Kini ReFi?
Isuna isọdọtun jẹ eto awọn irinṣẹ ati awọn imọran ti a ṣe sori , ti o ni ero lati ṣẹda awọn ọrọ-aje eyiti o jẹ isọdọtun, dipo yiyọkuro tabi ilokulo. Nikẹhin, awọn ọna ṣiṣe iyọkuro dinku awọn ohun elo to wa ati ya lulẹ̀; laisi awọn ilana isodotun, wọn ko ni idurosinisin. ReFi ṣiṣẹ lori arosinu pe isẹda ti iye owo gbọdọ je yiyo kuro lara wiwa ti ko lagbero ti awon alumoni lati aye ati agbegbe wa.
Dipo, ReFi ni ero lati yanju ayika, agbegbe, tabi awọn iṣoro awujọ nipa ṣiṣẹda awọn iyipo isọdọtun. Awọn eto wọnyi ṣẹda iniyelori fun awọn olukopa nigbakanna nigbati o de n se anfaani fun awọn ayika ati awujo.
Ọ̀kan lára àwọn ìpìlẹ̀ ReFi ni èròǹgbà nípa ètò ọrọ̀ ajé isodotun tí John Fullerton ti Capital Institute ṣe aṣáájú ọ̀nà. O dabaa awọn ipilẹ ti o ni asopọ mẹjọ(opens in a new tab) ti o wa labẹ ilera eto:
Awọn iṣẹ akanṣe ReFi mọ awọn ipilẹ wọnyi nipa lilo ati awon ohun elo lati ṣe iwuri awọn ihuwasi isọdọtun, fun apẹẹrẹ mimu-pada sipo ayika eda ti o bajẹ, ati dẹrọ ifowosowopo iwọn nla lori awọn ọran agbaye gẹgẹbi iyipada oju-ọjọ ati ipadanu ipinsiyeleyele.
ReFi tun ṣe agbekọja pẹlu alailakoso imọ-jinlẹ (DeSci), eyiti o lo Ethereum bi pẹpẹ lati ṣe inawo, ṣẹda, atunyẹwo, kirẹditi, fipamọ, ati apinkiri imọ-jinlẹ. Awọn irinṣẹ DeSci le di iwulo fun idagbasoke awọn iṣedede to se jerii si ati awọn iṣe fun imuse ati abojuto awọn iṣẹ isọdọtun bii gbigbin awọn igi, yiyọ ike kuro ninu okun, tabi mimu-pada sipo ayika.
Siso awon kirediti erogba di token
Ọja erogba atinuwa (VCM)(opens in a new tab) jẹ ẹrọ fun igbeowosile awọn iṣẹ akanṣe ti o ṣe idaniloju ipa rere lori awọn itujade erogba, boya idinku awọn itujade ti nlọ lọwọ, tabi yiyọ awọn eefin to ti jade tẹlẹ si awosanma. Awọn iṣẹ akanṣe wọnyi gba dukia ti a pe ni “awọn kirẹditi erogba” lẹhin ti wọn ti jẹriisi, eyiti wọn le ta fun awọn eniyan kọọkan ati awọn ajọ ti o fẹ lati ṣe atilẹyin iṣe oju-ọjọ.
Ni afikun si VCM, ọpọlọpọ awọn ọja erogba ti ijọba-palaṣẹ tun wa ('awọn ọja ifaramọ') ti o ṣe ifọkansi lati fi idi idiyele erogba kan mulẹ nipasẹ awọn ofin tabi ilana laarin agbegbe kan pato (fun apẹẹrẹ orilẹ-ede tabi agbegbe), iṣakoso ipese awọn iyọọda ti yoo je pinpin. Awọn ọja ifaramọ ṣe iwuri fun awọn apanirun laarin agbegbe wọn lati dinku itujade, ṣugbọn wọn ko lagbara lati yọ awọn eefin ti o ti jade tẹlẹ.
