Àwọn wọ́lẹ́ẹ́tì Ethereum
Ṣíṣàkóso kọ́kọ́rọ́ sí ọjọ́ iwájú dígítà rẹ
Wọ́lẹ́ẹ́tì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti ṣàkóso àwọn dúkìá dígítà rẹ àti wiwolé sí àwọn àfilọ́lẹ̀.
Kí ni a pè ní wọ́lẹ́ẹ́tì Ethereum?
Àwọn wọ́lẹ́ẹ́tì Ethereum jẹ́ àfilọ́lẹ̀ ó tí ó fún ọ ní ìṣàkóso lórí akọsilẹ rẹ. Gẹ́gẹ́ bí wọlẹẹti alafọwọ́kàn, ó ní ohun gbogbo tí o nílò láti fi ìdí ìdánimọ̀ rẹ múlẹ̀ àti ṣakoso ohun-ìní rẹ. Wọ́lẹẹti rẹ gbà ọ́ láàyè láti wolé sí orí àwọn àfilọ́lẹ̀, ri iye owó tókù, fi àwọn ìsòwò ránṣẹ́, àti jẹ́rìí sí ìdánimọ̀ rẹ.
Wọ́lẹ́ẹ́tì jẹ́ nǹkan tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lò láti ṣe ìtọ́jú àwọn dúkìá digitali pẹ̀lú ìdámọ̀ wọn lórí ẹ̀rọ ayélujára.
Wọlẹẹti jẹ́ ohun èlò fún ìbáraẹniṣepọ̀ pẹ̀lú àkántì Ethereum rẹ. Ìyẹn túmọ̀ sí wípé o le pààrọ̀ àwọn olùpèsè wọlẹẹti nígbàkúgbà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn wọlẹẹti tún jẹ́ kí o ṣàkosó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkántì Ethereum láti ori àfilọ́lẹ̀ kan si omiran.
Àwọn olùpèsè wọ́lẹẹti kòní àmójútó lórí àwọn owó rẹ. Wọ́n kàn pèsè fèrèsé fún ọ láti rí àwọn ohun-ìní rẹ lórí Ethereum àti àwọn irinṣẹ́ láti ṣàkóso wọn ní rọ̀rùn.
Ohun èlò kan fún ìṣàkóso àwọn owó rẹ
Wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ yóò ṣe àfihàn iye owó rẹ tó kù, ìtàn ìdúnàádúrà, ó sì tún fún ọ ní ọ̀nà láti fi owó ránṣẹ́/gba owó. Àwọn wọ́lẹ́ẹ́tì mìíràn lè pèsè jù bẹ́ẹ̀ lo.
Àkántì Ethereum rẹ
Wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ ni ọ̀nà sínú àkántì Ethereum rẹ - iye owó rẹ tó kù, ìtàn ìdúnàádúrà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n o lè pààrọ̀ àwọn olùpèsè wọ́lẹ́ẹ́tì nígbàkigbà.
Ọ̀rọ̀ ìwọlé rẹ fún àwọn àfilọ́lẹ̀ Ethereum
Wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ jẹ́ kí o lè sopọ̀ mọ́ àwọn àfilọ́lẹ̀ nípa lílo àkántì Ethereum rẹ. Ó dàbí ọ̀rọ̀ ìwọlé tí o lè lò wọlé sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àfilọ́lẹ̀.
Àwọn wọ́lẹ́ẹ̀tì, àkántì, ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé àti àdírẹ́sì
Ó dára láti mọ ìyàtọ̀ láàrin àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì kan.
Àkántì Ethereum jẹ́ àsopò kókóró ìgbaniwọlé àṣírí. ni a máa fi sèdá àdírẹ́sì tí o lè pín fún ẹnikẹ́ni, ní láti wà ní àṣírí torí pé yóò jẹ́ àfiwọlé fún àwọn iṣẹ́ mìíràn. Àwọn kọ́kọ́rọ́ yìí yóò jé kí o lè dúnàádúrà, á tún jé kí dúkìá wà ní àkàtà rẹ.
Àkọsílẹ̀ Ethereum ní àdírẹ́sì , gẹ́gẹ́ bíi àpò orí ayélujára ṣe ní àdírẹ́sì ímeèlì. Èyí ní a fi sẹ̀ ìdámọ̀ dúkìá dígítà rẹ.
