Kí ni àwọn NFTs?
NFTs jẹ́ àwọn ààmì tó jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ kọọkan. NFT kọ̀ọ̀kan ní àwọn ohun-ìní tó yàtọ̀ (tí kìí ṣe owó) àti pé ó ṣọ̀wọ́n. Èyí yàtọ̀ sí àwọn ààmì bíi tàbí àwọn ààmì mìíràn tó dá lórí Ethereum bíi USDC níbi tí gbogbo ààmì jẹ́ kan náà, tí wọ́n ní àbùdá kan náà ('fungible'). O kò bìkítà nípa irú owó dọ́là wo ní pàtó (tàbí ETH) tí o ní nínú wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ, nítorí pé gbogbo wọn jọ ara wọn, iye wọn sì jẹ́ kan náà. Síbẹ̀síbẹ̀, o do bìkítà irú NFT kan pàtó tí o ní, nítorí gbogbo wọn ní àwọn àbùdá ara ẹni tó jẹ́ kí wọ́n yàtọ̀ sí àwọn mìíràn (‘tí kìí ṣe fungible').
Àrà ọ̀tọ̀ tí NFT kọ̀ọ̀kan ń gbanilááyè ìsàmìsí àwọn nǹkan bíi iṣẹ́ ọnà, àwọn ìkójọpọ̀, tàbí àwọn ohun ìní gidi pàápàá, níbi tí NFT aláìlẹ́gbẹ́ kan pàtó ti ń ṣojú fún ayé gidi àrà ọ̀tọ̀ kan pàtó tàbí ohun èlò orí ẹ̀rọ. Níní ohun ìní ni a lè ṣe àrídájú rẹ̀ ní gbangba lórí Ethereum .
Íńtánẹ́ẹ̀tì ti àwọn ohun-ìní
Àwọn NFT àti Ethereum yanjú díẹ̀ nínú àwọn ìṣòro tó wà lórí íńtánẹ́ẹ̀tì lónìí. Bí ohun gbogbo ṣe di dígítá díẹ̀ síi, ìnílò wà láti ṣẹ̀dá àwọn àbùdá ti àwọn ohun ti ara bíi àìtó, aláìlẹ́gbẹ́, ati ẹ̀rí ohun-ìní ní ọ̀nà tí kìí ṣe ìṣàkóso nípasẹ̀ àjọ àárín gbùngbùn kan. Fún àpẹrẹ, pẹ̀lú NFTs, o le ní fáìlì orin mp3 ní gbogbo àwọn ohun èlò ẹ̀rọ tó dá lórí Ethereum tí kò sì so mọ́ ohun èlò orin kan pàtó ti ilé-iṣẹ́ kan bí Spotify tàbí Apple Music. O lè ní àkọọ́lẹ̀ àjọlò orí ayélujára tí o lè tà tàbí pààrọ̀, ṣùgbọ́n kò lè jẹ́ gbígba kúrò lọ́wọ́ rẹ nípasẹ̀ olùpèsè pẹpẹ ètò àjọlò kan.
Èyí ni bí íńtánẹ́ẹ̀tì ti NFTs ṣe rí ní àfiwé sí íńtánẹ́ẹ̀tì ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ń lò lónìí...
Ìfiwéra
Íńtánẹ́ẹ̀tì NFT | Íńtánẹ́ẹ̀tì lónìí |
---|---|
O ní àwọn ohun ìní rẹ! Ìwọ nìkan ni o lè tà wọ́n tàbí kí o pààrọ̀ wọn. | O yá ohun ìní kan lọ́wọ́ àjọ kan, wọ́n sì lè gbà á lọ́wọ́ rẹ. |
Àwọn NFT jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ dígítà , kò sí àwọn NFT méjì tó jẹ́ ìkan náà. | Àdàkọ kan kì í sábà ṣeé dá yàtọ̀ sí ti ojúlówó. |
Oní NFT wà ní ìpamọ́ lórí blockchain fún ẹnikẹ́ni láti jẹ́rìísi ní gbangba. | Ìráàyèsí sí àwọn àkọsílẹ̀ nípa ẹni tó ni àwọn ohun dígítà jẹ́ ìṣàkóso nípasẹ̀ àwọn ilé-isẹ́ – o gbọ́dọ̀ gba ọ̀rọ̀ wọn gbọ́. |
Àwọn NFT jẹ́ àwọn lórí Ethereum. Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n lè lo pẹ̀lú ìrọ̀rùn nínú àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n àti ohun èlò ẹ̀rọ mìíràn lórí Ethereum! | Àwọn ilé-iṣẹ́ tó ní àwọn ohun dígítà sábà máa ń máa nílò ohun ìní "ọgbà tó ní ògiri" tiwọn. |
Àwọn ẹlẹ́dàá àkóónú lè ta iṣẹ́ wọn níbikíbiwọ́n sì lè ráàyèsí ọjà àgbáyé. | Àwọn ẹlẹ́dàá gbára lé àwọn nǹkan àti pínpín àwọn ìkànnì tí wọ́n ń lò. Àwọn nǹkan wọ̀nyí sábà máa ń wà lábẹ́ àwọn ìlànà lílò àti àwọn ààlà nípa àgbègbè. |
Àwọn olùdásílẹ̀ NFT lè ní ẹ̀tọ́ ìní lórí iṣẹ́ wọn, kí wọ́n sì ṣètò owó ẹ̀tọ́ ní tààràtà sínú àdéhùn NFT. | Àwọn ìkànnì, bíi orin àwọn iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́, ni ó ń gba èyí tó pọ̀ jù nínú èrè tí wọ́n ń rí nínú ọjà tí wọ́n tà. |
Kí ni a ń lo NFTs fún?