Pelu idagbasoke rẹ ni awọn ọdun aipẹ, VCM tẹsiwaju lati jiya lowo ọpọlọpọ awọn ọran:
- Owo ti a pin si ona pupọ
- Awọn ilana idunadura to diju
- Awọn idiyele giga
- Iyara isowo to lọra pupọ
- Aini imu gbooro
Gbigbe VCM lọ si ọja erogba digita (DCM) ti o da lori blockchain le jẹ anfaani lati ṣe igbesoke imọ-ẹrọ ti o wa fun ijẹrisi, idunadura ati jijẹ awọn kirẹditi erogba. Blockchains ngbanilaaye fun data ijẹrisi ni gbangba, iraye si fun ọpọlọpọ awọn olumulo, ati owo diẹ sii.
Awọn iṣẹ akanṣe ReFi lo imọ-ẹrọ blockchain lati dinku ọpọlọpọ awọn iṣoro ti ọja ibile:
- Owo wa ni owo awon akojopo die kan ti o le wa fun isowo nipasẹ ẹnikẹni. Awọn ajo nla ati awọn olumulo kọọkan le lo awọn akojopo wọnyi laisi awọn awakiri afọwọṣe fun awọn olutaja/oluraja, awọn idiyele ikopa, tabi iforukọsilẹ ṣaaju.
- Gbogbo awọn idunadura ti wa ni igbasilẹ lori awọn blockchains ti gbogbo eniyan. Ọna ti kirẹditi erogba kọọkan gba nitori iṣẹ ṣiṣe iṣowo jẹ itọpa lailai ni kete ti o ti jẹ ki o wa ninu DCM.
- Iyara idunadura to fere jẹ lẹsẹkẹsẹ. Nini awọn iye erogba kirediti nla nipasẹ awọn ọja le gba awọn ọjọ tabi awọn ọsẹ, ṣugbọn eyi le ṣee ṣe ni iṣẹju-aaya diẹ ninu DCM.
- Iṣẹ ṣiṣe iṣowo waye laisi awọn agbedemeji, eyiti o n gba awọn idiyele giga. Awọn kirẹditi erogba digita ṣe aṣoju idinku idiyele pataki ni akawe si awọn kirẹditi ibile.
- DCM jẹ eyi to le gbooro ati pe o le koju awọn ibeere ti awọn eniyan kọọkan ati awọn ọpọlọpọ ile-iṣẹ ni awon orilẹ-ede bakanna.
Awọn eya pataki ti DCM
Awọn eroja pataki mẹrin ni o ṣe oju-aye lọwọlọwọ ti DCM:
- Awọn iforukọsilẹ gẹgẹbi Verra(opens in a new tab) ati Gold Standard(opens in a new tab) rii daju pe awọn iṣẹ akanṣe to n ṣẹda awọn kirẹditi erogba jẹ igbẹkẹle. Wọn tun ṣiṣẹ awọn apoti data ninu eyiti awọn kirẹditi erogba digita ti bẹrẹ ati pe o le gbe tabi lo tan (ti fẹyìntì).
Igbi tuntun ti awọn iṣẹ akanṣe tuntun wa ti a kọ sori awọn blockchains ti o ngbiyanju lati da awọn alaṣẹ ru ni eka yii.
- Awọn afara erogba, A.k.a. awon oni token, pese imo ero lati soju tabi gbe erogba kirediti lati awon iwe akosile ibile sinu DCM. Awọn apẹẹrẹ akiyesi pẹlu Ilana Toucan(opens in a new tab),C3(opens in a new tab), ati Moss.Earth(opens in a new tab).
- Awọn iṣẹ iṣọpọ nfunni ni iyago fun erogba ati/tabi awọn kirẹditi yiyọ kuro fun awọn olumulo ipari ki wọn le beere anfani ayika ti kirẹditi kan ati satilẹyin wọn fun iṣe oju-ọjọ pẹlu agbaye.
Diẹ ninu awon bii Klima Infinity(opens in a new tab) ati Senken(opens in a new tab) nfunni ni ọpọlọpọ awọn iṣẹ akanṣe ti o je dagbasoke nipasẹ awọn ẹgbẹ kẹta ati ti a fun ni labẹ awọn iṣedede ti iṣeto bi Verra; awọn miiran bii Nori(opens in a new tab) nikan nfunni ni awọn iṣẹ akanṣe kan ti o je dagbasoke labẹ idiwon kirẹditi erogba tiwọn, eyiti wọn funni ati fun eyiti wọn ni aaye ọja iyasọtọ tiwọn.
