Rékọjá sí àkóónú àkọ́kọ́

Ojú-ìwé tí a múdójúìwọ̀n gbẹ̀yìn: 19 Oṣù Agẹmọ 2024

Ìfilọ́lẹ̀ sí Wẹ́b3

Àláìlákóso ti ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lọ́wọ́ láti wọ orí ayélujára, ó sì ti dá ẹ̀rọ-ìpèsè tó dúró sán-ún, tó sì lágbára tí ayélujára ń gbé orí rẹ̀. Bákan náà, àwọn kan tí wọ́n jẹ́ alákòóso àpapọ̀ ló ń lo ayélujára lọ́nà tó lágbára, wọ́n sì máa ń dá pinnu ohun tó yẹ àti èyí tí kò yẹ kí wọ́n gbà láàyè.

Web3 ni ìdáhùn sí ìṣòro yìí. Dípò Wẹ́ẹ̀bù tí àwọn iléeṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ ńláńlá nìkan mójú tó, Wẹ́ẹ̀bù 3 gba aláìlákóso, àwọn tó ń lò ó ló sì ń kọ́ ọ, tí wọ́n ń lò ó, tó sì jẹ́ pé àwọn ló ni ín. Web3 fi agbára sí ọwọ́ àwọn ènìyàn dípò àwọn ilé-iṣẹ́. Ṣaaju ki a to sọrọ nipa Web3, jẹ ki a ṣawari bi a ṣe de ibi yii.

Àwọn wẹẹbu akọ́kọ́

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń ronú nípa Wẹ́ẹ̀bù gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ ìgbésí ayé òde òní tó ń bá a nìṣó—ó jẹ́ dídá sílẹ̀, ó sì ṣẹ̀ṣẹ̀ wà látìgbà yẹn. Sibẹsibẹ, wẹẹbu ti gbogbo wa mọ ni ode oni yatọ̀ sí eyi ti wọn koko ro. Fún oyé kikún, oda ki a ṣe ifọsi wẹwẹ itàn wẹẹbu-- Wẹẹbu akọkọ ati Wẹẹbu kejì.

Wẹẹbù akọkọ: kíkà-nikan (1990-2004)

Ní ọdun 1989, ni CERN, Geneva, Tim Berners-Lee ń ṣẹda ìlànà tí yoo di wẹẹbu agbaye. Èrò rẹ? Láti ṣẹ̀dá ìlànà aláìlákóso tó sí sílẹ̀ tó gbani láàyè àlàyé pínpín láti ibikíbi lágbáyé.

Ìbẹ̀rẹ̀ àkọ́kọ́ ti ẹ̀dá Berners-Lee, tí a mọ̀ ní báyìí bíi 'Web 1.0', wáyé ní bíi àárín ọdún 1990 sí 2004. Wẹ́ẹ̀bu ìkíní jẹ ojú opo ọlọbọrọgidi ti àwọn ilé iṣẹ, ko dẹ si ibaṣepọ láàrin àwọn oluṣamulo ati àwọn eniyan ko saba maa n ṣe atẹdaje - eyi la fí mo sí wẹ́ẹ̀bù kikà-nikan.

Client-server architecture, ti o ń ṣojú wẹ́ẹ̀bù kíní

Wẹẹbu keji: Kikà-Kikọ̀ (2004- di oni)

Àkókò Wẹẹbu keji bẹrẹ ni ọdun 2004 nipasẹ iwaye àwọn pẹpẹ mídíà àwùjọ. Dípò kikà nikan, wẹẹbu yii ṣe ka- o si ṣe kọ. Dípò ki àwọn ileṣẹ tun bọ maa ṣe atẹjade fún àwọn oluṣamulo, wọn bẹre si ni ṣeda pẹpẹ ti yoo ma pin atẹjade oluṣamulo ati ibaṣepo oluṣamulo-si-oluṣamulo. Bí àwọn eniyan ṣe ń pọ si lori opo ayelujara, àwọn iléṣẹ nla bẹ̀rẹ̀ sii ni akoso ni ọpọlọpọ ati ọpọ èrè ori wẹ́ẹ̀bù. Wẹ́ẹ̀bù keji tún bí ọna iri èrè nipasẹ ipolowo. Botiwulẹ jẹ pẹ àwọn oluṣamulo le ṣe atẹjade, síbẹ wọn ko ní tabi jẹrẹ lori rẹ.

Client-server architecture, ti o ń ṣoju Wẹẹbu keji

Wẹ́ẹ̀bù kẹta: Kà-Kọ́-Ní

Agbekalẹ ọ̀rọ̀ "Wẹ́ẹ̀bù kẹta" jẹ yọ lati ọdọ oludasilẹ keji Ẹ́tẹ́ríọ́mù Gavin Wood ní ìgba díẹ̀ lẹyin idasilẹ Ẹ́tẹ́ríọ́mù ni ọdun 2014. Gavin ṣe agbekalẹ ojutu sí ìdojukọ tí ọpọlọpọ oluṣamulo crypto lerò: Wẹ́ẹ̀bu naa nilo ìgbẹkẹlẹ́ tí o pọ lapọju. Íyẹn ni wipẹ, pupọ ninu wẹẹbu tí àwọn eniyan mọ ti won sí ńlo loni gbarale ìgbẹkẹlé ninu àwọn iléṣẹ aladani wipe wọn yoo ṣiṣẹ pẹ̀lú ife awujọ lokan.

Decentralized node architecture, ti o ń ṣoju wẹẹbù kẹta

Kí ni Web3?

Wẹẹbu kẹta tí dí ọ̀rọ̀ amuyẹ fún ifojusún fún intanẹẹti titún, ti yoo dara julọ. Ní àárín gbùngbùn rẹ, Wẹ́ẹ̀bù kẹta ń lo àwọn blockchain, owó crypto ati NFTs lati fún àwọn oluṣamulo ní agbara pada nipasẹ níní akoso. Atẹjade 2020 kan ni oju opo ayelujara Twitter(opens in a new tab) ṣọọ́ ni ọna to dara ju: Wẹẹbu kíní jẹ kìkà-nikan, Wẹ́ẹ̀bù keji jẹ kíkà-kikọ, Wẹẹbù kẹta yóò jẹ kíkà-kikọ-Níní.

Àwọn koko ẹ̀ro Wẹẹbù kẹta

Ní paapa, o ṣoro lati ṣetúmọ Wẹẹbù kẹta ni pato, àwọn koko ìlànà tí o ń ṣe atọna igbekale rẹ.

  • Wẹẹbù kẹta ko ní akoso àárin: dipo iṣakoso opo ayẹlujara ni owo àwọn iléṣẹ alakoso àárin, iṣakosò dí pinpin làárin àwọn oluṣẹda ati oluṣamulo.
  • Wẹ́ẹ̀bù kẹta je alaigba iyọnda: gbogbo eniyan lo ni anfaani latí kopa ni Wẹ́ẹ̀bù kẹta, lai yọ eni kankan silẹ.
  • Wẹ́ẹ̀bù kẹta ni ìlànà ìsanwó tirẹ: o ṣamulo owó crypto fún lilo ati fifi ranṣẹ owó lori ayẹlujara dipo gbigbarale banki ati ìlànà isanwọ ti igba atijọ.
  • Wẹẹbu kẹta jẹ alai ní igbẹkele o ṣamulo àwọn imoriya ati iṣeto oni iṣuna dipo gbigbaralẹ àwọn iléṣe ẹlẹgbẹ-kẹta.

Kí ní pàtàkì Wẹẹbù kẹta?

Botiwulẹ jẹ pẹ àwọn abuda gboogi Wẹẹbu kẹta ko wa ni iyasọtọ ṣùgbọ́n kosi ipele ti o lẹ wa, fún irorún a ti gbiyanju lati ya won soto lati le jeki won ye ni.

