Rékọjá sí àkóónú àkọ́kọ́

Kọ́ ẹ̀kọ́ Ibùdó

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ethereum

Ìtọ́sọ́nà ètò-ẹ̀kọ́ rẹ sí àgbáyé ti Ethereum. Kọ́ ẹ̀kọ́ bíi Ethereum ṣe ń ṣiṣẹ́ àti bí o ṣe lè sopọ̀ mọ. Ojú-ìwé yìí pẹ̀lú àwọn àròkọ ìmọ̀-ẹ̀rọ àti tí kìí ṣe ìmọ̀-ẹ̀rọ, àwọn ìtọ́sọ́nà, àti àwọn ohun èlò.

Kí ni Ethereum?

Àwọn owó crypto bíi bitcoin jẹ́ kí ẹnikẹ́ni lè fi owó ránṣẹ́ kárí ayé. Ethereum náà ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún lè ṣiṣẹ́ pẹ̀lú kóòdù tó lè jẹ́ kí àwọn ènìyàn ṣẹ̀dá àwọn ohun èlò àti àjọ orí ẹ̀rọ. Ó jẹ́ ohun tó ní agbára àti ìrọ̀rùn: èyíkéyìí ètò kọ̀ǹpútà lè ṣiṣẹ́ lórí Ethereum. Kọ́ ẹ̀kọ́ díẹ̀ síi, kí o sì wá bí o ṣe lè bẹ̀rẹ̀:

Kini Ethereum?

Tí o bá jẹ́ ẹni tuntun, bẹ̀rẹ̀ níbí láti kọ́ ìdí tí Ethereum fi jẹ́ pàtàkì.

Àpèjúwe ènìyàn kan tó ń wo inú ọjà bàsá, tó yẹ kí ó ṣojú Ethereum.
Kini Ethereum?

Kí ni ETH?

Ether (ETH) ni owó tó jẹ́ agbára nẹ́tíwọọkì Ethereum àti àwọn ohun èlò ẹ̀rọ.

Kí ni ETH?

Kí ni Web3?

Web3 jẹ́ àwòṣe fún ẹ̀rọ ayélujára láti ṣe ìdíyelé lórí àwọn ohun-iní ati ìdánimọ̀ rẹ̀.

Kí ni Web3?

Báwo ni máa ṣe lo Ethereum?

Lílo Ethereum lè túmọ̀ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. Bóyá o fẹ́ wọlé sí ohun èlò ẹ̀rọ kan, fi ìdánimọ̀ rẹ hàn lórí ayélujára, tàbí fi díẹ̀ nínú ETH ránṣẹ́. Ohun àkọ́kọ́ tí o máa nílò ni àkántì kan. Ọ̀nà tó sí rọrùn jùlọ láti ṣẹ̀dá àti wọlé sí àkántì kan ni lílo sọfitiwia tí a ń pè ní wọ́lẹ́ẹ́tì.

Kí ni wọ́lẹ́ẹ́tì?

Wọ́lẹ́ẹ́tì àyélujára dà bíi ojúlówó wọ́lẹ́ẹ́tí; Wọ́n ṣe àfipamọ́ ohun tí o nílò láti fìdí ìdánimọ̀ rẹ̀ múlẹ̀ àti láti wọlé sí àwọn ibi tó ṣe pàtàkì sí ọ.

Àpèjúwe ti róbọ́ọ̀tì kan.
Kí ni wọ́lẹ́ẹ́tì?

Wá wọ́lẹ́ẹ́tì kan

Ṣàwákirí àwọn wọ́lẹ́ẹ́tì tó dá lórí àwọn ẹ̀yà tó ṣe pàtàkì sí ọ.

Àtòjọ àwọn wọ́lẹ́ẹ́tì

Ethereum networks

Save money by using cheaper and faster Ethereum extentions.

Choose network

Àwọn nǹkan tó yẹ kí o ronú lé lórí nígbà tí o bá ń lo Ethereum

  • Ìdúnàádúrà Ethereum kọ̀ọ̀kan nílò owó kan ní ìrísí ETH, kódà tí o bá nílò láti gbé àwọn ààmì oríṣiríṣi tí a ṣe lórí Ethereum bíi stablecoins USDC tàbí DAI.
  • Owó sísan lè ga tó dá lórí iye àwọn ènìyàn tó ń gbìyànjú láti lo Ethereum, nítorí náà a dámọ̀ràn lílò Ìpele 2s.

Kí ní a ń lò Ethereum fún?

Ethereum ti yọrísí ìṣẹ̀dá àwọn ọjà àti iṣẹ́ tuntun tó lè mú ìdàgbàsókè bá àwọn ààyè oríṣiríṣi ti ìgbésí ayé wa. A ṣì wà ní àwọn ìpele ìbẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n nǹkan púpọ̀ wà tó yẹ kó máa múnú wa dùn.

Ìṣúnná aláìlákóso (DeFi)

Ṣàwárí ètò ìnáwó mìíràn tí a kọ́ láìsí àwọn ilé ìfowópamọ́, tí ó sì wà fún ẹnikẹ́ni.

Kí ni ìṣòwò aláìlákóso?

Stablecoins

Àwọn owó crypto tó ní àsopọ̀ sí iye ti owó kan, ọjà, tàbí ohun èlò ìnáwó mìíràn.

Kí ni àwọn stablecoins?

Àwọn tọ́kẹ̀n ohun ìní aláìlẹ́gbẹ́ (NFTs)

Ṣe aṣojú níní àwọn nǹkan tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀, láti iṣẹ́ ọnà sí àwọn ìwé ẹ̀rí ìní sí tíkẹ́ẹ̀tì eré.