- Awọn nnkan abẹlẹ ati awọn amayederun ti o dẹrọ igbelosoke ti ipa ati ijafafa ti gbogbo oukn ipese ọja erogba. KlimaDAO(opens in a new tab) n pese owo bi ire ti gbogbo eniyan (n gba ẹnikẹni laaye lati ra tabi ta awọn kirẹditi erogba ni idiyele to se kedere), ṣe iwuri iṣelọpọ ni ppuọsi ti awọn ọja erogba ati awọn ifẹhinti pẹlu awọn ere, ati pese ohun elo ibaraenisepo ore-olumulo lati wọle si data nipa, bi daradara bi gbigba ati ifehinti, awon orisirisi ti kirediti erogba to di token.
ReFi tayo awọn ọja erogba
Botilẹjẹpe lọwọlọwọ ìtẹnumọ́ to lagbara lori awọn ọja erogba ni gbogbogbo ati yiyi VCM si DCM ni pataki laarin aaye naa, ọrọ naa “ReFi” ko ni opin si erogba. Awọn ohun-ini ayika miiran ti o kọja awọn kirediti erogba le ni idagbasoke ati siso di token, eyiti yoo tumọ si awọn ohun tita odi miiran tun le ṣe idiyele laarin awọn ipele ipilẹ ti awọn eto oro-aje ojo iwaju. Pẹlupẹlu, abala isọdọtun ti awoṣe eto-ọrọ aje yii le ṣee lo si awọn agbegbe miiran, gẹgẹbi igbeowosile ti awọn oja gbogbogbo nipasẹ awon pepe igbeowosile akojopo kuadiratiki bi Gitcoin(opens in a new tab). Awọn ile-iṣẹ ti a kọ lori imọran ikopa gbangba ati pinpin awọn ohun ini fun gbogbo eniyan ni agbara lati fi owo kun awọn iṣẹ akanṣe sọfitiwia orisun gbangba, ati eto ẹkọ, ayika, ati awọn iṣẹ akanṣe awujo.
Nipa yiyi idari ti owo kuro lati awọn iṣe yiyokuro si ṣiṣan isọdọtun, awọn iṣẹ akanṣe ati awọn ile-iṣẹ ti o pese awọn anfaani awujọ, ayika, tabi agbegbe-ati eyiti o le kuna lati ṣaṣeyọri igbeowosile ni isuna ibile-le lọ kuro ni ilẹ ati ṣe ipilẹṣẹ awọn ohun tita rere fun awujọ ati siwaju sii ni yarayara ati irọrun. Iyipada si awoṣe igbeowosile yii tun ṣi ilẹkun si awọn eto-ọrọ-aje alapapo diẹ sii, nibiti awọn eniyan ti gbogbo awọn ìsọfúnni nípa àwọn ènìyàn le di olukopa lọwọ to n sise ju awọn oluworan to palolo lasan. ReFi nfunni ni iran Ethereum gẹgẹbi ọna ṣiṣe fun ṣiṣakoṣo iṣe lori awọn ipenija ayeraye ti o dojukọ eya wa ati gbogbo igbesi aye ni agbaye wa-gẹgẹbi ipele ipilẹ ti apẹrẹ eto-aje tuntun kan, to jeki ọjọ iwaju to ni ifisi ati alagbero tunbo wa fun awọn ọgọrun ọdun to mbọ.
Afikun kika lori ReFi
- Kopọ ipele giga ti awọn owo erogba ati aye wọn ninu oro-aje(opens in a new tab)
- Ile-iṣẹ fun Ọjọ iwaju, aramada ti n ṣe afihan ipa ti owo to ni atilẹyin erogba ninu idoju ija ko ayipada oju-ọjọ(opens in a new tab)
- Ijabọ alaye nipasẹ Iṣẹ-ṣiṣe fun Iwọn Awọn ọja Erogba atinuwa(opens in a new tab)
- Kevin Owocki ati Evan Miyazono's Iwole Iwé atọ́ka CoinMarketCap lori ReFi ti Kevin Owocki ati Evan Miyazono(opens in a new tab)