Bí o ṣe lè lo wọ́lẹ́ẹ́tì kan
Kọ ẹkọ bi o ṣe le ṣiṣẹ gbogbo awọn iṣẹ ipilẹ ti woleeti kan. Bí o kò bá tí ní ìkan tẹ́lẹ̀, yẹ ìkànnì wa lóri Bí o ṣe lè ṣẹ̀dá àkántì Ethereum kan wò.
Ṣí wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ
O yẹ kó o rí dáṣíbọ́ọ̀dù kan tó ṣe àfihàn iye owó rẹ, tó sì ní àwọn bọ́tìnì láti ṣe ìfiránṣẹ́ àti láti gba owó.
Gba owó cryptocurrency
Ṣé o fẹ́ gba owó crypto sínú wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ?
Àkántì Ethereum kọ̀ọ̀kan ní àdírẹ́sì tirẹ̀ tí ó jẹ́ àwọn nọ́ńbà àti lẹ́tà tí ó tò ni tẹ̀lé ǹ tẹ̀lé. Àdírẹ́sì náà dà bí nọ́ńbà àkáǹtì ilé ìfowópamọ́. Àwọn àdírẹ́sì Ethereum yóò máa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú “0x” ní gbogbo ìgbà. O le pín àdírẹ́sì yìí pẹ̀lú ẹnikẹ́ni: kò so sí ewu láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Bíi ti àdírẹ́sì ilé rẹ ni àdírẹ́sì Ẹ̀tẹ́ríọ̀mù rẹ ṣe rí: o ní láti sọ ó fún àwọn èèyàn kí wọ́n lè rí ọ. O lè ṣe èyí láìséwu, nítorí pé o ṣì lè fi kọ́kọ́rọ́ mìíràn tí ìwọ nìkan lè lò láti ti ilẹ̀kùn rẹ kí ẹnikẹ́ni má bàa wọlé, kódà bí wọ́n bá tiẹ̀ mọ ibi tó o ń gbé.
O ní láti fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ fi owó ránṣẹ́ sí ọ ní àdírẹ́sì rẹ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun èlò wọ́lẹ́ẹ́tì ló jẹ́ kí o ṣe àdàkọ adirẹsi rẹ tàbí kí o fi kóòdì QR hàn fún lílò tó rọrùn. Yẹra fún títẹ èyíkèyí adirẹsi Ethereum rẹ pẹ̀lú ọwọ́. Èyí lè mú àṣìṣe wá nígbà tí o bá ń kọ ọ́ sílẹ̀, kí o sì pàdánù owó.
Àwọn ohun èlò orísirísi le yàtọ̀ síra tàbí lo èdè tí ó yàtọ̀, sùgbọ́n wọ́n yẹ kí wọ́n mú ọ gba ìlànà tí ó jọra tí o bá ń gbìyànjú láti fi owó ránṣẹ́.
- Sí ohùn èlò wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ.
- Tẹ sórí "Gbà" (tabi ọ̀rọ̀ mìíràn tí o súnmọ́).
- Ṣe àdàkọ àdírẹ́ẹ̀sì Ethereum rẹ.
- Pèsè àdírẹ́ẹ̀sì Ethereum rẹ fún ẹni tí ó fẹ́ ṣe ìfiránṣẹ́.
Fi owó crypto ránṣẹ́
Ṣé o fẹ́ fi ETH ránṣẹ́ sí wọ́lẹ́ẹ́tì mìíràn?
- Sí ohùn èlò wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ.
- Gba àdírẹ́ẹ̀sì olùgbà kí o sì ri dájú wípé o wà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú nẹ́tíwọ̀ọ̀kì kannáà bíi ti olùgbà rẹ.
- Tẹ àdírẹ́ẹ̀sì olùgbà tàbí kí o fi kámẹ́rà rẹ ṣàyẹ̀wò kóòdì QR kó o má bàa máa fi ọwọ́ kọ àdírẹ́sì náà.
- Tẹ sórí bọ́tìnì “fi ránṣẹ́” nínú wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ (tabi ọ̀rọ̀ mìíràn tí o súnmọ́).
- Ọ̀pọ̀lopọ̀ àwọn ohun ìní, bíi DAI tàbí USDC, wà lórí àwọn nẹ́tíwọ̀ọ̀kì púpọ̀. Nígbà tí o bá ń fi àwọn owó kírípítò ránṣẹ́, rí i dájú pé ẹni tó ń gbà á ń lo nẹ́tíwọ̀ọ̀kì kan náà bíi èyí tí ìwọ náà ń lò, níwọ̀n ìgbà tójẹ́pé àwọn èyí kì í ṣe èyí tí a lè pààrọ̀.
- Ríi dájú wípé àpamọ́wọ́ rẹ ní owó tí ó tó fún owó ìdúnàdúrà, èyítí ó le yàtọ pẹ̀lú ipò nẹ́tíwọ̀ọ̀kì. Púpọ̀ àwọn wọ́lẹ́ẹ́tì yóò ṣàfikún owó ìdábàá sí owó ìdúnàdúrà láìfọwọ́yí èyítí o le jẹ́ẹ̀rísí lẹ́yìn náà.