Níni

Wẹẹbù kẹta fún o ní anfaani lati ní àwọn dukia digitali fúnra rẹ nì ona ti ko ṣẹlẹ ri. Ni apẹrẹ, ti o ba ń sere idaraya wẹẹbu keji kan. Tí o ba ra nkan ninu ere idaraya, yoo wa nì asopọ taara si akanti rẹ. Tí àwọn oluṣẹda ere idaraya ba pa akanti rẹ rẹ́, wa padanu áwọn ohun-ini wonyi. Tabi, tí o kò ba gba ere idaraya naa mọ, o padanu owó tí o fi dokowo sinu awon ohun-ini inu ere idaraya re.

Wẹ́ẹ̀bù kẹta fún o ni àáye lati ni ohún-ini taara nipasẹ . Kò sí enikankan, koda kò jẹ awon oluṣẹda ere idaraya, to ní agbara lati gba ini rẹ. Atipe, ti o kò ba gba ere idaraya mọ, o le ta tabi paarọ ohún ini rẹ lori ọja gbangba lati gba deede iye owo rẹ pada.

Ko sí nipa NFTs
Díẹ̀ si nípa NFTs

Ìtako ìfofindè

Ibasepo làárin àwọn pẹpẹ ati àwọn olupilese akoonu ko dọgba rara.

OnlyFans jẹ oju opo tí oluṣamulo ti n ṣeda fọran fun agbalagba tí o sí ní bi miliọnu kan àwọn oluṣeda, pupo ninu won n lo pẹpẹ yi bi ọna atijẹtimu wọn àkọ́kọ́. Ní oṣu kẹjọ odún 2021, OnlyFans kede èrò wọn lati fí ofín de fọ́nrán oní ìhòhò. Ikede di ibinu-ṣuṣu laarín àwọn oluṣẹda fọ́nrán lori oju opo naa, tí wọn gba wipe wọn fẹ gba ọna atijẹ wọn lori oju opo tí àwọn kopa ninu idasilẹ rẹ. Lẹyin esi odi yii, wọn yi ipinnu wọn pada ni kiakia. Pẹ̀lú bí àwọn oluṣeda fọ́nrán yii ṣe jáwé olubori, eyi jẹ òkan ninu idojukọ àwọn oluṣẹda Wẹẹbu keji: waa padanu orúko rere ati awon olutẹle ti o ba kuro ni oju opo naa.

Ní Wẹ́ẹ̀bù kẹta, orí blockchain ní àwọn aye data rẹ wa. Nigbati o ba pinnu lati kuro lori oju opo ayelujara kan, o le mu orúkọ rere rẹ pẹ̀lú rẹ, o si le fi sí oju opo míìran toba lọ pẹ̀lú ìlànà rẹ.

Wẹẹbù keji nilo àwọn oluseda akoonu lati ní ìgbẹlẹle ninu àwọn ojú opo lati mọ ṣe ayidapa ofín wọn, ṣùgbọ́n itako ìfòfinde jẹ ẹya ipilẹ àwọn oju opo Wẹ́ẹ̀bù kẹta.

Àwọn àjò aláìlákóso (DAOs)

Pẹ̀lú bí o ti ní àwọn data tirẹ ní Wẹẹbu kẹta, otún le ní oju opo naa gẹgẹ bi ohun ini, nipasẹ lilo awon token to duro gẹgẹ bi awon ipin ninu ilẹ́ṣẹ naa. Àwọn DAO le jẹ ki o ṣabojuto nini oju opo alailakoso kí o si le ṣe ipinnu nipa ọjọ iwaju rẹ.

Ìtunmọ DAO ni ifenuko imo-ero ni tí yoo siṣẹ fúnra rẹ lai ní akoso aarin lori ọ̀pọ̀ àwọn ohún ini (awon token). Oluṣamulo pẹ̀lú token le dibo bi àwọn ohún ini yoo se di níná, ti koodu yoo si ṣe agbejade ìdìbo naa laifowoyi.