Kí ni àwọn NFTs?

Àwọn àjò aláìlákóso (DAOs)

Fún ìmúlò àwọn ọ̀nà tuntun láti ṣètò iṣẹ́ láìsí alákóso.

Kí ni àwọn DAO?

Àwọn ohun èlò ẹ̀rọ aláìlákóso

Ṣẹ̀dá ètò ọ̀rọ̀-ajé orí ayélujára ti àwọn iṣẹ́ ẹlẹ́gbẹ́-sí-ẹgbẹ́.

Ṣàwárí dapps

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lílò tó ń yọjú

Àwọn ilé-iṣẹ́ olókìkí mìíràn tún wà tí a ṣẹ̀dá tàbí ń mú sunwọ̀n síi pẹ̀lú Ethereum:

Mú nẹ́tíwọọkì Ethereum lágbára

O lè ṣèrànwọ́ láti dáàbò bo Ethereum kí o sì gba àwọn ẹ̀bùn ní àkókò kan náà nípa ṣíṣòwò pẹ̀lú ETH rẹ̀. Àwọn àṣàyàn oríṣiríṣi wà fún ìdókòwò tó dá lórí ìmọ̀ ẹ̀rọ rẹ̀ àti iye ETH tó ní.

Ìdókòwò pẹ̀lú Ethereum

Kọ́ bí o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí fi ETH rẹ̀ ṣọ̀wọ̀.

Bẹ̀rẹ̀ sí ṣòwò

Ṣiṣe ipade kan

Kó ipa pàtàkì nínú nẹ́tíwọọkì Ethereum nípa mímú nódù kan ṣiṣẹ́.

Ṣiṣe ipade kan

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìlànà lílo Ethereum

Fún àwọn olùṣàmúlò tó nífẹ̀ẹ́ jù lọ sí abala ìmọ̀ ẹ̀rọ nẹ́tíwọọkì Ethereum.

Ìmúlò agbára

Mélòó ni agbára tí Ethereum ń lò?

Ṣé Ethereum jẹ́ aláwọ̀ ewé?

Ọ̀nà àfojúsùn Ethereum

Ọ̀nà àfojúsùn Ethereum jẹ́ kí ó ṣeé mú gbòòrò, ní ààbò, àti ìmúdúró díẹ̀ síi.

Ṣàwárí ọ̀nà àfojúsùn

Ìwé àlàyé Ethereum

Ojúlówó ìwé ìdámọ̀ràn Ethereum tí Vitalik Buterin kọ ní ọdún 2014.

Ka ìwé àlàyé

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwùjọ Ethereum

Àṣeyọrí ti Ethereum jẹ́ ọ̀pẹ́ sí àwùjọ tó fọkànsìn lọ́nà tó kàmàmà. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn tó ń fúnni níṣìírí tí wọ́n sì ń súnni ṣe nǹkan ń ṣèrànwọ́ láti mú kí ìran Ethereum tẹ̀síwájú, nígbà tí wọ́n tún ń pèsè ààbò fún nẹ́tíwọọkì náà nípasẹ̀ ìdókòwò àti ìṣàkóso. Ẹ wá dara pọ̀ mọ́ wa!

Ibùdó àwùjọ

Àwùjọ wa pẹ̀lú àwọn ènìyàn láti gbogbo ìpilẹ̀ṣẹ̀.

Àfiwé àkójọpọ̀ àwọn olùkọ́ ilé tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ papọ̀.
Ṣàwárí síi

Báwo ni mo ṣe le kópa?

Ìwọ (bẹ́ẹ̀ni, ìwọ!) a gbà ọ́ tọwọ́tẹsẹ̀ láti lọ́wọ́sí àwùjọ Ethereum.

Báwo ni mo ṣe le kópa?

Àwọn àwùjọ orí ayélujára

Àwùjọ́ ayélujára pèsè àǹfààní ńlá lati béère àwọn pàtó ibéère tàbí lati kópa.

Ṣé àwárí àwọn àwùjọ

Àwọn ìwé àti àwọn àkáálẹ̀ ẹ̀rọ-agbagbe

Àwọn ìwé nípa Ethereum

Àwọn àkáálẹ̀ ẹ̀rọ-agbagbe nípa Ethereum

  • Green Pill(opens in a new tab) Ṣàwárí àwọn ètò ọrọ̀-ajé crypto tó ń dá àwọn àbájáde rere sílẹ̀ fún àgbáyé
  • Zero Knowledge(opens in a new tab) Ó lọ jinlẹ̀ sínú ìmọ̀-ẹ̀rọ tí yóò pèsè agbára fún ojú òpó wẹ́ẹ̀bù aláìlákóso tó ń bọ̀ àti àwùjọ tó ń kọ́ èyí
  • Unchained(opens in a new tab) Ó jinlẹ̀ sínú àwọn ènìyàn tí wọ́n ń kọ́ íńtánẹ́ẹ̀tì aláìlákóso, àwọn ẹkùn réré ìmọ̀ ẹrọ yìí tó lè ṣàtìlẹyìn ọjọ́ iwájú wa, àti ara àwọn ọ̀rọ̀ tó le jùlọ nínú crypto, bíi ìlànà, ààbò àti ìpamọ́
  • The Daily Gwei(opens in a new tab) Awọn ìṣoníṣókí ìròyìn, ìmúdójúìwọ̀n àti ìtúpalẹ̀ Ethereum
  • Bankless(opens in a new tab) Ìtọ́sọ́nà sí owó Crypto

Ǹjẹ́ ojú-ìwé yìí ṣe ìrànlọ́wó?