iṣẹ́ tuntun tí a kò tíì dán wò, fọwọ́ sí èyí tí o nílò nìkan, tàbí kí o máa dáwọ́ wíwọlé padà déédéé. Báwo lo ṣe ń ṣe é?
Igbesẹ 1: Lo àwọn irinṣẹ́ àǹfààní ìgbàpadà ìráyèsí
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkànnì ló jẹ́ kí o wo àti fagídí àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n tí ó so mọ́ adirẹsi rẹ. Lọ si oju opo wẹẹbu ki o so apamọwọ rẹ pọ:
- Ethallowance(opens in a new tab)(Ethereum)
- Etherscan(opens in a new tab)(Ethereum)
- Cointool(opens in a new tab) (onírúurú nẹtiwọki)
- fífagi lée(opens in a new tab) (onírúurú nẹtiwọki)
- Unrekt(opens in a new tab) (onírúurú nẹtiwọki)
- EverRevoke(opens in a new tab) (onírúurú nẹtiwọki)
Igbesẹ 2: So wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ pọ̀
Lọ́gán tí o bá ti wà lórí wẹ́ẹ̀bù náà tẹ̀ s’orí “Ṣe isopọ̀ wọ́lẹ́ẹ́tì”. Ojú-ìkànnì náà yóò sọ fún ọ láti so wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ pọ̀.
Rii daju pe o lo nẹtiwọọki kanna ninu woleeti rẹ ati oju opo wẹẹbu rẹ. Ìwọ yóò kàn rí àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n nìkan tí ó ní ìbátan sí nẹtiwọọki tí o yàn. Fún àpẹẹrẹ, tí o bá sopọ̀ sí ẹ̀rọ Ethereum, ìwọ yóò rí àwọn àdéhùn Ethereum nìkàn, kìí ṣe àwọn àdéhùn láti àwọn ẹ̀rọ mìíràn bíi Polygon.
Igbesẹ 3: Yan àdéhùn ọlọ́gbọ́n tí o fẹ́ fagilé
Ó yẹ kí o rí gbogbo àwọn àdéhùn tí o gbà láàyè wíwọlé sí àwọn àmì rẹ̀ àti ààlà ìnáwó wọn. Wa ọ̀kan tí o wù ọ́ láti fagilé.
Tí o kò bá mọ èyí tí o f yàn, o le fagilé gbogbo wọn. Ko le dá wàhálà kankan sílẹ̀ fún ọ, ṣùgbón wàá ní láti ṣe igbani láàyè tuntun nígbà mìíràn tí o bá fẹ lo èyíkéyìí àwọn àdéhùn yìí.
Ìgbésẹ kẹrin: ṣe ìgbàpadà ìgbà láàyè sí àwọn owó rẹ
Lọ́gán tí o bá ti tė sórí fagilé, ó yẹ kí o rí àwọn àbá ìṣòwò tuntun nínú wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ. Ó yẹ kí o ní ìrètí èyí. Wàá ní láti san ọ̀yà fún fí fagilé kí ó tó lọ. Ní ìbámu pẹlú nẹtiwọọki èyí le gbà láti iṣẹ́jú kan sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́jú láti ṣe é ṣe.
A gbà ọ níyànjú láti ṣe àtúnṣe sí ẹ̀rọ ìfagilé rẹ lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀, kó o sì tún so wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ mọ́ ọn láti fi ṣàyẹ̀wò bóyá àdéhùn tí a ti fagi lé náà ti parẹ́ kúrò nínú àkọsílẹ̀.
A gbà ọ́ níyànjú pé kí o má ṣe gba àwọn iṣẹ́ àkànṣe láàyè láti wọlé sí àwọn tọ́kẹ̀n rẹ lálàì lópin àti fagilé gbogbo àwọn ìgbaniláàyè fún ìwọlé tọ́kẹ̀n nígbàgbogbo. Yíyọ ìgbà láàyè sí àwọn tọ́kẹ̀n kò gbọdọ̀ yọrí sí ìpàdánù àwọn owó rẹ, pàtàkì jùlọ tí o bá ló ọkàn nínú àwọn ohun èlò tí a kà sílẹ lókè.Awon ibere gbogbo ìgbà
Ṣé yíyọ ìgbaniláàyè fún tọ́kẹ̀n tún mú ìfòpin sí ìdókòwò, dídá owó jọ, yíyá ni lówó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ?
Rárá, kò ní ní ipa lórí èyíkéyìí àwọn ìlànà . O ma wà ní àwọn ipò rẹ wàá sí má gba àwọn èrè àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Ṣe yíyọ wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ kúrò lórí iṣẹ àkànṣe jẹ́ nkan náà yíyọ ìgbanilááyè láti lo owó mi?
Rárá o, bí o bá yọ wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ kúrò nínú iṣẹ́ àkànṣe náà, ṣùgbọ́n o ti fún wọn ní àyè fún tọ́kẹ̀n, wọ́n ṣì lè lo àwọn tọ́kẹ̀n náà. O nilo lati fagile awọn ọna wọnyii.
Ìgbà wo ni àṣẹ fún àdéhùn náà yóò dópin?
Kò sí ọjọ́ tí àwọn ìwé àṣẹ tí wọ́n fúnni ní àdéhùn máa ń dópin. Tó o bá fún àwọn àdéhùn láṣẹ, wọ́n lè máa lò ó, kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti fún wọn.
Kí ló dé tí àwọn iṣẹ́-àkànṣe fi ń ṣètò tọ́kẹ̀n tí kò ní ààlà?
Awọn iṣẹ akanṣe nigbagbogbo ṣe eyi lati mu adinku ba iye awọn ibeere ti o nilo, itumo nipe olumulo nikan ni lati fọwọsi lẹẹkan ati san owo idunadura nikan lẹẹkan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó rọrùn, èyí lè jẹ́ ewu fún àwọn onímulo láti fọwọ́ sí i láìronújinlẹ̀, lórí àwọn ìkànnì tí a kò fi ìgbà hàn tàbí tí a kò ṣàyẹ̀wò. Diẹ ninu awọn woleeti gba ọ laaye lati fi ọwọ ṣe idiwọn iye awọn token ti a fọwọsi lati ṣe idiwọn eewu rẹ. Wá ìsọfúnni síwájú sí i lọ́dọ̀ ẹni tó ń pèsè wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ.