Kí ni Ethereum?
Ìpìlẹ̀ fún ọjọ́ iwájú díjítà wa
Ìtọ́sọ́nà tó pé pérépéré fún alákọọbẹ̀rẹ̀ sí bí Ethereum ṣe ń ṣiṣẹ́, àwọn àǹfààní tó mú wá àti bí àwọn mílíọ̀nù ènìyàn káàkiri àgbáyé ṣe ń lò ó.
Àkópọ̀
Ethereum jẹ́ nẹ́tíwọọkì àwọn kọ̀ǹpútà káàkiri àgbáyé tí ó ń tẹ̀lé ìlànà kan tí a ń pè ní ìlànà Ethereum. Nẹ́tíwọọkì Ethereum ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ìpìlẹ̀ fún àwọn àwùjọ, ohun èlò ẹ̀rọ, ètò àti ohun-ìní dígítà tí ẹnikẹ́ni lè kọ́ àti lò.
O lè ṣẹ̀dá àkántì Ethereum láti ibikíbi, ní ìgbàkigbà, kí o sì ṣàwárí àgbáyé ti àwọn ohun èlò ẹ̀rọ tàbí kọ́ tìrẹ. Ohun tuntun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé o lè ṣe gbogbo èyí láìsí gbígbẹ́kẹ̀lé aláṣẹ pàtàkì kan tó lè yí òfin padà tàbí dín ìráàyèsí rẹ kù.
- Free and global Ethereum accounts
- Pseudo-private, no personal information needed
- Without restrictions anyone can participate
- No company owns Ethereum or decides its future
Kí ni Ethereum lè ṣe?
Ilé ifowópamọ́ fún gbogbo ènìyàn
Kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló ní àǹfààní láti lo àwọn iṣẹ́ ìṣúnná owó. Gbogbo nǹkan tí o nílò ni ìsomọ́ íntánẹ́ẹ̀tì láti wọlé sí Ethereum àti àwọn ohun èlò yíyánilówó, yíyáwó àti ìfowópamọ́ tí a kọ sórí rẹ̀.
Ayélujára tó ṣí sílẹ̀
Ẹnikẹ́ni lè ṣepọ̀ nẹ́tíwọọkì Ethereum tàbí kó àwọn ohun èlò ẹ̀rọ lórí rẹ̀. Èyí jẹ́ kí o lè ṣàkóso àwọn ohun ìní àti ìdánimọ̀ rẹ, dípò kí àwọn ilé-iṣẹ́ ńláńlá díẹ̀ kan máa ṣàkóso wọn.
Nẹ́tíwọọkì ẹlẹ́gbẹ́-sí-ẹgbẹ́
Ethereum jẹ́ kí o ṣe kòkáárí, ṣe àwọn àdéhùn tàbí gbé àwọn ohun-ìní dígítà tààrà pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn. O kò nílò láti gbẹ́kẹ̀lé àwọn alárinà.
Ìtako ìfòfinde
Kò sí ìjọba tàbí ilé-iṣẹ́ kankan tó ní àṣẹ lórí Ethereum. Aláìlákóso jẹ́ kí ó fẹ́ẹ má ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni láti dá ọ dúró gbígba owó tàbí lílo àwọn iṣẹ́ lórí Ethereum.
Ìdánilójú ìṣòwò
Àwọn oníbàárà ní ìdánilójú nínú rẹ̀ tó ní ààbò pé owó yóò pààrọ̀ ọwọ́ tí o bá pèsè ohun tí a ní àdéhùn lè lórí. Bákan náà, àwọn olùgbéẹjáde lè ní ìdánilójú pé àwọn òfin náà kò ní yí padà lórí wọn.
Àwọn ọjà àpapọ̀
Gbogbo ohun èlò ni a kọ́ lórí blockchain kan náà pẹ̀lú ipò àgbáyé ti àjọpín, ìtumọ̀ ni pé wọ́n lè kọ́ ara wọn (bíi àwọn amọ̀ Lego). Èyí jẹ́ kí àwọn ọjà tó dára àti àwọn ìrírí àti àwọn ìdánilójú pé kò sí ẹnikẹ́ni tó lè yọ èyíkéyìí àwọn irinṣẹ́ tí àwọn ohun èlò ẹ̀rọ gbẹ́kẹ̀lé.
