Rékọjá sí àkóónú àkọ́kọ́

Àwọn àgbàjáde owó ìdókòwò

  • Awọn igbesoke Shanghai/Capella to gbanilaaye awọn yiyọ owo kuro lori Ethereum
  • Awọn adari ero olufowosi gbọdọ pese adirẹsi yiyọ owo kuro lati jẹ ki
  • Awọn ereje pinpin laifowoyi ni gbogbo awọn ọjọ diẹ
  • Awọn olufowosi ti wo kuro ninu idokowo ni kikun yoo gba iyoku owo wọn

Awon iyokuro owo idokowo tokasi gbigbe ETH lati akanti olufowosi lori ipele ifohunsokan Ethereum (the Beacon Chain), si ipele imusise nibiti o ti le fi se idunadura.

Sisanwo ere ti iyoku owo to po iye to ju 32 ETH ni yoo je fifiranse laifowoyi ati nigbagbogbo si adirẹsi iyọwo kuro kan to ni asopọ pelu olufowosi kọọkan, ni gbara ti olumulo ba ti pese re. Awọn olumulo tun lejade kuro ninu idokowo patapata, sis iyoku owo olufowosi won to wa ni kikun.

Awọn ere idokowo

Awọn sisan ere je siseto laifowoyi fun awon akanti olufowosi to n sise pelu iye to po ju ti iyoku owo ti 32 ETH.

Iyoku owo eyikeyi ti o wa loke 32 ETH ti o gba nipasẹ awọn ere ko ṣe alabapin si oju owo, tabi mu iwuwo ti olufọwọsi yii pọ si lori nẹtiwọọki, ati pe a yọkuro laifọwọyi bi isanwo ere ni gbogbo awọn ọjọ diẹ. Yato si lati pese adirẹsi yiyọ kuro ni akoko kan, awọn ere wọnyi ko nilo eyikeyi iṣe lati ọdọ adari ero olufọwọsi. Eyi ni gbogbo ipilẹṣẹ lori ipele ipohunpo, nitorinaa ko si gaasi (owo idunadura) ti a nilo ni eyikeyi igbesẹ.

Bawo ni a ṣe de ibi?

Ni awọn ọdun diẹ sẹhin Ethereum ti ṣe ọpọlọpọ awọn iṣagbega nẹtiwọọki ti o yipada si nẹtiwọọki ti o ni aabo nipasẹ ETH funrararẹ, dipo iwakusa to nilo agbara gidi bi o ti jẹ tẹlẹ. Kikopa ninu ipohunpo lori Ethereum ni bayi ni a mọ si "idokowo", bi awọn olukopa ti atinuwa ti ETH pa, gbe sinu "idokowo" fun agbara lati kopa ninu nẹtiwọki. Awọn olumulo ti o tẹle awọn ofin yoo gba ere, nigba awọn igbiyanju lati se iyanjẹ le mu ijiya dani.

Lati ifilọlẹ ti adehun ifowonipamo dokowo ni Oṣu kọkanla ọdun 2020, diẹ ninu awọn aṣaaju-ọna Ethereum akikanju ti atinuwa ti awọn owo pa lati mu “awọn olufọwọsi” ṣiṣẹ, awọn akanti pataki ti o ni ẹtọ lati jẹri ni deede ati gbero awọn bulọọki, ni atẹle awọn ofin nẹtiwọọki.

Ṣaaju iṣagbega Shanghai/Capella, o ko le lo tabi wọle si ETH rẹ ti o fi dokowo. Ṣugbọn ni bayi, o le wọle lati gba awọn ere rẹ laifọwọyi sinu akanti ti o yan, ati pe o tun le yọkuro ETH ti o fi dokowo nigbakugba ti o ba fẹ.

Bawo ni mo ṣe fe mura?

Àwọn olùdókòwò lọ́wọ́lọ́wọ́

O lè fi nọ́mbà atọ́ka olùfọwọ́sí rẹ sí ibí láti mọ̀ bóyá o nílò láti ṣe ìmúdójúìwọ̀n àwọn ìwé ẹri rẹ(eléyìí wà nínú lọ́ọ́gì oníbàárà rẹ):

Àwọn àkíyèsí pàtàkì

Pipese adirẹsi yiyọ kuro jẹ igbesẹ ti o nilo fun eyikeyi akanti olufọwọsi ṣaaju ki o le yẹ lati yọ ETH re kuro lati iinu iyoku owo rẹ.

Akanti olufọwọsi kọọkan le ṣe iyasọtọ fun adirẹsi yiyọ kuro kan nikan, ni akoko kan. Ni kete ti o ba yan adirẹsi kan ti o fi silẹ si ipele ipohunpo, eyi ko le ṣe tunṣe tabi yipada lẹẹkansi. Ṣayẹwo nini ati deede lẹẹmeji ti adirẹsi ti o pese ṣaaju fifiranṣẹ.

