Rékọjá sí àkóónú àkọ́kọ́

Ojú-ìwé tí a múdójúìwọ̀n gbẹ̀yìn: 18 Oṣù Ọ̀pẹ̀ 2024

Ìfilọ́lẹ̀ sí àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n

Àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n jẹ́ àwọn búlọ́ọ́kù kíkọ́ ìpìlẹ̀ ohun èlò Ethereum. Wọn jẹ awọn eto kọnputa ti a fipamọ sori ti o tẹle ọgbọn “ti o ba jẹ eyi leyin naa iyẹn”, ati pe o ni idaniloju lati ṣiṣẹ ni ibamu pelu awọn ofin ti asọye nipasẹ koodu rẹ, eyiti ko le yipada ni kete ti won ba ṣẹda re.

Nick Szabo seda ọrọ naa "adehun ọlọgbọn". Ní 1994, ó kọ ìfilọ̀sí èrò(opens in a new tab), àti ní 1996 ó kọ ìwádìí nípa ohun tí àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n lè ṣe(opens in a new tab).

Szabo fojú inú wo ìpàtẹ orí ayélujára níbití àwọn ìlànà àdáṣe, jẹ́ kí ìdúnàdúrà àti àwọn ìṣòwò le ṣeé ṣe láìsí àwọn alágbàtà tí a le gbẹ́kẹ̀lé. Àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n lórí Ethereum gbé ìran yìí sí ṣíṣe.

Wo bí Finematics ṣe ṣàlàyé àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n:

Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn àdéhùn àbáláyé

Ọ̀kan nínù àwọn ìṣòro ńlá pẹ̀lú àdéhùn ìbílẹ̀ ní ìlò fún àwọn ènìyàn tí a le gbẹ́kẹ̀lé láti ṣe àrídópin sí àwọn àbájáde àdéhùn náà.

Àpẹẹrẹ kan nìyí:

Alice àti Bob ń fi kẹ̀kẹ́ sáré. Ká sọ pé Alice fi $10 ta tẹ́tẹ́ wípé òun ni yóò borí nínú ìdíje náà. Bob ní ìdánilójú pé òun ni yóò borí, ó sì gbà láti ṣe tẹ́tẹ́ náà. Níkẹyìn, Alice parí eré náà ṣáájú Bob, ó sì jẹ́ olùborí tó fojúhàn. Àmọ́ Bob kọ̀ láti san owó náà, ó sọ pé Alice ti ṣe òjóró.

Àpẹẹrẹ òmùgọ̀ yìí jẹ́ ká rí ìṣòro tó wà nínú àdéhùn tí kò mọ́gbọ́n dání. Kódà, bí àwọn ipò tí ó wà nínú àdéhùn yìí bá di mímúṣẹ (ìyẹn ni pé ìwọ lo borí nínú ìdíje náà), o tún sí ní láti gbẹ́kẹ̀lé ẹnìkejì láti mú àdéhùn náà ṣẹ (ìyẹn ni pé èrè lórí tẹ́tẹ́ náà).

Ẹ̀rọ tó ń ta ọjà orí kọ̀ǹpútà

Àpèjúwe tí ó rọrùn fún àdéhùn ọlọ́gbọ́n jẹ́ ẹ̀rọ ìtajà, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ bíi ti àdéhùn ọlọ́gbọ́n - àwọn ohun tí ó wọlé pàtó ń ṣe ìdánilójú àwọn ohun tí yóò jáde tí a ti pinnu ṣáájú.

  • O yan ọjà kan
  • Ẹ̀rọ ìtajà náà ṣàfihàn iye owó ọjà
  • O san owó ọjà náà
  • Ẹ̀rọ tó ń ta ọjà náà á rí i dájú pé o san iye owó òtítọ́
  • Ẹ̀rọ ìtajà yìí fún ọ ní ọjà rẹ

Ẹ̀rọ tó ń ta ọjà yóò gbé ọjà rẹ jáde lẹ́yìn ìgbà tí gbogbo ohun tí wọ́n béèrè bá ti pé. Bí o kò bá yan ọjà kan tàbí fi owó tó tó, ẹ̀rọ ìtajà náà kò ní fún ọ ní ọjà rẹ.

Iṣẹ́ ṣíṣe aláìfọwọ́yí

Àǹfàní gbóògì ti àdéhùn ọlọ́gbọ́n ni wípé ó ṣe ìpinnu ṣíṣe kóòdù nígbàtí àwọn ipò kàn bá tí wà nílẹ̀. Kò sí ìdí láti dúró de ìgbà tí ẹ̀dá èèyàn kan bá wá túmọ̀ àbájáde èsì náà tàbí tí ó bá wa fi ọ̀rọ̀ wérọ̀ lórí rẹ̀. Èyí mùú kùrò ìsàmúlò àwọn alárinà tó ṣeé fọkàntán.