Àmọ àwọn eniyan túnmọ̀ ọpọlọpọ awujo wẹẹbù kẹta sí DAOs. Àwọn awujo yii ni ipele orisirisi alailakoso ati koodu ti o ń siṣe fúnra rẹ. Lọwọlọwọ, a ń ṣe iṣawari àwọn nkan tí DAOs jẹ, ati idagbasoke wọn ni ojo iwaju.

Learn more about DAOs
Díẹ̀ si lórí àwọn DAO

Idanimọ

Ní ibilẹ, wa ṣẹda akanti fún gbogbo oju opo ti o ba ń lo. Ní apẹẹre, o le ní akanti lori Twitter, YouTube, ati Reddit. Se o fẹ lati paarọ orúkọ ifihan tabi aworan profaili rẹ? O ni lati ṣe eyi kaakiri akanti kọọkan. O le lo ìwọle oju opo ayelujara awujo ni igba mìíran ṣùgbọ́n yoo wa pẹ̀lú iṣoro ti a mọ--ìfófinde. Ní ìtẹ̀ kan, àwọn oju opo yii le ti o jade kuro patapata ninu gbogbo opo ayelujara. Koda o le buru ju bẹ lọ, ọpọ oju opo nilo rẹ lati fún wọn ni àwọn idanimọ ara ẹni lati le ní akanti pẹ̀lú wọn.

Wẹ́ẹ̀bù keta koju àwọn iṣoro yii nipasẹ nini akoso idanimọ digitali rẹ pẹ̀lú adirẹsi Ẹ́tẹ́ríọ́mù ati profaili . Lilo àdírẹ́sì Ẹ́tẹ́ríọ́mù fún o ni anfaani lati wọle pẹ̀lú alaye iwọle kan ṣoṣo sí ori gbogbo oju opo to ni ààbo, itako-ìfofinde ati àìdánimọ̀.

Ìlànà ìsanwó abinibi

Ìlànà ìsanwó Wẹẹbu keji gbarale àwọn banki ati ile-iṣẹ ìsanwó, ti o si ti yọ àwọn ti ko ní akanti banki tabi ti wọn n gbe ni ilu òdì kuro. Wẹ́ẹ̀bù kẹta ńlo awon token bi lati fi owó ranṣẹ tààra lori asawakiri ayelujara lai nilo ileṣẹ ẹlẹgbẹkẹta.

Díẹ̀ si nípa ETH

Web3 limitations

Pẹ̀lú gbogbo anfaani Wẹẹbu kẹta lọwọlọwọ, àwọn idiwọ si pọ fun ayika naa lati ko ju fún ikesẹjari ètò naa.

Wiwole

Ẹ̀yà pàtàkì Wẹẹbu kẹta, bi wiwọle pẹ̀lú Ẹ́tẹ́ríọ́mù, ti wa ni sẹpẹ ni ofẹ fún ẹnikẹni. Ṣùgbọ́n, owó iṣẹ idundura to ga ju si tún ko irẹwẹsi ba ọpọ. O ṣee ṣe ki Wẹẹbu kẹta ma di lilo ni àwọn orilẹ ede tí wọn kere ní ọrọ ati idagbasoke nitori owó idunadura to ga. Lori Ẹ́tẹ́ríọ́mù, àwọn ipenija yii tí ní ojutu nipasẹ onà afojusun ati . Ìmọ̀ ẹrọ naa ti ṣetan, ṣùgbọ́n a nilo imulo ti o ga lori ipele keji lati le je ki gbogbo eniyan ni iraye si Wẹẹbu kẹta.

