
Kú àbọ̀ sí Ethereum
Pẹpẹ asíwájú fún àwọn áàpù tuntun àti àwọn nẹ́tíwọọkì blockchain
Mú wọ́lẹ́ẹ̀tì kan
Ṣẹ̀dá àwọn àkántì & ṣe àkóso àwọn ohun-ìní
Gba ETH
Owó níná ti Ethereum
Dán àwọn áàpù wò
Ìnáwó, eré ìdárayá, àwùkọ
Bẹ̀rẹ̀ sí kọ́
Ṣẹ̀dá áàpù rẹ akọkọ

Kinni Ethereum?
Ethereum jẹ́ nẹ́tíwọ́ọ̀kì blockchain àpínkiri, open source àti pèpéle ìdàgbàsókè software, tí owó onínọ́mbà ether (ETH) ń fún ní agbára. Ethereum ni ìpìlẹ̀ ààbò, káríayé fún ìran tuntun ti àwọn áàpù tí kò leè dì.
Nẹ́tíwọ́ọ̀kì Ethereum ṣí sílẹ̀ fún gbogbo ènìyàn: kò sí àṣẹ tó pọndandan. Kò ní onígbà, ó sì jẹ́ kíkọ́ àti títọ́jú láti ọwọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn, àwọn àjọ, àti àwọn olùlò káríayé.
Ọ̀nà tuntun kan láti lo íńtánẹ́ẹ̀tì

Owó oni-nọ́mbà fún lílò ojoojúmọ́
Stablecoins jẹ́ owó onínọ́mbà tó ń pa iye dúró, tí a so mọ́ àwọn ohun-ìní tó dúró sinsin bíi dọ́là Amẹ́ríkà. Wọlé sí àwọn ìsanwó káríayé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tàbí tọ́jú iye pamọ́ sí àwọn dọ́là oni-nọ́mbà lórí Ethereum.
Ṣé awárí àwọn owó ẹyọ tó lẹ́sẹ̀ nlẹ̀
Ètò ìnáwó tó ṣí sílẹ̀ fún gbogbo ènìyàn
Yá, yíni, gba èlé, àti púpọ̀ síi, láìsí àpamọ́ báǹkì. Ètò ìnáwó àpínkiri Ethereum ṣí sílẹ̀ 24/7 fún ẹnikẹ́ni tó ní ìsopọ̀ Íńtánẹ́ẹ̀tì.
Ṣe ìwádìí DeFi
Nẹ́tíwọọkì ti àwọn nẹ́tíwọọkì
Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn nẹ́tíwọ́ọ̀kì Layer 2 ni a kọ́ lé Ethereum. Gbádùn àwọn owó ìsanwó kékeré àti àwọn ìṣòwò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí o ń jàǹfààní láti inú ààbò Ethereum tí a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀.
Ṣàwárí àwọn Layer 2
Àwọn áàpù tí o bọ̀wọ̀ fún àṣírí rẹ
Àwọn áàpù tí a kọ́ lé Ethereum ń ṣiṣẹ́ láì ta data rẹ. Láti media ajọṣepọ sí eré sí iṣẹ́, lo àpamọ́ kan náà fún gbogbo áàpù tuntun nígbàtí o ń pa àṣírí mọ́ àti wíwọlé.
Wá àwọn áàpù kiri
Íńtánẹ́ẹ̀tì ti àwọn ohun-ìní
Láti iṣẹ́-ọnà sí ilé àti ilẹ̀ sí àwọn ìpín-ìdókòwò, ohun-ìní èyíkéyìí leè jẹ́ títókìn lórí Ethereum láti fi hàn àti láti jẹ́rìí sí ohun-ìní nípasẹ̀ oni-nọ́mbà. Ra, tà, ṣòwò, àti ṣẹ̀dá àwọn ohun-ìní àti àwọn ohun ìkówójọ—nígbàkúgbà, níbikíbi.
Nípa àwọn NFT síi
Kí ni ETH?
Ether (ETH) ni owó onínọ́mbà abínibí tó ń fún nẹ́tíwọ́ọ̀kì Ethereum ní agbára, tí a ń lò láti san àwọn owó ìṣòwò àti láti fi ìdáàbòbò blockchain sílẹ̀ nípasẹ̀ staking.
Yàtọ̀ sí ipa imọ̀-ẹ̀rọ rẹ̀, ETH jẹ́ owó oni-nọ́mbà tó ṣí sílẹ̀, tó ṣeéṣe láti ṣe ètò. A ń lò ó fún àwọn ìsanwó káríayé, gẹ́gẹ́ bí adógún fún àwọn awin, àti gẹ́gẹ́ bí ìtọ́jú iye tó kò gbára lé èyíkéyìí àjọ àárín.

Àyíká tó lágbára jùlọ
Ethereum ni pèpéle aṣíwájú fún pípesè, ṣíṣàkóso, àti yíyanjú àwọn ohun-ìní oni-nọ́mbà. Láti owó onítókìn àti àwọn ohun èlò ìnáwó sí àwọn ohun-ìní gidi àti àwọn ọjà tí ń yọjú, Ethereum n pese ìpìlẹ̀ ààbò, àìṣegbé fún ètò ọrọ̀-ajé oni-nọ́mbà.
Ìgbòkègbodò lórí Ethereum Mainnet àti àwọn nẹ́tíwọ́ọ̀kì Layer 2
Íńtánẹ́ẹ̀tì ń yí padà
Jẹ́ ara ìyípadà orí ẹ̀rọ

Àwùjọ olùgbéró tó tóbi jùlọ owó ẹyọ tó lẹ́sẹ̀ nlẹ̀
Ethereum jẹ́ ilé fún àyíká olùdásílẹ̀ tó tóbi jùlọ àti tó ní agbára jùlọ ti Web3. Lo JavaScript àti Python, tàbí kí o kọ́ èdè àdéhùn ọlọ́gbọ́n tó dá ṣáṣá bíi Solidity tàbí Vyper láti kọ áàpù tìrẹ.
Àwọn àpẹẹrẹ kóòdù
Ìròyìn Ethereum
Àwọn àtẹ̀jáde bulọọgi tuntun jùlọ àti àwọn ìmúdójúìwọ̀n láti àwùjọ náà
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ Ethereum
Àwọn àwùjọ Ethereum máa ń gbàlejò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ káàkiri àgbáyé, jálẹ̀ ọdún
Dara pọ̀ mọ́ ethereum.org
Oju opo wẹẹbu ethereum.org jẹ́ kíkọ́ àti títọ́jú láti ọwọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn atúmọ̀-èdè, àwọn kọ́dà, àwọn aṣẹ̀dá, àwọn akọ̀wé, àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwùjọ. O leè dabaa àtúnṣe sí èyíkéyìí nínú àkóónú tó wà lórí ojúlé open source yii.
Bí o ti lè kópa
Mọ gbogbo ọ̀nà tí o lè gbà ran ethereum.org lọ́wọ́ láti dàgbà kí ó sì dára síi.
GitHub
Lọ́wọ́ sí kóòdù, àpẹẹrẹ, àwọn àròkọ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Discord
Láti béèrè àwọn ìbéèrè, láti ṣètò gbígbọn ọwọ́ sáwo àti láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ìpè àwùjọ.
X
Láti bá àwọn ìmúdójúìwọ̀n ati ìròyìn pàtàkì dọ́gba.