NFTs ni a ń lò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nǹkan, tó pẹ̀lú:
- ṣíṣe ìjẹ́rìísí pé o lọ síbi ayẹyẹ kan
- fi hàn pé o ti parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan
- àwọn ohun tí a lè ní fún eré ìdárayá
- iṣẹ́ ọnà orí ẹ̀rọ
- fífi àwọn ohun ìní gidi ṣe ààmì
- fífi ẹ̀rí ìdánimọ̀ rẹ hàn lórí ayélujára
- ríráàyèsí àkóónú
- jíjá tíkẹ́ẹ̀tì
- àwọn orúkọ ìkànnì orí ayélujára aláìlákóso
- ohun ìṣèdúró nínú
Bóyá o jẹ́ oníṣẹ́ ọnà tó fẹ́ pín iṣẹ́ rẹ̀ nípa lílo NFTs, láì pàdánù àkóso àti fífi èrè rẹ rúbọ fún àwọn alárinà. O lè ṣẹ̀dá àdéhùn tuntun àti pàtó nọ́mbà àwọn NFT, àwọn àbùdá wọn àti ọ̀nà àsopọ̀ sí díẹ̀ nínú àwọn iṣẹ́ ọ̀nà pàtó. Gẹ́gẹ́ bíi oníṣẹ́ ọnà, o lè ṣètò sínú àdéhùn ọlọ́gbọ́n àwọn owó-orí tó yẹ kí o san (fún àpẹẹrẹ gbígbé 5% ti owó títà fún oní àdéhùn ní gbogbo ìgbà tí a bá gbé NFT kan). O tún lè fìdí rẹ múlẹ̀ pé o sẹ̀dá NFTs náà nítorí pé o ni tó mú àdéhùn náà ṣiṣẹ́. Àwọn oníbàárà rẹ lè fi hàn pé àwọn ní ojúlówó NFT kan láti inú àkójọpọ̀ rẹ nítorí pé wọ́lẹ́ẹ́tì wọn ní nǹkan ṣe pẹ̀lú àmì kan nínú àdéhùn ọlọ́gbọ́n rẹ. Wọ́n lè lò ó káàkiri àyíká Ethereum, ní ìdánilójú nínú ojúlówó rẹ̀.
Tàbí dábàá tíkẹ́ẹ́tì kan sí ìṣẹ̀lẹ̀ eré ìdárayá kan. Gẹ́gẹ́ bíi tí olùṣètò ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣe lè yan iye tíkẹ́ẹ́tì tí yóò ta, ẹlẹ́dàá NFT lè pinnu iye ẹ̀dà rẹ̀ tó wà. Nígbà mìíràn, ẹ̀dà rẹ̀ gan-an ni, irú bíi tíkẹ́ètì Gbígbàwọlé Gbogbogbò 5000. Nígbà mìíràn, wọ́n máa ń tẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n jọra gan-an, ṣùgbọ́n tí wọ́n yàtọ̀ díẹ̀ síra, irú bí tíkẹ́ètì pẹ̀lú ìjókòó tí a yàn. A lè rà wọ́n kí a sì tà wọ́n ní ẹlẹ́gbẹ́-sí-ẹgbẹ́ láì san owó fún àwọn alákóso tíkẹ́ẹ́tì àti oníbàárà nígbà gbogbo pẹ̀lú ìdánilójú ti ojúlówó tíkẹ́ẹ́tì náà nípa ṣíṣe àyẹ̀wò àdírẹ́sì àdéhùn náà.
Lórí ethereum.org, a máa ń lo NFTs láti fi hàn pé àwọn ènìyàn ti ṣàfikún tó ní ìtumọ̀ sí ibi ìpamọ́ Github wa (ṣètò ìkànnì náà, kọ tàbí ṣàtúnṣe àpilẹ̀kọ kan...), túmọ̀ àkóónú wa, tàbí kí wọ́n lọ síbi ìpè àwùjọ wa, a sì ní tún ti ní orúkọ ìkànnì NFT wa. Tí o bá ṣe lọ́wọ́sí ethereum.org, o lè béèrè NFT kan. Díẹ̀ nínú àwọn ìpàdé crypto ti lo àwọn POAP gẹ́gẹ́ bíi tíkẹ́ẹ́tì. Díẹ̀ síi lórí ìlọ́wọ́sí.