Blockchain jẹ́ àkójọpọ̀ dátà ti ìdúnàádúrà tó ní ìmúdójúìwọ̀n àti àjọpín lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn kọ̀ǹpútà nínú nẹ́tíwọọkì kan. Ní gbogbo ìgbà tí ètò ìdúnàádúrà tuntun bá jẹ́ àfikún, a pe ní “block” - nítorí náà orúkọ blockchain. Blockchain àwùjọ bíi Ethereum gba ẹnikẹ́ni láàyè láti fikún, ṣùgbọ́n kò gbani lááyè láti yọ dátà. Tí ẹnìkan bá fẹ́ yí èyíkéyìí àlàyé náà padà tàbí yan ètò náà jẹ, wọn yóò nílò láti ṣe bẹ́ẹ̀ lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn kọ̀ǹpútà lórí nẹ́tíwọọkì náà. Iyẹn jẹ́ púpọ̀! Èyí jẹ́ kí àwọn blockchain aláìlákóso bíi Ethereum ní ààbò gaan.
Kí ló dé tí màá fi lo Ethereum?
Tí o bá nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ọ̀nà tó túbọ̀ lágbára, tí ó ṣí sílẹ̀, tí ó sì ṣeé gbára lé láti ṣe kòòkárí lágbàáyé, ṣẹ̀dá àwọn ètò, kọ́ àwọn ohun èlò ẹ̀rọ àti láti pín ìníyelórí, Ethereum jẹ́ fún ọ. Ethereum jẹ́ ìtàn tí gbogbo wa kọ, nítorí náà wá kí o ṣàwárí àwọn ayé àgbàyanu tí a lè fi kọ́ papọ̀.
Ethereum tún ti jẹ́ iyebíye fún àwọn ènìyàn tó ní láti dojú kọ àìdánilójú lórí ààbò tàbí ìgbẹ́kẹ̀lé tàbí ìṣípòpadà ti àwọn ohun-ìní wọn nítorí àwọn agbára ìta tí kò sí ní ìṣàkóso wọn.
Ta ló ń ṣagbátẹrù Ethereum?
Ethereum kò ní ìṣàkóso nípasẹ̀ èyíkéyìí nǹkan pàtó. Ó wà nígbàkúùgbà tí àwọn kọ̀ǹpútà tó sopọ̀ bá ń mú sọfitiwia ṣiṣẹ́ ní àtẹ̀lé ìlànà Ethereum àti àfikún sí Ethereum. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kọ̀ǹpútà yìí ni wọ́n ń pè ní nódù. Nódù lè ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ ẹnikẹ́ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti kópa nínú dídáàbò bo nẹ́tíwọọkì náà, o ní láti pẹ̀lú ETH (owó abínibí Ethereum). Ẹnikẹ́ni tó bá ní 32 ETH lè ṣe èyí láìsí pé ó nílò ìgbanilááyè.
Kódà, kìí ṣe ẹ̀dá kan ṣoṣo ló pèsè kóòdù orísun Ethereum. Ẹnikẹ́ni lè dábàá àwọn àtúnṣe sí ìlànà àti láti jíròrò àwọn ìṣàgbéga. Àwọn ìmúṣẹ púpọ̀ kan ti ìlànà Ethereum wà tó jẹ́ àgbéjáde nípasẹ̀ àwọn àjọ olómìnira ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èdè síṣètò, tí wọ́n sì máa ń kọ́ ní gbangba, tí wọ́n sì máa ń gba àwùjọ níyànjú láti kópa.
Kí ni àdéhùn ọlọ́gbọ́n?
Àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n jẹ́ àwọn ètò kọ̀ǹpútà tó ń gbé orí blockchain Ethereum. Wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ nígbà tí wọ́n bá gba ìdúnàádúrà kan látọ̀dọ̀ olùṣàmúlò kan. Wọ́n jẹ́ kí Ethereum ní ìrọ̀rùn púpọ̀ nínú ohun tó lè ṣe. Àwọn ètò wọ̀nyí ń ṣiṣẹ́ bíi àwọn búlọ́ọ́kù ilé fún àwọn ohun èlò ẹ̀rọ àti ètò aláìlákóso.
Ǹjẹ́ o ti lo ọjà kan rí tó yí àwọn òfin iṣẹ́ rẹ̀ padà bí? Tàbí yọ ẹ̀yà kan tí o ri pé ó wúlò kúrò? Ní kété tí àdéhùn ọlọ́gbọ́n kan bá jẹ́ àtẹ̀jáde sí Ethereum, yóò wà lórí ayélujára, yóò sì máa ṣiṣẹ́ níwọ̀n ìgbà tí Ethereum bá wà. Kódà ẹni tó kọ ìwé náà kò lè mú un kúrò. Níwọ̀n ìgbà tí àwọn àdéhùn ọlọ́gbọ́n jẹ́ àdáṣe, wọn kì í ṣe ìyàsọ́tọ̀ èyíkéyìí olùṣàmúlò, wọ́n sì ṣetán láti lo nígbà gbogbo.
Àwọn àpẹẹrẹ tó gbajúmọ̀ ti àwọn ìwé àdéhùn ọlọ́gbọ́n jẹ́ àwọn ohun èlò ìyánilówó, àwọn pàṣípààrọ̀ ìṣòwò aláìlákóso, ìdíyelófò, ìkówójọ àwùjọ, àwọn ìkànnì àjọlò orí íńtánẹ́ẹ̀tì, láìfọ̀rọ̀ gùn ohunkóhun tí o lè ronú nipa.
Pàdé ether, owó crypto ti Ethereum
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbésẹ̀ lórí nẹ́tíwọọkì Ethereum nílò iṣẹ́ díẹ̀ láti ṣe lórí kọ̀ǹpútà tó wà nínú Ethereum (tí a mọ̀ sí Ẹ̀rọ-ayárabíàṣá Ethereum). Ìṣirò yìí kì í ṣe ọ̀fẹ́; o sanwó fún lílo owó crypto abínibí ti Ethereum tí a ń pè ní ether (ETH). Èyí túmọ̀ sí pé o nílò ó kéré jù iye ether kan láti lo nẹ́tíwọọkì náà.
Ether jé dígítà tó dáṣáká, o sì lè fi ránṣẹ́ sí ẹnikẹ́ni níbikíbi lágbàáyé lójú ẹsẹ̀. Ìpèsè ether kò sí lábẹ́ àbójútó ìjọba tàbí ilé-iṣẹ́ kankan - ó jẹ́ aláìlákóso àti tó ṣe kedere pátápátá. Ether jẹ́ ìpèsè ní ọ̀nà pàtó kan ní ìbámu sí ìlànà náà, sí àwọn olùdókòwò nìkan tó dáàbòbò nẹ́tíwọọkì náà.
Lílo Agbára Ọdọọdún ní TWh/yr
Báwo ni agbára lílo ti Ethereum?
Ní ọjọ́ karùndínlógún oṣù kẹ̀sán ojo arundilogun, ọdún 2022, Ethereum la ìgbésókè ìsopọ̀ kọjá èyítí ó yí Ethereum padà lati sí .
Ìsopọ̀ náà jẹ́ ìgbésókè tó tóbi jùlọ ti Ethereum, ó sì dín agbára lílò tí a nílò kù láti gba Ethereum ní 99.95%, ó sì ṣẹ̀dá nẹ́tíwọọkì tó ní ààbò díẹ̀ síi fún ìdíyelé kárbọ̀nù tó kéré púpọ̀. Ethereum ní báyìí jẹ́ blockchain tó ní kárbọ̀nù kékeré nígbà tó ń mú ààbò àti imúgbòòrò rẹ̀ pọ̀ si.