- Ní kété tó bá ti ṣe ìfiránṣẹ́ ìṣòwò rẹ, Iye kírípítò tí o ba èyí tí ó firánṣẹ́ mu yóò farahàn nínú àkántì olùgbà náà. Èyí le gba níbikíbi láti iṣẹ́jú àáyá sí iṣẹ́jú díẹ̀ èyí tí o dá l'órí ipò nẹ́tíwọ̀ọ̀kì l'àkókò náà.
Ìsopọ̀ sí àwọn iṣẹ́ àkànṣe
Àdírẹ́ẹ̀sì rẹ yóò jẹ́ bákan náà ní gbogbo iṣẹ́ àkànṣe Ethereum. O kò nílò láti forúkọsílẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan lórí èyíkèyí iṣẹ́ àkànṣe. Ní kété tí o bá tí ní wọ́lẹ́ẹ́tì kan, o lè so mọ́ èyíkéyìí iṣẹ́ àkànṣe Ethereum láì ṣàfikún ìsọfúnni kankan. Kò nílò àwọn àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì tàbí àwọn ìsọfúnni mìíràn tó jẹ́ ti ara ẹni.
- Lọ sí ìkànnì èyíkéyìí iṣẹ́ àkànṣe.
- Tí ojú-ewé wẹ́ẹ̀bù náà bá jẹ́ èyí tí ń ṣ’àpéjúwe ti iṣẹ́ náà, ó yẹ kí o ní àǹfàní láti tẹ bọ́tìnì "Ṣí ohun-èlò náà" lórí i rẹ̀ nínú àkójọ àsàyàn èyítí yóò gbé ọ sí orí wẹ́ẹ̀bù gangan.
- Lọ́gán tí o bá ti wà ní orí ohun èlò náà tẹ̀ s’orí “Ìsopò”.
- Yan wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ láti inú àwọn àsàyàn tí a ti pèsè kalẹ̀. Bí o kò bá rí wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ, ó lè wà ní ìsàlẹ̀ àṣàyàn “WalletConnect”.
- Buwọ́lu ìbéèrè ifọwọ́sí tó wà nínú wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ láti ṣètò ìsopọ̀ náà. Buwọ́lu ìsọfúnni yìí kò ní nílò ìnáwó ETH kankan.
- Òhun nìyẹn! Bẹ̀rẹ̀ sí ní lo ohun èlò náà. O le rí díẹ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àkànṣe tó wúni lóríojú-ewè Dapps wa.
Awon ibere gbogbo ìgbà
Tí mo bá ní àdírẹ́sì ETH kan, ṣé mo ní adirẹsi kan náà lórí àwọn blockchains míràn?
O le lo àdírẹ́ẹ̀sì kannáà lórí gbogbo àwọn blockchain tí o ní ìbámu pèlú EVM (tí o bá ní irú wọ́lẹ́ẹ́tì pẹ̀lú ọ̀rọ̀ gbolohun olùgbàpadà). Àtòjọ(opens in a new tab) yìí yóò fi hàn ọ́ àwọn blockchain tí o lè lò pẹ̀lú àdírẹ́sì kan náà. Díẹ̀ nínú àwọn blockchain, bí Bitcoin, ṣe ìmúse ìṣètò sí nẹ́tíwọ̀ọ̀kì tí ó yàtò pátápátá àti wípé o yóò nílò àdírẹ́ẹ̀sì tó yàtọ̀ pẹ̀lú ọ̀nà tó yàtọ̀. Tí o bá ní wọ́lẹ́ẹ́tì àdéhùn ọlọ́gbọ́n, ó yẹ kí o ṣàyẹ̀wò ojú òpó wẹ́ẹ̀bù ọjà rẹ̀ fún àlàyé díẹ̀ síi lórí blockchain wo ló ní àtìlẹ́yìn.
Ṣé mo lè lo àdírẹ́ẹ̀sì kan náà lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rọ?
Bẹ́ẹ̀ ni, o lè lo àdírẹ́sì kan náà lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rọ. Àwọn wọ́lẹ́ẹ́tì jẹ́ pẹpẹ lásán láti ṣ’àfihàn iye owó àti láti ṣe kàràkàtà, àkántì rẹ kò sí nínú wọ́lẹ́ẹ́tì náà, ṣùgbọ́n ó wà lórí blockchain.
Mi kò tí rí owó crypto náà gbà, níbo ni mo ti lè ṣayẹwo ipò ìdúnàádúrà?
O le lo àwọn aṣàwárí búlọ̀kù láti rí ipò ìdúnàádúrà ní ojú ẹsẹ̀. Gbogbo ohun tí o ní láti ṣe ni láti wá àdírẹ́sì wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ tàbí ìdánimọ̀ ìdúnàádúrà náà.
Ṣé mo lè fagi lé ìdúnàádúrà tàbí kí n dá ìdúnàádúrà padà?
Rárá o, tí o bá ti fọwọ́ sí ìdúnàádúrà kan, o kò lè fagilé ìdúnàádúrà náà.