Ko si ewu fun owo rẹ ni akoko yii fun kiko lati pese eyi, ka ba gba pe ọrọ iranileti / irugbin rẹ ti wa ni aabo ni nibiti kise ori ayelujara, ati pe ko ti ni ipalara ni eyikeyi ọna. Ikuna lati ṣafikun awọn iwe-ẹri yiyọ kuro yoo fi ETH silẹ ni titipa ninu akanti olufọwọsi bi o ti wa titi ti wa fi pese adirẹsi yiyọ kuro.

Jijade kuro ninu idokowo patapata

Pipese adirẹsi yiyọ kuro ni o nilo ṣaaju ki o to le gbe eyikeyi owo jade kuro ninu iyoku owo akanti olufọwọsi.

Awọn olumulo to n wa lati jade kuro ni idokowo patapata ati yọ iyoku owo won kuro ni kikun gbọdọ tun fowo si ati se agbejade ifiranṣẹ “ijade atinuwa” pẹlu awọn kokoro olufọwọsi eyiti yoo bẹrẹ ilana ti ijade kuro lati inu idokowo. Eyi ni a ṣe pẹlu onibaara olufọwọsi rẹ ati fi silẹ si nodu ipohunpo rẹ, ati pe ko nilo gaasi.

Ilana ti olufọwọsi ti njade kuro ninu idokowo gba iye akoko oniyipada, to da lori iye awọn miiran to n jade ni akoko kanna. Ni kete ti o ti pari, ko ni je ojuse akanti yii mo lati ṣiṣe awọn iṣẹ nẹtiwọọki olufọwọsi, ko ni ẹtọ fun awọn ere mo, ati pe ko si ni “ETH” wọn mọ ninu "idokowo". Ni akoko yii akanti naa yoo je isamisi bi “yiyọkuro” ni kikun.

Ni kete ti won ti ṣe ifihan akanti kan bi “yiyọkuro”, ati pe awọn iwe-ẹri yiyọ kuro ti je pipese, ko si nkankan diẹ sii ti olumulo nilo lati ṣe ju ki won duro lo. Awọn akanti jẹ laifọwọyi ati gbigba nigbagbogbo nipasẹ awọn oludamoran bulooku fun awọn owo ti o yẹ fun gbigba jade, ati pe iyoku owo akanti rẹ yoo je gbigbe ni kikun (ti a tun mọ bi “iyọkuro ni kikun”) lakokoayewo to nbọ.

Nigbawo ni awọn yiyọ kuro idokowo di ṣiṣẹ?

Awon iyọkuro owo idokowo ti wa laaye! Iṣẹ ṣiṣe yiyọ owo kuro ni a mu ṣiṣẹ bi ara ti igbesoke Shanghai/Capella to waye ni Oṣu kẹrin Ọjọ 12, Ọdun 2023.

Igbesoke Shanghai/Capella jẹ ki ETH idokowo se gba pada si awọn akanti Ethereum deede. Eyi ti pari iyipo lori owo idokowo, o si mu Ethereum sunmọ ni igbesẹ kan lori irin-ajo rẹ si ọna kikọ ayika alailakoso to ni iduroṣinṣin, to ni imu gbooro, to ni aabo.

  • Diẹ sii lori itan Etheuum
  • Diẹ sii lori ọna afojusun Ethereum

Bawo ni awọn sisanwo yiyọ owo kuro se n sise?

Boya olufọwọsi kan ni ẹtọ fun yiyọ kuro tabi rara jẹ ipinnu nipasẹ ipo ti akanti olufọwọsi funrararẹ. Ko si imoran olumulo ti o nilo ni akoko eyikeyi lati pinnu boya akanti kan yẹ ki o ni ifilọlẹ yiyọ kuro tabi rara — gbogbo ilana naa ni a ṣe ni adaṣe laifọwọyi nipasẹ ipele ipohunpo lori iyipo to n tẹsiwaju.

More of a visual learner?

Ṣayẹwo alaye yii ti awọn yiyọkuro idokowo Ethereum nipasẹ Finematics:

"Ayewo" olufowosi

Nigbati a ba ṣeto olufọwọsi kan lati gbero bulọọku atẹle, o nilo lati kọ itotelera yiyọ kuro, ti o to awọn yiyọkuro to yẹ 16. Eyi ni a ṣe nipasẹ ibẹrẹ ti o bẹrẹ pẹlu itọka olufọwọsi 0, ipinnu boya yiyọkuro ti o yẹ fun akanti yii ni ibamu si awọn ofin ti ilana naa, ati ṣafikun rẹ si itotelera to ba wa. Ofọwọsi naa to ṣeto lati daba awọn bulooku wọnyi yoo gbe nibi ti eyi to kẹhin ti duro, lilọsiwaju ninu eto titilai.