Fún àpẹẹrẹ, o lè kọ ìwé àdéhùn ọlọ́gbọ́n kan tó ní owó ní escrow fún ọmọdé, gbígbà wọn láàyè láti yọ owó kúrò lẹ́hìn ọjọ́ kan pàtó. Tí wọ́n bá gbìyànjú láti yọ́kúrò ṣáájú ọjọ́ yẹn, àdéhùn ọlọ́gbọ́n kì yóò ṣiṣẹ́. Tàbí o lè kọ ìwé àdéhùn tí yóò fún ọ ní ẹ̀yà dígítà tí àkọlé ọkọ̀ ayọkẹlẹ kan nígbàtí o bá san owó fún oníṣòwò náà.

Àwọn àbájáde àsọtẹ́lẹ̀

Àwọn àdéhùn ìbílẹ̀ jẹ́ àìgbọ́yé nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn láti túmọ̀ àti ìmúṣe wọn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn onídajọ́ méjì lè ṣe ìtumọ̀ àdéhùn ní ìyàtọ̀, èyí tó lè já sí àwọn ìpinnu àìṣedéédéé àti àwọn àbájáde àìdọ́gba. Àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n yọ ṣí ṣeé ṣe yìí. Dípo, àwọn ìwé àdéhùn ọlọ́gbọ́n ṣiṣẹ́ ní pípé tó dá lórí àwọn ipò tí a kọ láàrín kóòdù àdéhùn náà. Ìtọ́kasí yìí túmọ̀ sí pé fún àwọn ipò kan náà, àdéhùn ọlọ́gbọ́n yóò gbé àbájáde kan náà jáde.

Àkọsílẹ̀ fún gbogbo ènìyàn

Àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìwúlò fún àwọn ìṣàyẹ̀wò àti ìtọpinpin. Láti ìgbà tí àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n Ethereum wà lórí blockchain ti gbogbo ènìyàn, ẹnikẹ́ni lè ṣe ìtọpinpin gbígbé dúkìá àti àlàyé mìíràn tó ní ìbátan lẹ́sẹkẹ́sẹ. Fún àpẹẹrẹ, o lè ṣàyẹ̀wò láti ríi pé ẹnikan fi owó ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì rẹ.

Ìdáàbò bo àṣírí

Àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n tún dáàbò bo àṣírí rẹ. Níwọ̀n ìgbà tí Ethereum jẹ́ nẹ́tíwọọkì apésọ (àwọn ìdúnàádúrà rẹ jẹ́ àsopọ̀ ní gbangba pẹ̀lú àdírẹ́sì cryptography aláìlẹ́gbẹ́, kìí ṣe ìdánimọ̀ rẹ), o lè dáàbò bo àṣírí rẹ lọ́wọ́ àwọn aláfojúsí.

Àwọn òfin tó hàn

Lákòótán, bíi àwọn ìwé àdéhùn ìbílẹ̀, o lè ṣàyẹ̀wò kíni ó wà nínú àdéhùn ọlọ́gbọ́n ṣáájú kí o tó fọwọ́sí (tàbí bí bẹ́ẹ̀kọ ṣe àjọṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀). Akóyawọ àdéhùn tó gbọngbọ́n ṣe ìṣèdúró pé ẹnikẹ́ni lè ṣàyẹ̀wò rẹ̀.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lílo àdéhùn ọlọ́gbọ́n

Àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n lè ṣe pàtàkì ohunkóhun tí àwọn ètò kọ̀ǹpútà lè ṣe.

Wọ́n lè ṣe àwọn ìṣirò, ṣẹ̀dá owó, fi dátà pamọ́, ṣẹ̀dá , ṣàfiránṣẹ́ àwọn ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti pàápàá ṣàgbéjáde àwọn àwòrán. Èyí ni díẹ̀ nínú olókìkí, àwọn àpẹẹrẹ gidi-ayé:

  • Stablecoins
  • Ṣíṣẹ̀dá àti pínpín àwọn ohun-ìní dígítà aláìlẹ́gbẹ́
  • Àwọn pàṣípààrọ̀ owó gbangba àìfọwọ́yí
  • Eré ìdárayá aláìlákóso
  • Ètò ìmúlò ìbánigbófò tó ń sanwó làìfọwọ́yí(opens in a new tab)
  • Ìdiwọ̀n tó jẹ́ kí ènìyàn ṣẹ̀dá àwọn owó àdáni tó ṣe é lò lórí gbogbo ẹ̀rọ

Kíkà síwájú síi

Ǹjẹ́ àpilẹ̀kọ yìí ṣe ìrànlọ́wó?