Iriri oluṣamulo

Idena ikọṣẹmọṣẹ wiwọle sí Wẹẹbù kẹta ti ga ju lọwọlọwọ yii. Àwon oluṣamulo gbọdọ loye nipa aniya ààbo, loye àkọsílẹ ikọsẹmọṣẹ to dijupọ, ati lilo opo oluṣamulo ni geere. Olupese wọlẹẹti ni pààpa, ń ṣisẹ lati wa ojutu síi, ṣùgbọ́n a nilo ilọsiwaju to pọ kii Wẹẹbu kẹta to di lilo ni ọpọ.

Èkó

Wẹẹbù kẹta mu ìlànà titún wa tí o nilo kiko oriṣiriṣi awoṣe ju àwọn ti wẹ́ẹ̀bù keji lọ. Ikẹko kan na ṣẹlẹ nigbati wẹẹbu ikini n di gbajumọ ni odún 1990; àwọn oludasilẹ oju opo wẹẹbu agbaye lo aṣayan akosemose eko kan lati kọ ọpọlọpọ nipa lilo akawe ti o rọrun (alaye opopona mọrosẹ, asawakiri ayẹlujara, sisawakiri lori wẹẹbu) sí atẹjadẹ ori ẹrọ mohúnmaworan(opens in a new tab). Wẹ́ẹ̀bù keta rorún, ṣùgbọ́n oyatọ. Àwọn igbesẹ ẹ̀kó ti o ń so ètò Wẹẹbu kẹta fún àwọn oluṣamulo Wẹẹbu keji jẹ pàtàkì fún aṣeyorí rẹ.

Ethereum.org kopa sí itẹsiwaju Wẹẹbu kẹta nipasẹ ètò itumo si ede oriṣiriṣi, pẹ̀lú àfojusún lati túnmọ àwọn akoonu pataki Ẹ́tẹ́ríọ́mù sí ede oríṣíríṣí bi o ba see se si.

Èto alailakoso

Ayika Wẹẹbu kẹta si wa ni titún, o sí n itẹsiwaju ni kiakia. Fún ìdí eyi, o sí gbarale àwọn afilọlẹ alakoso àárin (Github, Twitter, Discord, ati bẹẹbẹ lọ). Ọpọlọpọ ileṣẹ wẹẹbù kẹta ń ṣe kanmọnkia lati di alaafo wọnyi ṣùgbọ́n siṣẹda àwọn ètò tò dangajia nilo àkókò pupọ.

Ọjọ iwaju alailakoso

Wẹẹbù kẹta jẹ ayika titun to si ń tẹsiwaju. Gavin Wood ṣe agbekalẹ ọ̀rọ̀ naa ni ọdún 2014, ṣùgbọ̀n pupo ninu àwọn èrò wonyi bẹrẹ sí ní waye ni aipe yii. Ní ọdún to lo níkan, àwọn ti o nife sí crypto pọsi, ojutu imu gbooro si igbesoke ipele keji, ọpọlopo idanwo pẹ̀lú idari titún ati iyipada otún ni idanimọ digitali.

A si wa ni ibẹrẹ siṣẹda wẹẹbu to dara julọ pẹ̀lú wẹẹbu keta, ṣùgbọ́n bi a ṣe ń tesiwaju pẹ̀lú ètò idagbasoke naa ti yoo ṣe iranlọwọ fun, o dabi pe ọjọ iwaju wẹ́ẹ̀bù dara.

Bawo ní mo ṣe le kópa

  • Gba wọ́lẹ́ẹ́tì kan
  • Wa awujo lati darapọ mọ
  • Sawari àwọn afilọlẹ wẹ́ẹ̀bù keta
  • Darapọ̀ mọ́ DAO
  • Kọ si ori Wẹẹbu kẹta

Kíkà síwájú síi

Wẹ́ẹ̀bù kẹta ò ní ìtumọ̀ kan. Àwọn omo ẹgbẹ awujo ní èró ọtọọtọ lori rẹ. Èyí ni díẹ̀ nínú won:

Ṣe ìdánwò ìmo Ethereum rẹ

Ǹjẹ́ àpilẹ̀kọ yìí ṣe ìrànlọ́wó?