Ronu nipa aago alafọwọyi. Ọwọ ti o wa lori aago tọka si wakati naa, nlọsiwaju ni itọsọna kan, ko fo awọn wakati eyikeyi, ati nikẹhin yoo yika si ibẹrẹ lẹẹkansi lẹhin to de nọmba ti o kẹhin.

Bayi dipo 1 si 12, fojuinu wo pe aago naa ni 0 si N (apapọ nọmba awọn akanti olufọwọsi ti o ti forukọsilẹ tẹlẹ lori ipele ipohunpo, ju 500,000 ni Jan 2023).

Ọwọ lori aago tọka si olufọwọsi atẹle ti o nilo lati ṣayẹwo fun awọn yiyọ kuro to yẹ. O bẹrẹ ni 0, o si tẹsiwaju ni gbogbo ọna yika laisi fifo eyikeyi awọn akanti. Nigbati ti o de olufọwọsi to kẹhin, iyipo naa tẹsiwaju pada lati ibẹrẹ.

Ṣiṣayẹwo akanti kan fun awọn yiyọ kuro

Lakoko ti oludamoran ba n sayewo awọn olufọwọsi fun awọn yiyọkuro ti o ṣeeṣe, olufọwọsi kọọkan ti a ṣayẹwo ni a ṣe ayewo re pelu awọn ibeere kukuru lati pinnu boya yiyọ kuro yẹ ki o waye, ati to ba yẹ be, melo ETH ni o yẹ ko je yiyọkuro.

  1. Njẹ adirẹsi yiyọ kuro ti je pipese bi? Ti ko ba si adirẹsi yiyọ kuro ti a ti pese, akanti naa a je fifo ko si si yiyọkuro ti yoo waye.
  2. Se olufowosi naa ti jade kuro ati se o le yo owo kuro? Ti olufọwọsi naa ba ti jade ni kikun, ati pe a ti de akoko ti a gba pe akanti wọn jẹ “yiyọkuro” lẹhinna yiyọkuro ni kikun yoo je ṣiṣeto. Eyi yoo gbe gbogbo owo to ku si adirẹsi yiyọ kuro.
  3. Ṣe owo to ku to daniloju ti pọ si to 32? Ti akanti naa ba ni awọn iwe-ẹri yiyọ kuro, ko ti jade ni kikun, ati pe o ni awọn ere to ju 32 to n duro, yiyọkuro apakan ni yoo ṣiṣẹ eyiti o gbe awọn ere nikan to ju 32 lọ si adirẹsi yiyọ kuro olumulo.

Awọn iṣe meji nikan lo wa ti o je siṣe nipasẹ awọn adari olufowosi lakoko igbesi aye olufọwọsi ti o ni ipa lori eto yii taara:

  • Pese awọn iwe eri yiyọ kuro lati jeki eyikeyi ti yiyọ kuro waye
  • Jade kuro ninu nẹtiwọki, eyi ti yoo fa yiyọ kuro ni kikun

Ko nilo gaasi

Ọna yii si awọn yiyọkuro idokowo yago fun awọn oludokowo lati fi ọwọ se agbekale idunadura kan ti o beere iye kan pato ti ETH lati yọkuro. Eyi tumọ si pe ko si gaasi (owo idunadura) ti a beere, ati awọn yiyọ kuro ko dije fun aaye bulooku ipele imusise to wa tẹlẹ.

Igba melo ni maa gba awọn ere idokowo mi?

O pọju 16 yiyọ kuro le je siseto ni bulooku kan. Ni iwọn yẹn, awọn yiyọkuro olufọwọsi 115,200 le je ṣiṣeto fun ọjọ kan (ni ero pe ko si awọn aaye to je ipadanu). Gẹgẹbi a ti ṣe akiyesi loke, a o fo awọn olufọwọsi ti ko ni yiyọkuro to lẹtọ, sise adinku akoko lati pari ayewo naa.

Fifagun iṣiro yii, a le ṣe iṣiro akoko ti yoo gba lati ṣeto iye awon yiyọ kuro kan:

Iye awon yiyo kuroAkoko to gba lati pari won
400,0003.5 days
500,0004.3 days
600,0005.2 days
700,0006.1 days
800,0007.0 days

Bi o ṣe ri eyi to n lọra bi awọn olufọwọsi diẹ sii se wa lori nẹtiwọọki. Ilọsoke ninu awọn aaye to je ipadanu le fa fifalẹ eyi ni iwọn, ṣugbọn eyi yoo jẹ aṣoju fun ẹgbẹ to lọra ti awọn abajade to ṣeeṣe.

Awon ibere gbogbo ìgbà

Kíkà síwájú síi

Ǹjẹ́ ojú-ìwé yìí ṣe ìrànlọ́wó?