Rékọjá sí àkóónú àkọ́kọ́

Àwọn nẹ́tíwọọkì àwùjọ tí kò ní àkóso

  • Àwọn pẹpẹ tó dá lórí Blockchain fún ìbáraẹniṣepọ̀ àwùjọ àti ìṣẹ̀dá àkóónú àti pínpín.
  • Awọn nẹtiwọọki ikanni ajolo alailakoso daabobo aṣiri olumulo ati mu aabo data pọ si.
  • Awọn token ati NFTs ṣẹda awọn ọna tuntun lati so akoonu di owo.

Awọn nẹtiwọki Awujọ mu ipa nla ninu awọn ibaraẹnisọrọ ojoojumọ wa ati awọn ibaraenisepo wa. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìdarí àpapọ̀ lórí àwọn ìkànnì wọ̀nyí ti dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro sílẹ̀: ìpalára fún ìsọfúnni, ìdàrúdàpọ̀ àwọn ohun-èlò-ìsọfúnni, dídàrú àwọn ìkànnì, ìdálẹ́kọ̀ọ́, àti ìpalára fún ìpamọ́-ẹni jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí àwọn ìkànnì àjọlò máa ń gbà yanjú ìṣòro. Lati dojuko awọn isoro wọnyi, awọn olupilẹṣẹ n kọ awọn nẹtiwọọki awujọ lori Ethereum. Awọn nẹtiwọọki awujọ alailakoso le ṣatunṣe ọpọlọpọ awọn iṣoro ti awọn ikanni nẹtiwọọki awujọ ibile ati imudara iriri gbogbogbo awọn olumulo.

Kini awọn nẹtiwọọki awujọ alailakoso?

Awọn nẹtiwọọki awujọ alailakoso jẹ awọn pepe to gba awọn olumulo laaye lati ṣe paṣipaarọ alaye ati se atẹjade ati pinpin akoonu si awọn olugbo. Nitoripe awọn ohun elo wọnyi nṣiṣẹ lori blockchain, wọn ni agbara lati wa ni alailakoso ati satako si ifofinde ati iṣakoso ti ko yẹ.

Pupọ awọn nẹtiwọọki awujọ alailakoso wa bi awọn omiiran si awọn iṣẹ ikanni ajolo to fidi mule, bii Facebook, LinkedIn, Twitter, ati Medium. Ṣugbọn awọn nẹtiwọọki awujọ to ni agbara blockchain ni awọn ẹya kan to fi wọn siwaju awọn pepe awujọ ibile.

Bawo ni awọn nẹtiwọki awujọ alailakoso ṣe n ṣiṣẹ?

Awọn nẹtiwọọki awujọ alailakoso jẹ kilasi ti awọn ohun elo alailakoso (dapps)— awọn ohun elo tio ni agbara nipasẹ ti a fi ranṣẹ sori blockchain. Koodu adehun naa ṣiṣẹ bi ẹhin fun awọn ohun elo wọnyi ati ṣalaye ọgbọn iṣowo wọn.

Awọn pepe ikanni ajolo ibile gbarale awọn apoti data lati tọju alaye olumulo, koodu eto, ati awọn iru data miiran. Ṣugbọn eyi ṣẹda awọn aaye kan-ti-ikuna ati ṣafihan eewu pataki. Fun apẹẹrẹ, awọn olupin Facebook je aisini ori ayelujara(opens in a new tab) fun awọn wakati ni Oṣu kẹwa ọdun 2021, to si ge awọn olumulo kuro lori pẹpẹ naa.

Awọn nẹtiwọọki awujọ alailakoso wa lori nẹtiwọọki ti o ni ẹgbẹẹgbẹrun awọn apa ni ayika agbaye. Paapaa ti awọn nodu kan ba kuna, nẹtiwọọki yoo ṣiṣẹ laini idena, to mu awọn ohun elo ni atako si awọn ikuna ati awọn mimuna lo.

Lilo awọn eto ipamọ alailakoso bi InterPlanetary File System (IPFS)(opens in a new tab), awọn nẹtiwọki awujọ ti a ṣe sori Ethereum le daabobo alaye olumulo lowo ilokulo ati lilo irira. Ko si ẹnikan ti yoo ta alaye ti ara ẹni rẹ si awọn olupolowo, bẹẹ ni awọn olosa yoo ni anfani lati ji awọn alaye aṣiri rẹ.

Ọpọlọpọ awọn pepe awujọ to da lori blockchain ni awọn token abinibi to ro isodowo lagbara ni ti aisi ere ipolowo. Awọn olumulo le ra awọn token wọnyi lati wọle si awọn ẹya kan, pari awọn rira awon ohun elo inu re, tabi fun awọn olupilẹṣẹ akoonu ti won feran ni imọran.

Awọn anfaani ti awọn nẹtiwọki awujọ alailakoso

  1. Awọn nẹtiwọki awujọ alailakoso jẹ ki atako ifofinde ati pe o ṣi sile fun gbogbo eniyan. Eyi tumo si wipe a ko le fofinde awon olumulo, yo wọn kuro lori pẹpẹ, tabi fofinde wọn lona ti ko tọ.

  2. Awọn nẹtiwọọki awujọ alailakoso ti je kiko sori awọn ero to dara to je orisun to si sile ati je ki koodu orisun fun awọn ohun elo wa fun ayewo gbogbo eniyan. Nipa imukuro imuse ti awọn algoridimu to diju to wọpọ ni ikanni ajolo ibile, awọn nẹtiwọọki awujọ to da lori blockchain le mu awọn inifesi awọn olumulo ati awọn olupilẹṣẹ pepe barajo.