Ojú òpó wẹ́ẹ̀bù yìí tún ní orúkọ ìkànnì mìíràn tí NFTs ró lágbára, ehereum.eth. Àdírẹ́sì .org
wà ní ìṣàkóso olùpèsè ètò orúkọ ìkànnì (DNS) kan, nígbà tí a forúkọ ethereum.eth
sílẹ̀ lórí Ethereum nípasẹ̀ Iṣẹ́ Orúkọ Ethereum (ENS). Àwa la sì ní tí a sì ń ṣàkóso rẹ̀. Ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ ètò ENS wa(opens in a new tab)
Díẹ̀ si nípa ETH(opens in a new tab)
Báwo ni NFTs ṣe ń ṣiṣẹ́?
NFTs, like any digital items on the Ethereum blockchain, are created through a special Ethereum based computer program called a "smart contract". Àwọn àdéhùn wọ̀nyí máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà kan, bíi tàbí , èyí tó ń pinnu ohun tí àdéhùn náà lè ṣe.
Àdéhùn ọlọ́gbọ́n NFT lè ṣe àwọn nǹkan pàtàkì díẹ̀:
- Ṣẹ̀dá àwọn NFT: Ó lè ṣe àwọn NFT tuntun.
- Fífúnni ní olóhun ìní: Ó tọpinpin ẹni tó ni àwọn NFT wo nípa síso wọ́n pọ̀ pẹ̀lú àwọn àdírẹ́sì Ethereum kan pàtó.
- Fún NFT kọ̀ọ̀kan ní ìdánimọ̀ kan: NFT kọ̀ọ̀kan ní nọ́mbà tó jẹ́ kó jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́. Ní àfikún, àwọn àlàyé kan máa ń sábà wà (metadata) tó so mọ́ ọn, tó ń ṣàpèjúwe ohun tí NFT dúró fún.
Nígbàtí ẹnìkan bá "ṣẹ̀dá" tàbí "tẹ" NFT kan, wọ́n ń sọ fún àdéhùn ọlọ́gbọ́n láti fún wọn ní ìní NFT kan pàtó. Àlàyé yìí ni a fi pamọ́ lọ́nà tó ní ààbò àti ní gbangba nínú blockchain.
Síwájú síi, ẹlẹ́dàá ti àdéhùn náà lè ṣàfikún àwọn òfin. Wọ́n lè dín iye àwọn NFT kan tó lè ṣeé ṣe kù tàbí pinnu pé ó yẹ kí àwọn gba owó-orí kékeré nígbàkúùgbà tí NFT náà bá pààrọ̀ ọwọ́.
Ààbò NFT
Ààbò Ethereum wá láti . A ṣètò náà láti ṣe ìdíwọ́ ní ọ̀nà ọrọ̀-ajẹ́ fún àwọn iṣẹ́ tó ní ìpalára, mímú Ethereum ní ìdánilójú aláìlefọwọ́bà. Èyí ni ohun tó mu kí àwọn NFT lè ṣeé ṣe. Ní kété tí tó ní ìdúnàádúrà NFT rẹ ti yóò ná olùkolù ní mílíọ̀nù ETH láti yi padà. Ẹnikẹ́ni tó bá ń lo ẹ̀rọ Ethereum yóò ní àǹfààní lẹ́sẹkẹ́sẹ láti rí ìfọwọ́yí àìsòótọ́ pẹ̀lú NFT kan, a ó sì fìyà jẹ ẹni náà, a ó sì lé e kúrò.
Àwọn ọ̀ràn ààbò tó jọmọ́ àwọn NFT nígbà gbogbo ní ìbátan sí àwọn ìtànjẹ àṣírí ara rẹ, àwọn àìlágbára àdéhùn ọlọ́gbọ́n tàbí àwọn àṣìṣe olùṣàmúlò (gẹ́gẹ́ bíi ṣíṣafihàn àwọn kọ́kọ́rọ́ ikọ̀kọ̀ láìròtẹ́lẹ̀), ṣíṣe ààbò tó dára ti wọ́lẹ́ẹ́tì ní pàtàkì fún àwọn oní NFT.
Díẹ̀ síi lórí ààbòKíkà síwájú síi
- Ìtọ́sọ́nà ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ nínú NFTs(opens in a new tab) – Linda Xie, Oṣù kíní Ọdún 2020
- Alépa EtherscanNFT(opens in a new tab)
- Ìdíwọ̀n àmì ERC-721
- Ìdíwọ̀n àmì ERC-1155
- Àwọn Ohun Èlò Olókìkí àti Irinṣẹ́ NFT(opens in a new tab)