Wọ́lẹ́ẹ́tì ti jé irinsẹ́ kan tí o lè fi ṣàjoṣepọ̀ pèlú àkántì rẹ, pèlú lílo àwọn kọ́kọ́rọ́ ìgbaniwọlé àṣírí rẹ. Yóò jẹ́ kí o lè ri iye owó tókù, ṣe ìdúnàádúrà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ọ̀pọ̀ àwọn wọ́lẹ́ẹ́tì yóò jẹ́ kí o ṣẹ̀dá àkántì Ethereum. Nítorí náà, o kò nílò ọ̀kan kí o tó ṣe ìgbàsílẹ̀ wọ́lẹ́ẹ́tì láti orí ayélujára.
Àwọn oríṣi wọ́lẹ́ẹ́tì
Àwọn ọ̀nà díẹ̀ láti ní wíwò àti ìbáṣepò pẹ̀lú àkántì rẹ:
Ẹ̀rọ wọ́lẹ́ẹ́tì alárídìmúni èrọ tí o lè fi owó kíríputò rẹ pamọ́ sí pèlú ààbo tó péye láì so pọ̀ mọ́ íńtánẹ́ẹ̀tì
Àwọn àkántì lórí ẹ̀rọ aláàgbeká tí ó fún ọ láàyè sí àwọn owó rẹ láti ibikíbi
Àwọn wọ́lẹ́ẹ́tì ẹ̀rọ aṣàwákiri jẹ́ àwọn àfilọ́lẹ̀ wẹ́ẹ̀bù tó jẹ́ kí o lè ṣe àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àkántì rẹ tààrà ní orí ẹ̀rọ aṣàwákiri
Wọ́lẹ́ẹ́tì àmúgbòòrò ẹ̀rọ aṣàwákiri jẹ́ àwọn àmúgbòòrò tí o lè ṣe àgbàsílẹ̀ rẹ láti orí ayélujára tó jẹ́ kí o lè ṣe àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àkántì rẹ àti àwọn àfilọ́lẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀rọ aṣàwákiri
Àwọn ohun èlò kọ̀mpútà orí tábìlì tí o bá fẹ́ láti ṣàkóso àwọn owó rẹ nípasẹ̀ macOS, Windows tàbí Linux
Ṣe àfiwé wọ́lẹ́ẹ́tì nípasẹ̀ àwọn ẹ̀yà
Bí o ṣe lè wà ní ààbò
Gba ojúṣe fún àwọn owó rẹ
Àwọn pàsípáàrọ̀ ààrin yóò so àkántì rẹ pọ̀ mọ́ orúkọ olùmúlò àti ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé tí o le gbà padà ní ọnà ìbílẹ̀. Rántí pé o gbẹ́kẹ̀lé pàsípáàrọ̀ náà pèlú àmójútó owó rẹ. Tí pàsípáàrọ̀ náà bá ní ìṣòro owó, àwọn owó rẹ yóò wà ní ewu.
Kọ àwon rẹ sílẹ̀
Àwọn wọ́lẹ́ẹ́tì yóò fún ọ ní ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ nígbà gbogbo tí o gbọdọ̀ kọ sí ibìkan tí ó pamọ́. Ẹ̀yi nìkan ni ọ̀nà tí yóò fún ọ ní àǹfààní láti gba wọ́lẹ́ẹ́tì rẹ padà.
Àpẹẹrẹ kan nì yìí:
there aeroplane curve vent formation doge possible product distinct under spirit lamp
Má ṣe fi pamọ́ sí orí kọ̀npútà rẹ. Kọ́ sílẹ̀ kí o sì jé kí ó wà ní ààbò.
Fi wọ́lẹ́ẹ́tì re síbi tí o ti lè ri ní kíákíá
Tí o bá ń lo wọ́lẹ́ẹ́tì ayélujára, fí èka ayélujára náà síbi tí o ti lè ri kíákíá kí o ba lè dáabò bo ara rẹ lọ́wọ́ àwọn onítànjẹ.
Ṣe àyẹ̀wò gbogbo rẹ̀ lẹ́ẹ̀ mẹ́ta
Rántí pé ìdúnàádúrà kò ṣé dápadà àti pé wọ́lẹ́ẹ́tì kò le ṣeé gbà padà ní ìrọ̀rùn nítorí náà ṣe ìtètè-funra kí o sì máa ṣọ́ra nígbà gbogbo.