Mo gbọ́ pé wọ́n ti ń lo owó crypto gẹ́gẹ́ bí irinṣẹ́ fún ìwà ọ̀daràn. Ṣé òótọ́ ni èyí?
Gẹ́gẹ́ bíi ìmọ̀-ẹ̀rọ èyíkéyìí, nígbà mìíràn yóò jẹ́ àṣìlò. Síbẹ̀síbẹ̀, nítorí gbogbo àwọn ìdúnàádúrà Ethereum ṣẹ̀lẹ̀ lórí blockchain tó ṣí sílẹ̀, ó rọrùn nígbà gbogbo fún àwọn aláṣẹ láti tọpinpin àwọn iṣẹ́ ìrúfin ju bí yóò ṣe jẹ́ nínú ètò ìsúná owó ìbílẹ̀, tó jẹ́ pé ó jẹ́ kí Ethereum jẹ́ yíyàn tí kò ní ìtara fún àwọn tí yóò fẹ́ lo láì ṣàkíyèsí wọn.
Wọ́n lo Crypto nígbà tó kéré jù owó bébà lọ fún àwọn èrèdí ọ̀daràn ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àwárí pàtàkì ti ìjábọ̀ àìpẹ́ kan nípasẹ̀ Europol, Àjọ European Union fún Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Ìgbófinró:
“Lílo àwọn owó crypto fún àwọn iṣẹ́ ìrúfin dàbí pé ó jẹ́ apákan kékeré ti ètò ọrọ̀-ajé owó crypto lápapọ̀, àti pé ó dàbí ẹni pé ó kéré ju iye àwọn owó ìrúfin tó wà nínú eto ìsúná ìbílẹ̀.”
Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín Ethereum àti Bitcoin?
A ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ ni ọdún 2015, A kọ́ Ethereum lórí àkọ̀tun Bitcoin, pẹ̀lú àwọn ìyàtọ̀ ńlá kan.
Àwọn méjèèjì jẹ́ kí o lo owó dígítà láìsí àwọn olùpèsè ìsanwó tàbí àwọn ilé ìfowópamọ́. Ṣùgbọ́n Ethereum jẹ́ ohun tí a lè ṣètò, nítorí náà o tún lè kọ́ àti gbé àwọn ohun èlò aláìlákóso sórí nẹ́tíwọọkì rẹ̀.
Bitcoin jẹ́ ká lè fi àwọn ìfiránṣẹ́ pàtàkì ránṣẹ́ síra wa nípa ohun tí a rò pé ó níye lórí. Fífi ìdí ìníyelórí múlẹ̀ láìsí aláṣẹ jẹ́ ohun tó ti lágbára tẹ́lẹ̀. Ethereum mú èyí gbòòrò síi: dípò àwọn ìfiránṣẹ́ nìkan, o lè kọ èyíkéyìí ètò gbogbogbò tàbí àdéhùn. Kò sí òpin sí irú àwọn àdéhùn tí o lè ṣẹ̀dá àti fohùn ṣọ̀kan lórí, nítorí náà àkọ̀tun ńlá ń ṣẹlẹ̀ lórí nẹ́tíwọọkì Ethereum.
Nígbàtí Bitcoin jẹ́ nẹ́tíwọọkì ìsanwó nìkan, Ethereum dàbí ọjà àwọn iṣẹ́ ìṣúnná owó, àwọn eré ìdárayá, àwọn ìkànnì àjọlò íńtánẹ́ẹ̀tì àti àwọn ohun èlò ẹ̀rọ mìíràn.
Kíkà síwájú síi
Ọ̀sẹ̀ nínú Ìròyìn Ethereum - Ìwé ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ kan tó ń sọ nípa àwọn ìdàgbàsókè pàtàkì tó ń ṣẹlẹ̀ nínú àyíká.
Àwọn Átọ̀mù, Àwọn ilé-iṣẹ́, Àwọn Blockchain - Kí nìdí tí blockchain fi ṣe pàtàkì?
Ohun pàtàkì nínú ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà Àlá Ethereum