  3. Awọn nẹtiwọki awujọ alailakoso yọ "arin-ọkunrin" kuro. Awọn olupilẹṣẹ akoonu ní níni taara lori akoonu wọn, ati pe wọn ni ibasepo taara pẹlu awọn atele, ololufe, oluraja, ati ẹgbẹ miiran, laisi nkankan bikoṣe adehun ọlọgbọn laarin.

  4. Bi awọn dapps ti n ṣiṣẹ lori nẹtiwọọki Ethereum, eyiti o ni atilẹyin nipasẹ awọn nẹtiwọọki ti nodu ẹlẹgbẹ-si-ẹlẹgbẹ agbaye, awọn nẹtiwọọki awujọ alailakoso ko ni ifaragba si akoko idaduro olupin ati awọn mimuna lọ.

  5. Awọn pẹpẹ awujọ alailakoso n funni ni ilana imudara isodowo fun awọn olupilẹṣẹ akoonu nipasẹ , awọn sisanwo crypto ninu ohun elo, ati diẹ sii.

  6. Awọn nẹtiwọọki awujọ alailakoso fun awọn olumulo ni ipele giga ti ikọkọ ati ailorukọ. Fun apẹẹrẹ, ẹni kọọkan le wọle si nẹtiwọki awujọ to da lori Ethereum nipa lilo profaili tabi —laisi nini lati pin alaye idanimọ ti ara ẹni (PII), bi awọn orukọ, adirẹsi imeeli, ati bẹbẹ lọ.

  7. Awọn nẹtiwọọki awujọ alailakoso gbekele ibi ipamọ alailakoso, kii ṣe awọn apoti data to lakoso, eyiti o dara julọ fun aabo data olumulo.

Awọn nẹtiwọki awujọ alailakoso lori ethereum

Nẹtiwọọki Ethereum ti di ohun elo ti won fẹ julọ fun awọn olupilẹṣẹ ti won n ṣẹda ikanni ajolo alailakoso nitori okiki ti awọn token rẹ ati ipilẹ olumulo nla rẹ. Eyi ni diẹ ninu awọn apẹẹrẹ ti awọn nẹtiwọọki awujọ to da lori Ethereum:

Mirror

Mirror(opens in a new tab) jẹ pẹpẹ kikọ to ni agbara web3 to ni ifọkansi lati jẹ alailakoso ati ohun-ini olumulo. Awọn olumulo le ka ati kọ lọfẹ lori Mirror nipa sisopọ awọn woleeti wọn nirọrun. Awọn olumulo tun le gba kikọ ati ṣe alabapin si awọn onkọwe ayoo wọn.

Awọn ifiweranṣẹ ti a tẹjade lori Mirror ti wa ni ipamọ patapata lori Arweave, pẹpẹ ibi-itọju alailakoso, ati pe o le je titejade bi awọn token ohun ini alailegbe (NFTs) ti a mọ si Awọn NFT kikọ. Awọn NFT kikọ jẹ ọfẹ patapata fun awọn onkọwe lati ṣẹda, gbigba si n ṣẹlẹ lori Ethereum — ṣiṣe awọn idunadura ni owo perete, iyara, ati ore ayika.

MINDS

MINDS(opens in a new tab) jẹ ọkan ninu awọn nẹtiwọọki awujọ alailakoso ti a lo julọ. O ṣiṣẹ bi Facebook, o si ti ṣa awọn miliọnu awọn olumulo jọ.

Awọn olumulo n lo $MIND to je token ti abinibi pepe lati sanwo fun awọn ohun kan. Awọn olumulo tun le gba awọn token $MIND nipasẹ titẹjade akoonu olokiki, idasi si ayika, ati tọka awọn miiran si pẹpẹ.

Lo awọn nẹtiwọki awujọ alailakoso

Awọn nẹtiwọki awujọ Web2 lori Ethereum

Awọn pepe awujọ abinibi kii ṣe awọn nikan lo n gbiyanju lati ṣafikun imọ-ẹrọ blockchain sinu ikanni ajọlo. Ọpọlọpọ awọn pepe to ni akoso tun n gbero lati se apapo Ethereum sinu ero wọn:

Reddit

Reddit ni awon Maaki Awujo to lokiki(opens in a new tab), eyiti o jẹ awọn token ERC-20 ti awọn olumulo le gba nipasẹ fifiranṣẹ ojulowo akoonu ati idasi awọn awujo ori ayelujara (awọn subreddits). O le se irapada awọn token wonyi laarin subreddit lati gba awọn eto ati anfaani ara oto. Fun iṣẹ akanṣe yii, Reddit n ṣiṣẹ pẹlu Arbitrum, nẹtiwọki ti a ṣe lati ṣe imugbooro awọn idunadura Ethereum.

Eto naa ti wa laaye bayii, pẹlu r/CryptoCurrency subredditṣiṣiṣẹ ẹya Awọn maaki Awujo tire ti a pe ni “Moons”(opens in a new tab). Ni ibamu si apejuwe ile-ise, Moons “n fun awọn alatejade, awọn alasọye, ati awọn alabojuto ni ere fun awọn ilowosi wọn si subreddit naa.” Nitoripe awọn token wọnyi wa lori blockchain (awọn olumulo gba wọn ninu awọn woleeti), wọn jẹ olominira ti Reddit ati pe a ko le mu wọn lọ.

Yato si lilo Awọn maaki Awujo lati ṣii awọn ẹya pataki, awọn olumulo le tun ṣowo wọn fun owo bébà lori awọn pasipaaro. Bakanaa, Awọn maaki Awujo ti olumulo kan ni sọ ipa wọn lori ilana ṣiṣe ipinnu laarin awujo.

Kíkà síwájú síi

Awọn arokọ

Videos

Àwọn àwùjọ

Ǹjẹ́ ojú-ìwé yìí ṣe ìrànlọ́wó?